Kíróníkà Kìíní 25:1-31

  • Àwọn olórin àti àwọn akọrin ilé Ọlọ́run (1-31)

25  Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì+ sọ́tọ̀ láti máa fi háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti síńbálì*+ sọ tẹ́lẹ̀. Orúkọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ni,  látinú àwọn ọmọ Ásáfù: Sákúrì, Jósẹ́fù, Netanáyà àti Áṣárélà, àwọn ọmọ Ásáfù lábẹ́ ìdarí Ásáfù, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ lábẹ́ àṣẹ ọba.  Látinú Jédútúnì,+ àwọn ọmọ Jédútúnì ni: Gẹdaláyà, Séérì, Jeṣáyà, Ṣíméì, Haṣabáyà àti Matitáyà,+ wọ́n jẹ́ mẹ́fà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn Jédútúnì, ẹni tó ń fi háàpù sọ tẹ́lẹ̀, láti máa dúpẹ́ àti láti máa yin Jèhófà.+  Látinú Hémánì,+ àwọn ọmọ Hémánì ni: Bùkáyà, Matanáyà, Úsíélì, Ṣẹ́búẹ́lì, Jérímótì, Hananáyà, Hánáánì, Élíátà, Gídálítì, Romamuti-ésérì, Joṣibẹ́káṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì.  Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Hémánì, aríran ọba tó bá ti kan ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run tòótọ́ láti gbé e* ga; torí náà, Ọlọ́run tòótọ́ fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá (14) àti ọmọbìnrin mẹ́ta.  Gbogbo wọn wà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn láti máa kọrin ní ilé Jèhófà pẹ̀lú síńbálì, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́. Àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba ni Ásáfù, Jédútúnì àti Hémánì.  Àwọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn tí a ti kọ́ níṣẹ́ orin láti máa kọrin sí Jèhófà jẹ́ igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288), gbogbo wọn jẹ́ ọ̀jáfáfá.  Torí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ lórí iṣẹ́ wọn, bí ti ẹni kékeré ṣe rí bẹ́ẹ̀ ni ti ẹni ńlá, bíi ti ọ̀jáfáfá náà sì ni ti akẹ́kọ̀ọ́.  Kèké tó kọ́kọ́ jáde jẹ́ ti Ásáfù fún Jósẹ́fù,+ ìkejì fún Gẹdaláyà+ (òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ méjìlá [12]); 10  ìkẹta fún Sákúrì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 11  ìkẹrin fún Ísíráì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 12  ìkarùn-ún fún Netanáyà,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 13  ìkẹfà fún Bùkáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 14  ìkeje fún Jéṣárélà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 15  ìkẹjọ fún Jeṣáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 16  ìkẹsàn-án fún Matanáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 17  ìkẹwàá fún Ṣíméì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 18  ìkọkànlá fún Ásárẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 19  ìkejìlá fún Haṣabáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 20  ìkẹtàlá fún Ṣúbáélì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 21  ìkẹrìnlá fún Matitáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 22  ìkẹẹ̀ẹ́dógún fún Jérémótì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 23  ìkẹrìndínlógún fún Hananáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 24  ìkẹtàdínlógún fún Joṣibẹ́káṣà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 25  ìkejìdínlógún fún Hánáánì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 26  ìkọkàndínlógún fún Málótì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 27  ogún fún Élíátà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 28  ìkọkànlélógún fún Hótírì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 29  ìkejìlélógún fún Gídálítì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 30  ìkẹtàlélógún fún Máhásíótì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 31  ìkẹrìnlélógún fún Romamuti-ésérì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12).

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aro.”
Ní Héb., “ìwo rẹ̀.”