Kíróníkà Kìíní 20:1-8
20 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* lákòókò tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Jóábù+ kó àwùjọ ọmọ ogun kan jáde, ó sì run ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì; ó wá dó ti Rábà,+ àmọ́ Dáfídì dúró sí Jerúsálẹ́mù.+ Jóábù gbéjà ko Rábà, ó sì wó o palẹ̀.+
2 Nígbà náà, Dáfídì mú adé Málíkámù kúrò ní orí rẹ̀, ó sì rí i pé ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ tálẹ́ńtì* wúrà kan àti pé àwọn òkúta iyebíye wà lára rẹ̀; a sì fi dé Dáfídì lórí. Ó tún kó ẹrù tó pọ̀ gan-an látinú ìlú náà.+
3 Ó kó àwọn èèyàn inú rẹ̀, ó fi wọ́n sídìí iṣẹ́+ pé kí wọ́n máa fi ayùn rẹ́ òkúta, kí wọ́n sì máa fi àwọn ohun èlò onírin mímú àti àáké ṣiṣẹ́. Ohun tí Dáfídì ṣe sí gbogbo àwọn ìlú àwọn ọmọ Ámónì nìyẹn. Níkẹyìn, Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun náà pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
4 Lẹ́yìn èyí, wọ́n bá àwọn Filísínì jà ní Gésérì. Ìgbà yẹn ni Síbékáì + ọmọ Húṣà pa Sípáì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù,+ wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Filísínì.
5 Wọ́n tún bá àwọn Filísínì jà, Élíhánánì ọmọ Jáírì pa Láámì arákùnrin Gòláyátì+ ará Gátì, ẹni tí igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ.*+
6 Ogun tún wáyé ní Gátì,+ níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia,+ ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+
7 Ó ń pẹ̀gàn+ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jónátánì ọmọ Ṣíméà,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, pa á.
8 Àwọn yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Réfáímù+ ní Gátì,+ Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló sì pa wọ́n.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, nígbà ìrúwé.
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “olófì.”