Kíróníkà Kejì 19:1-11
19 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì ọba Júdà pa dà sí ilé* rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù láìséwu.*+
2 Jéhù+ ọmọ Hánáánì+ aríran jáde lọ bá Ọba Jèhóṣáfátì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé èèyàn burúkú ló yẹ kí o máa ràn lọ́wọ́,+ ṣé àwọn tó kórìíra Jèhófà ló sì yẹ kí o nífẹ̀ẹ́?+ Nítorí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí ọ.
3 Síbẹ̀, àwọn ohun rere kan wà tí a rí nínú rẹ,+ nítorí o ti mú àwọn òpó òrìṣà* kúrò ní ilẹ̀ yìí, o sì ti múra ọkàn rẹ sílẹ̀* láti wá Ọlọ́run tòótọ́.”+
4 Jèhóṣáfátì ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, ó sì tún jáde lọ sáàárín àwọn èèyàn náà láti Bíá-ṣébà dé agbègbè olókè Éfúrémù,+ kó lè mú wọn pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+
5 Ó tún yan àwọn onídàájọ́ káàkiri ilẹ̀ náà ní gbogbo àwọn ìlú olódi Júdà, láti ìlú dé ìlú.+
6 Ó sọ fún àwọn onídàájọ́ náà pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí kì í ṣe èèyàn lẹ̀ ń ṣojú fún tí ẹ bá ń dájọ́, Jèhófà ni, ó sì wà pẹ̀lú yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìdájọ́.+
7 Ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà wà lọ́kàn yín.+ Ẹ máa kíyè sára nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí pé kò sí àìṣẹ̀tọ́,+ kò sí ojúsàájú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.”+
8 Ní Jerúsálẹ́mù, Jèhóṣáfátì tún yan àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn olórí agbo ilé Ísírẹ́lì láti máa ṣe onídàájọ́ fún Jèhófà àti láti máa yanjú àwọn ẹjọ́ fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.+
9 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe láti fi hàn pé ẹ bẹ̀rù Jèhófà nìyí, kí ẹ sì ṣe é pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti gbogbo ọkàn yín:*
10 Nígbà tí àwọn arákùnrin yín bá wá láti ìlú wọn, tí wọ́n gbé ẹjọ́ tó jẹ mọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ìbéèrè nípa òfin, àṣẹ, àwọn ìlànà tàbí àwọn ìdájọ́ wá, kí ẹ kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má bàa jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìbínú rẹ̀ máa wá sórí ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín. Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí kí ẹ má bàa jẹ̀bi.
11 Amaráyà olórí àlùfáà rèé, òun ni olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti Jèhófà.+ Sebadáyà ọmọ Íṣímáẹ́lì ni olórí ilé Júdà nínú gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti ọba. Àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ aláṣẹ yín. Ẹ jẹ́ alágbára, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀, kí Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe rere.”*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tàbí “ní àlàáfíà.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ọkàn rẹ ti múra tán.”
^ Tàbí “ọkàn tó pa pọ̀.”
^ Tàbí “pẹ̀lú ohun rere.”