Ẹ́sítà 8:1-17

  • Ọba gbé Módékáì ga (1, 2)

  • Ẹ́sítà bẹ ọba (3-6)

  • Àṣẹ tí ọba fi ta ko àṣẹ àkọ́kọ́ (7-14)

  • Àwọn Júù rí ìtura, wọ́n sì ń yọ̀ (15-17)

8  Ní ọjọ́ yẹn, Ọba Ahasuérúsì fún Ẹ́sítà Ayaba ní ilé Hámánì,+ ọ̀tá àwọn Júù;+ Módékáì sì wá síwájú ọba torí pé Ẹ́sítà ti sọ bó ṣe jẹ́ sí òun.+  Ọba wá bọ́ òrùka àṣẹ+ rẹ̀ tó gbà lọ́wọ́ Hámánì, ó sì fún Módékáì. Ẹ́sítà sì fi Módékáì ṣe olórí ilé Hámánì.+  Bákan náà, Ẹ́sítà tún bá ọba sọ̀rọ̀. Ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń sunkún, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó yí jàǹbá tí Hámánì ọmọ Ágágì fẹ́ ṣe pa dà àti ohun tó gbèrò láti ṣe sí àwọn Júù.+  Ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹ́sítà,+ ni Ẹ́sítà bá dìde, ó sì dúró níwájú ọba.  Ó sọ pé: “Tó bá dáa lójú ọba, tí mo bá sì rí ojú rere rẹ̀, tó bá yẹ lójú ọba, tó sì fẹ́ràn mi, jẹ́ kí wọ́n kọ ìwé àṣẹ kan láti fagi lé ìwé àṣẹ tí Hámánì elétekéte+ ọmọ Hamédátà ọmọ Ágágì+ kọ, èyí tó kọ pé kí wọ́n pa àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba run.  Nítorí ara mi ò lè gbà á pé kí n máa wo àjálù tó máa dé bá àwọn èèyàn mi, ara mi ò sì ní gbà á pé kí àwọn ìbátan mi pa run.”  Nítorí náà, Ọba Ahasuérúsì sọ fún Ẹ́sítà Ayaba àti Módékáì tó jẹ́ Júù pé: “Ẹ wò ó! Mo ti fún Ẹ́sítà ní ilé Hámánì,+ mo sì ti ní kí wọ́n gbé e kọ́ sórí òpó igi,+ nítorí ète tó pa láti gbéjà ko* àwọn Júù.  Ní báyìí, ẹ kọ ohunkóhun tó bá dáa lójú yín lórúkọ ọba nítorí àwọn Júù, kí ẹ sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e, nítorí ìwé àṣẹ tí wọ́n bá kọ lórúkọ ọba, tí wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé kò ṣeé yí pa dà.”+  Torí náà, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba ní àkókò yẹn ní oṣù kẹta, ìyẹn oṣù Sífánì,* ní ọjọ́ kẹtàlélógún, wọ́n sì kọ gbogbo ohun tí Módékáì pa láṣẹ fún àwọn Júù àti fún àwọn baálẹ̀,+ fún àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè àwọn ìpínlẹ̀*+ tó wà ní Íńdíà títí dé Etiópíà, ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínláàádóje (127), wọ́n kọ ọ́ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè tirẹ̀, bákan náà, wọ́n kọ ọ́ sí àwọn Júù ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn àti ní èdè wọn. 10  Ó kọ ọ́ ní orúkọ Ọba Ahasuérúsì, ó fi òrùka àṣẹ ọba+ gbé èdìdì lé e, ó sì fi àwọn ìwé náà rán àwọn asáréjíṣẹ́ tó ń gun ẹṣin; ẹṣin àfijíṣẹ́ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá nílẹ̀ ni wọ́n gùn, iṣẹ́ ọba sì ni àwọn ẹṣin náà wà fún. 11  Nínú ìwé náà, ọba fún àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìlú kọ̀ọ̀kan láyè láti kóra jọ, kí wọ́n sì gbèjà ara* wọn, kí wọ́n pa àwọn ọmọ ogun àwùjọ tàbí ti ìpínlẹ̀* èyíkéyìí tó bá gbéjà kò wọ́n, títí kan àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin, kí wọ́n run wọ́n, kí wọ́n pa wọ́n rẹ́, kí wọ́n sì gba ohun ìní wọn.+ 12  Ọjọ́ kan náà ni kí èyí ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ìyẹn oṣù Ádárì.*+ 13  Kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ inú* ìwé náà ṣe òfin káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀.* Kí wọ́n kéde rẹ̀ fún gbogbo àwọn èèyàn, kí àwọn Júù lè múra sílẹ̀ lọ́jọ́ náà láti gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn.+ 14  Àwọn asáréjíṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àfijíṣẹ́ tó wà fún iṣẹ́ ọba sáré jáde lọ kíákíá gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe pa á láṣẹ. Wọ́n sì tún gbé òfin náà jáde ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá.* 15  Módékáì wá jáde níwájú ọba nínú ẹ̀wù oyè olówùú búlúù àti funfun,* ó dé adé ńlá tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè àtàtà olówùú pọ́pù.+ Igbe ayọ̀ sì sọ ní ìlú Ṣúṣánì.* 16  Àwọn Júù rí ìtura,* wọ́n ń yọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n sì ń ṣògo. 17  Ní gbogbo ìpínlẹ̀* àti gbogbo ìlú tí àṣẹ ọba àti òfin rẹ̀ dé, àwọn Júù ń yọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n ń se àsè, wọ́n sì ń ṣe àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í pe ara wọn ní Júù,+ torí ẹ̀rù àwọn Júù ń bà wọ́n.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “ẹ̀dà.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”
Tàbí “Súsà.”
Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”
Tàbí “òwú ọ̀gbọ̀.”
Tàbí “Súsà.”
Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀.”
Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”