Òwe 31:1-31
31 Àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Lémúẹ́lì, ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ìyá rẹ̀ fi dá a lẹ́kọ̀ọ́:+
2 Kí ni kí n sọ fún ọ, ọmọ mi,Kí ni kí n sọ, ìwọ ọmọ ikùn mi,Kí sì ni kí n sọ, ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi?+
3 Má fi okun rẹ fún àwọn obìnrin,+Má sì tọ ọ̀nà tó ń fa ìparun bá àwọn ọba.+
4 Lémúẹ́lì, kò tọ́ sí àwọn ọba,Kò tọ́ kí àwọn ọba máa mu wáìnìTàbí kí àwọn alákòóso máa sọ pé, “Ọtí mi dà?”+
5 Kí wọ́n má bàa mutí tán, kí wọ́n wá gbàgbé àṣẹ tó wà nílẹ̀,Kí wọ́n sì fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n.
6 Fún àwọn tó ń kú lọ ní ọtí+Àti wáìnì fún àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá.*+
7 Kí wọ́n mu, kí wọ́n gbàgbé ipò òṣì wọn;Kí wọ́n má sì rántí ìdààmú wọn mọ́.
8 Gba ọ̀rọ̀ sọ fún ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀;Gbèjà ẹ̀tọ́ gbogbo àwọn tó ń kú lọ.+
9 Sọ̀rọ̀, kí o sì dájọ́ lọ́nà òdodo;Gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ti tálákà.*+
א [Áléfì]
10 Ta ló ti rí aya tó dáńgájíá?*+
Ó níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju iyùn.*
ב [Bétì]
11 Ọkọ rẹ̀ fọkàn tán an,Kò* sì ṣaláìní ohun tó yẹ.
ג [Gímélì]
12 Ohun rere ni obìnrin náà fi ń san án lẹ́san, kì í ṣe búburú,Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.*
ד [Dálétì]
13 Obìnrin náà wá òwú àti aṣọ ọ̀gbọ̀* kàn;Ó sì fẹ́ràn láti máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́.+
ה [Híì]
14 Ó dà bí àwọn ọkọ̀ òkun oníṣòwò,+Ó ń kó oúnjẹ rẹ̀ wọlé láti ọ̀nà jíjìn.
ו [Wọ́ọ̀]
15 Bákan náà, ó máa ń dìde nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́,Láti wá oúnjẹ sílẹ̀ fún agbo ilé rẹ̀Àti èyí tó máa fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.+
ז [Sáyìn]
16 Ó ronú nípa oko kan, ó sì rà á;Ó gbin ọgbà àjàrà látinú èrè iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.*
ח [Hétì]
17 Ó múra sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ àṣekára,*+Ó sì fún apá rẹ̀ lókun.
ט [Tétì]
18 Ó rí i pé òwò òun ń mérè wọlé;Fìtílà rẹ̀ kì í kú ní òru.
י [Yódì]
19 Ọwọ́ rẹ̀ gbá ọ̀pá ìrànwú mú,Ọwọ́ rẹ̀ sì di ìrànwú* mú.+
כ [Káfì]
20 Ó la àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí aláìní,Ó sì la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà.+
ל [Lámédì]
21 Kò dààmú nípa agbo ilé rẹ̀ pé yìnyín ń já bọ́,Nítorí pé gbogbo agbo ilé rẹ̀ ti wọ ẹ̀wù òtútù.*
מ [Mémì]
22 Ó ṣe àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn rẹ̀.
Aṣọ rẹ̀ jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* àti olówùú pọ́pù.
נ [Núnì]
23 Àwọn èèyàn mọ ọkọ rẹ̀ dáadáa ní àwọn ẹnubodè ìlú,+Níbi tó máa ń jókòó sí láàárín àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà.
ס [Sámékì]
24 Ó máa ń fi ọ̀gbọ̀* ṣe aṣọ,* ó sì máa ń tà á,Ó tún máa ń ta àmùrè fún àwọn oníṣòwò.
ע [Áyìn]
25 Ó fi agbára àti ògo ṣe aṣọ wọ̀,Ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀* bó ṣe ń wo ọjọ́ iwájú.
פ [Péè]
26 Tó bá la ẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ló ń jáde,+Òfin inú rere* sì wà ní ahọ́n rẹ̀.
צ [Sádì]
27 Ó ń ṣọ́ ohun tó ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀,Kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.+
ק [Kófì]
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì pè é ní aláyọ̀;Ọkọ rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.
ר [Réṣì]
29 Ọ̀pọ̀ obìnrin tó dáńgájíá* ló wà,Àmọ́ ní tìrẹ, o ta gbogbo wọn yọ.
ש [Ṣínì]
30 Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè má tọ́jọ́,*+Àmọ́ obìnrin tó bẹ̀rù Jèhófà ló máa gba ìyìn.+
ת [Tọ́ọ̀]
31 Ẹ fún un ní èrè ohun tó ṣe,*+
Kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè ìlú.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tí ọkàn wọn gbọgbẹ́.”
^ Tàbí “Gba ẹjọ́ àwọn aláìní àti ti tálákà rò.”
^ Tàbí “aya àtàtà.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ìyẹn, ọkọ rẹ̀.
^ Ìyẹn, obìnrin náà.
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “owó ara rẹ̀.” Ní Héb., “èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”
^ Ní Héb., “Ó fi agbára di ìbàdí rẹ̀ lámùrè.”
^ Ọ̀pá ìrànwú àti ìrànwú ni igi tí wọ́n fi ń yí òwú àti fọ́nrán pọ̀ tàbí kí wọ́n fi ṣe é.
^ Ní Héb., “ẹ̀wù oníṣẹ̀ẹ́po.”
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Tàbí “Ó sì ń rẹ́rìn-ín.”
^ Tàbí “Ẹ̀kọ́ onífẹ̀ẹ́; Òfin ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”
^ Tàbí “obìnrin àtàtà.”
^ Tàbí “lè jẹ́ òfo; asán.”
^ Ní Héb., “Ẹ fún un látinú èso ọwọ́ rẹ̀.”