Òwe 4:1-27
4 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí ìbáwí bàbá;+Ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ lè ní òye,
2 Nítorí màá fún yín ní ìtọ́ni rere;Ẹ má ṣe pa ẹ̀kọ́* mi tì.+
3 Ọmọ gidi ni mo jẹ́ fún bàbá mi+Ìyá mi sì fẹ́ràn mi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.+
4 Bàbá mi kọ́ mi, ó sì sọ pé: “Kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wà lọ́kàn rẹ digbí.+
Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa wà láàyè.+
5 Ní ọgbọ́n, ní òye.+
Má gbàgbé, má sì kúrò nínú ohun tí mo sọ.
6 Má pa á tì, yóò dáàbò bò ọ́.
Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́.
7 Ọgbọ́n ni ohun tó ṣe pàtàkì* jù lọ,+ torí náà ní ọgbọ́n,Pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.+
8 Jẹ́ kó níyì gan-an lójú rẹ, yóò sì gbé ọ ga.+
Yóò bọlá fún ọ nítorí pé o gbá a mọ́ra.+
9 Yóò fi òdòdó ẹ̀yẹ tó fani mọ́ra sí ọ lórí;Yóò sì dé ọ ní adé ẹwà.”
10 Ọmọ mi, fetí sílẹ̀, kí o sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi,Ọdún tí o máa fi wà láàyè yóò sì pọ̀.+
11 Màá kọ́ ọ ní ọ̀nà ọgbọ́n;+Màá darí rẹ ní ipa ọ̀nà òdodo.*+
12 Nígbà tí o bá ń rìn, ẹsẹ̀ rẹ kò ní kọ́lẹ̀;Tí o bá sì ń sáré, o ò ní kọsẹ̀.
13 Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kó lọ.+
Pa á mọ́, nítorí òun ni ẹ̀mí rẹ.+
14 Má ṣe gba ọ̀nà àwọn ẹni burúkú,Má sì rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.+
15 Yẹra fún un, má gba ibẹ̀ kọjá;+Má gbabẹ̀, máa bá tìẹ lọ.+
16 Torí wọn ò lè sùn àfi tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa.
Wọn kì í rí oorun sùn àfi tí wọ́n bá mú kí ẹnì kan ṣubú.
17 Oúnjẹ ìwà burúkú ni wọ́n fi ń bọ́ ara wọn,Wáìnì ìwà ipá ni wọ́n sì ń mu.
18 Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀Tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.+
19 Ọ̀nà àwọn ẹni burúkú dà bí òkùnkùn;Wọn ò mọ ohun tó ń mú wọn kọsẹ̀.
20 Ọmọ mi, fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi;Fetí sílẹ̀ dáadáa* sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.
21 Máa fi wọ́n sọ́kàn;Jẹ́ kí wọ́n jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ,+
22 Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tó wá wọn rí+Wọ́n sì jẹ́ ìlera fún gbogbo ara* wọn.
23 Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ,+Nítorí inú rẹ̀ ni àwọn ohun tó ń fúnni ní ìyè ti ń wá.
24 Mú èké ọ̀rọ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+Sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ békebèke jìnnà sí ọ.
25 Ọ̀ọ́kán tààrà ni kí ojú rẹ máa wò,Bẹ́ẹ̀ ni, iwájú rẹ gan-an ni kí o tẹjú* mọ́.+
26 Mú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ ń gbà jọ̀lọ̀,*+Gbogbo ọ̀nà rẹ á sì lójú.
27 Má yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+
Má fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà búburú.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “òfin.”
^ Tàbí “ṣe kókó.”
^ Tàbí “ìdúróṣinṣin.”
^ Ní Héb., “Dẹ etí rẹ.”
^ Ní Héb., “ẹran ara.”
^ Tàbí “ranjú.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Fara balẹ̀ kíyè sí ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ ń gbà.”