Òwe 24:1-34
24 Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi,Má sì jẹ́ kó máa wù ọ́ láti bá wọn kẹ́gbẹ́,+
2 Nítorí ìwà ipá ni ọkàn wọn ń rò,Ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìjàngbọ̀n.
3 Ọgbọ́n la fi ń gbé ilé* ró,+Òye sì la fi ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
4 Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ yóò fi kún fúnOnírúurú ìṣúra tó ṣeyebíye tó sì fani mọ́ra.+
5 Ẹni tó gbọ́n jẹ́ alágbára,+Ìmọ̀ sì ni èèyàn fi ń mú kí agbára rẹ̀ pọ̀ sí i.
6 Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n ni kí o fi ja ogun rẹ,+Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* ìṣẹ́gun* á wà.+
7 Ọgbọ́n tòótọ́ ga ju ohun tí ọwọ́ òmùgọ̀ lè tẹ̀;+Kò* ní ohun kankan láti sọ ní ẹnubodè ìlú.
8 Ẹnikẹ́ni tó bá ń gbèrò ibi,Ọ̀gá elétekéte la ó máa pè é.+
9 Èrò tí kò mọ́gbọ́n dání* máa ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀,Àwọn èèyàn sì máa ń kórìíra afiniṣẹ̀sín.+
10 Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà,*Agbára rẹ ò ní tó nǹkan.
11 Gba àwọn tí wọ́n fẹ́ lọ pa sílẹ̀,Sì fa àwọn tó ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sí ibi pípa sẹ́yìn.+
12 Tí o bá sọ pé: “Ṣebí a ò mọ̀ nípa rẹ̀,”Ṣé Ẹni tó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn* kò mọ̀ ni?+
Bẹ́ẹ̀ ni, Ẹni tó ń wò ọ́* máa mọ̀Yóò sì san ẹnì kọ̀ọ̀kan lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.+
13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí ó dára;Oyin inú afárá sì ń dùn lẹ́nu.
14 Lọ́nà kan náà, mọ̀ pé ọgbọ́n dára fún ọ.*+
Tí o bá wá a rí, ọjọ́ ọ̀la rẹ á dáraÌrètí rẹ kò sì ní pa rẹ́.+
15 Má ṣe lúgọ sí tòsí ilé olódodo láti ṣe é níbi;Má ṣe ba ibi ìsinmi rẹ̀ jẹ́.
16 Nítorí olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde,+Àmọ́ àjálù yóò mú kí ẹni burúkú ṣubú pátápátá.+
17 Tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má ṣe dunnú,Tó bá sì kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ yọ̀;+
18 Nítorí Jèhófà yóò rí i, á sì bí i nínú,Á sì yí ìbínú rẹ̀ kúrò lórí rẹ̀.*+
19 Má ṣe kanra* nítorí àwọn aṣebi;Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi.
20 Nítorí ọjọ́ ọ̀la ẹni ibi kò lè dáa;+Fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.+
21 Ọmọ mi, bẹ̀rù Jèhófà àti ọba.+
Má sì bá àwọn oníyapa* kẹ́gbẹ́.+
22 Nítorí àjálù wọn yóò dé lójijì.+
Ta ló mọ ìparun tí àwọn méjèèjì* máa mú bá wọn?+
23 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tún jẹ́ ti àwọn ọlọ́gbọ́n:
Kò dára láti máa ṣe ojúsàájú nínú ìdájọ́.+
24 Ẹni tó bá ń sọ fún ẹni burúkú pé, “Olódodo ni ọ́,”+Àwọn èèyàn yóò gégùn-ún fún un, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì dá a lẹ́bi.
25 Àmọ́ yóò dáa fún àwọn tó ń bá a wí;+Òjò ìbùkún ohun rere yóò rọ̀ sórí wọn.+
26 Àwọn èèyàn yóò fi ẹnu ko ètè ẹni tó ń fi òótọ́ inú fèsì.*+
27 Múra iṣẹ́ tí o máa ṣe lóde sílẹ̀, kí o sì wá gbogbo nǹkan sílẹ̀ ní pápá;Lẹ́yìn náà, kọ́ ilé* rẹ.
28 Má ṣe ta ko ọmọnìkejì rẹ láìnídìí.+
Má ṣe fi ètè rẹ tanni jẹ.+
29 Má sọ pé: “Bó ṣe ṣe sí mi ni màá ṣe sí i pa dà;Màá san ohun tó ṣe pa dà fún un.”*+
30 Mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ oko ọ̀lẹ,+Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹni tí kò ní làákàyè.*
31 Mo rí i pé igbó ti kún bò ó;Èsìsì ti bo ilẹ̀ rẹ̀,Ògiri olókùúta rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀.+
32 Mo kíyè sí i, mo sì fi í sọ́kàn;Mo rí i, mo sì kọ́ ẹ̀kọ́* yìí:
33 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,
34 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “agbo ilé.”
^ Tàbí “olùdámọ̀ràn.”
^ Tàbí “àṣeyọrí; ìgbàlà.”
^ Ìyẹn, òmùgọ̀.
^ Tàbí “Ohun tí òmùgọ̀ ń gbèrò.”
^ Tàbí “lásìkò ìdààmú.”
^ Tàbí “èrò.”
^ Tàbí “wo ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “dùn mọ́ ọkàn rẹ.”
^ Ìyẹn, ọ̀tá náà.
^ Tàbí “gbaná jẹ.”
^ Tàbí “àwọn tó ń wá ìyípadà.”
^ Ìyẹn, Jèhófà àti ọba.
^ Tàbí kó jẹ́, “Fífèsì lọ́nà tó tọ́ dà bí fífi ẹnu koni lẹ́nu.”
^ Tàbí “agbo ilé.”
^ Tàbí “Màá ṣe bákan náà sí i.”
^ Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”
^ Ní Héb., “gba ìbáwí.”