Sámúẹ́lì Kìíní 24:1-22
24 Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù pa dà lẹ́yìn àwọn Filísínì tó lé lọ, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Dáfídì wà ní aginjù Ẹ́ń-gédì.”+
2 Torí náà, Sọ́ọ̀lù kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin tí ó yàn látinú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì wá Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sórí àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta tí àwọn ewúrẹ́ orí òkè máa ń wà.
3 Sọ́ọ̀lù dé ibi àwọn ọgbà àgùntàn tí wọ́n fi òkúta ṣe lójú ọ̀nà, níbi tí ihò kan wà, ó sì wọlé lọ láti tura,* àmọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jókòó sí inú ihò náà ní apá ẹ̀yìn.+
4 Àwọn ọkùnrin Dáfídì sọ fún un pé: “Ọjọ́ yìí ni Jèhófà sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Màá fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́,+ o lè ṣe ohunkóhun tó bá dára ní ojú rẹ sí i.’” Torí náà, Dáfídì dìde, ó sì rọra gé etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí Sọ́ọ̀lù wọ̀.
5 Àmọ́ lẹ́yìn náà, ọkàn* Dáfídì ń dá a lẹ́bi ṣáá,+ torí pé ó gé etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí Sọ́ọ̀lù wọ̀.
6 Ó sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà, pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí i, torí ẹni àmì òróró Jèhófà ni.”+
7 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí ló fi dá àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dúró,* kò sì gbà wọ́n láyè láti kọ lu Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù dìde, ó kúrò nínú ihò náà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.
8 Lẹ́yìn náà, Dáfídì dìde, ó jáde kúrò nínú ihò náà, ó sì nahùn pe Sọ́ọ̀lù, o ní: “Olúwa mi ọba!”+ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù bojú wẹ̀yìn, Dáfídì tẹrí ba, ó sì dọ̀bálẹ̀.
9 Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí nìdí tí o fi fetí sí àwọn tó ń sọ pé, ‘Wò ó! Dáfídì fẹ́ ṣe ọ́ ní jàǹbá’?+
10 O ti fojú ara rẹ rí i lónìí bí Jèhófà ṣe fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ nínú ihò. Àmọ́ nígbà tí ẹnì kan ní kí n pa ọ́,+ àánú rẹ ṣe mí, mo sì sọ pé, ‘Mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí olúwa mi, torí pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni.’+
11 Bàbá mi, wò ó, etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá rèé lọ́wọ́ mi; nígbà tí mo gé etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá, mi ò pa ọ́. Ṣé ìwọ náà rí i, ṣé o sì ti wá mọ̀ báyìí pé mi ò gbèrò láti ṣe ọ́ ní jàǹbá tàbí kí n dìtẹ̀ sí ọ? Mi ò ṣẹ̀ ọ́,+ àmọ́ ńṣe ni ò ń dọdẹ mi kiri láti gba ẹ̀mí* mi.+
12 Kí Jèhófà ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ,+ kí Jèhófà sì bá mi gbẹ̀san lára rẹ,+ àmọ́ mi ò ní jẹ́ gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ.+
13 Bí òwe àtijọ́ kan tó sọ pé, ‘Ẹni burúkú ló ń hùwà burúkú,’ àmọ́ ní tèmi, mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ.
14 Ta tiẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì ń lé kiri? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá bíi tèmi yìí ni? Àbí ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo?+
15 Kí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàárín èmi àti ìwọ. Yóò rí i, yóò gba ẹjọ́ mi rò,+ yóò dá ẹjọ́ mi, yóò sì gbà mí lọ́wọ́ rẹ.”
16 Bí Dáfídì ṣe parí ọ̀rọ̀ tó sọ fún Sọ́ọ̀lù yìí, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọ mi?”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkankíkan.
17 Ó sọ fún Dáfídì pé: “Òdodo rẹ ju tèmi lọ, torí o ti ṣe dáadáa sí mi, àmọ́ mo ti fi ibi san án fún ọ.+
18 Bẹ́ẹ̀ ni, o ti sọ ohun rere tí o ṣe lónìí fún mi bí o kò ṣe pa mí nígbà tí Jèhófà fi mí lé ọ lọ́wọ́.+
19 Ta ló máa rí ọ̀tá rẹ̀ tí á sì jẹ́ kó faraare lọ? Jèhófà yóò fi ire san án fún ọ,+ nítorí ohun tí o ṣé fún mi lónìí.
20 Wò ó! Mo mọ̀ pé kò sí bí o kò ṣe ní di ọba tó máa ṣàkóso+ àti pé ìjọba Ísírẹ́lì máa pẹ́ lọ́wọ́ rẹ.
21 Ní báyìí, fi Jèhófà búra+ fún mi pé o ò ní pa àtọmọdọ́mọ* mi run àti pé o ò ní pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nílé bàbá mi.”+
22 Torí náà, Dáfídì búra fún Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn náà Sọ́ọ̀lù lọ sí ilé rẹ̀.+ Àmọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sí ibi ààbò.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “bo ẹsẹ̀ rẹ̀.”
^ Tàbí “ẹ̀rí ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “tú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ká.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “èso.”