Kíróníkà Kejì 13:1-22

  • Ábíjà di ọba Júdà (1-22)

    • Ábíjà ṣẹ́gun Jèróbóámù (3-20)

13  Ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jèróbóámù, Ábíjà jọba lórí Júdà.+  Ọdún mẹ́ta ló fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikáyà+ ọmọ Úríélì láti Gíbíà.+ Ogun sì wáyé láàárín Ábíjà àti Jèróbóámù.+  Nítorí náà, Ábíjà kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lákíkanjú, tí wọ́n sì jẹ́ akọgun* lọ sójú ogun.+ Bákan náà, Jèróbóámù kó ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ ogun,* àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dojú kọ ọ́.  Ábíjà wá dúró lórí Òkè Sémáráímù tó wà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ mi, Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì.  Ṣé ẹ ò mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti fún Dáfídì ní ìjọba lórí Ísírẹ́lì títí láé,+ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?*+  Àmọ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì dìde, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí olúwa rẹ̀.+  Àwọn ọkùnrin aláìríkan-ṣèkan àti aláìníláárí ń kóra wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n borí Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì nígbà tí Rèhóbóámù ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì ya ojo, kò sì lè dojú kọ wọ́n.  “Ní báyìí, ẹ rò pé ẹ lè dojú kọ ìjọba Jèhófà tó wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Dáfídì, torí pé ẹ pọ̀ jù wọ́n lọ, ẹ sì ní àwọn ère ọmọ màlúù wúrà tí Jèróbóámù fi ṣe àwọn ọlọ́run fún yín.+  Ṣebí ẹ ti lé àwọn àlùfáà Jèhófà jáde,+ ìyẹn àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì àti àwọn ọmọ Léfì, tí ẹ sì yan àwọn àlùfáà tiyín bí àwọn èèyàn ilẹ̀ míì ti ń ṣe?+ Ẹni tó bá mú akọ ọmọ màlúù kan àti àgbò méje wá* lè di àlùfáà àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọ́run. 10  Ní tiwa, Jèhófà ni Ọlọ́run wa,+ a kò sì fi í sílẹ̀; àwọn àlùfáà wa, ìyẹn àtọmọdọ́mọ Áárónì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà, àwọn ọmọ Léfì sì ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. 11  Wọ́n ń mú àwọn ẹbọ sísun rú èéfín sí Jèhófà ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́+ pẹ̀lú tùràrí onílọ́fínńdà,+ àwọn búrẹ́dì onípele*+ sì wà lórí tábìlì ògidì wúrà, wọ́n máa ń tan ọ̀pá fìtílà wúrà+ àti àwọn fìtílà rẹ̀ ní alaalẹ́,+ nítorí pé à ń ṣe ojúṣe wa fún Jèhófà Ọlọ́run wa; àmọ́ ẹ̀yin ti fi í sílẹ̀. 12  Ẹ wò ó! Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú wa, ó ń darí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ sì wà níbí láti máa fun kàkàkí láti fi pe ogun sí yín. Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ má ṣe bá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín jà, torí ẹ ò ní ṣàṣeyọrí.”+ 13  Àmọ́ Jèróbóámù rán àwọn kan láti lọ lúgọ kí wọ́n lè yọ sí wọn látẹ̀yìn, ó wá di pé wọ́n wà níwájú Júdà, àwọn tó lúgọ sì wà lẹ́yìn wọn. 14  Nígbà tí àwọn èèyàn Júdà bojú wẹ̀yìn, wọ́n rí i pé ogun ń bọ̀ níwájú, ogun ń bọ̀ lẹ́yìn. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà,+ àwọn àlùfáà sì ń fun kàkàkí kíkankíkan. 15  Àwọn èèyàn Júdà bú sẹ́kún nítorí ogun, nígbà tí àwọn èèyàn Júdà kígbe ogun, Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ́gun Jèróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú Ábíjà àti Júdà. 16  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sá níwájú Júdà, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé Júdà lọ́wọ́. 17  Ábíjà àti àwọn èèyàn rẹ̀ pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, òkú àwọn tí wọ́n pa lára Ísírẹ́lì sì wà nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ ogun.* 18  Bí a ṣe rẹ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wálẹ̀ ní àkókò náà nìyẹn, àwọn èèyàn Júdà sì borí wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 19  Ábíjà ń lépa Jèróbóámù nìṣó, ó sì gba àwọn ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Bẹ́tẹ́lì+ pẹ̀lú àwọn àrọko rẹ̀,* Jẹ́ṣánà pẹ̀lú àwọn àrọko rẹ̀ àti Éfúrénì+ pẹ̀lú àwọn àrọko rẹ̀. 20  Jèróbóámù kò tún lágbára mọ́ nígbà ayé Ábíjà; níkẹyìn, Jèhófà kọ lù ú, ó sì kú.+ 21  Àmọ́ Ábíjà ń lágbára sí i. Nígbà tó yá, ó fẹ́ ìyàwó mẹ́rìnlá (14),+ ó sì bí ọmọkùnrin méjìlélógún (22) àti ọmọbìnrin mẹ́rìndínlógún (16). 22  Ìyókù ìtàn Ábíjà, àwọn ohun tó ṣe àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn ìwé* wòlíì Ídò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”
Ní Héb., “àṣàyàn ọkùnrin.”
Ìyẹn, májẹ̀mú tó wà títí lọ, tí kò sì ní yí pa dà.
Ní Héb., “tó bá fi akọ ọmọ màlúù kan àti àgbò méje kún ọwọ́ rẹ̀.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Ní Héb., “àṣàyàn ọkùnrin.”
Ní Héb., “gbára lé.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí “àlàyé.”