Ẹ́kísódù 39:1-43
39 Wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò+ hun àwọn aṣọ lọ́nà tó dáa láti máa fi ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́. Wọ́n ṣe àwọn aṣọ mímọ́ ti Áárónì,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
2 Ó fi wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe éfódì.+
3 Wọ́n fi òòlù lu àwọn wúrà pẹlẹbẹ títí tó fi fẹ́lẹ́, ó wá gé e tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ kó lè lò ó pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, ó sì kóṣẹ́ sí i.
4 Wọ́n ṣe àwọn aṣọ tó máa so pọ̀ mọ́ ọn ní èjìká, wọ́n sì so wọ́n mọ́ etí méjèèjì éfódì náà.
5 Àwọn ohun kan náà ni wọ́n fi ṣe àmùrè tí wọ́n hun,* èyí tó wà lára éfódì náà láti dì í mú kó lè dúró dáadáa,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè, wọ́n lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.
6 Lẹ́yìn náà, wọ́n lẹ òkúta ónísì mọ́ orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n sì fín orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sára rẹ̀, bí ìgbà tí wọ́n fín nǹkan sára èdìdì.+
7 Ó fi wọ́n sórí àwọn aṣọ èjìká éfódì náà kó lè jẹ́ òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
8 Ó wá mú kí ẹni tó ń kó iṣẹ́ sí aṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà,+ bí wọ́n ṣe ṣe éfódì, ó lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa.+
9 Tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba. Wọ́n ṣe aṣọ ìgbàyà náà, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.*
10 Wọ́n to òkúta sára rẹ̀ ní ìpele mẹ́rin. Ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ rúbì, tópásì àti émírádì.
11 Ìpele kejì jẹ́ tọ́kọ́wásì, sàfáyà àti jásípérì.
12 Ìpele kẹta jẹ́ òkúta léṣémù,* ágétì àti ámétísì.
13 Ìpele kẹrin jẹ́ kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́ ìtẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe.
14 Àwọn òkúta náà dúró fún orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (12), wọ́n sì fín àwọn orúkọ náà sára òkúta bí èdìdì, orúkọ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà.
15 Wọ́n wá ṣe ẹ̀wọ̀n tó lọ́ pọ̀ sára aṣọ ìgbàyà náà, bí okùn tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe.+
16 Wọ́n fi wúrà ṣe ìtẹ́lẹ̀ méjì àti òrùka méjì, wọ́n sì fi òrùka méjèèjì sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà.
17 Lẹ́yìn náà, wọ́n ki okùn oníwúrà méjèèjì bọnú àwọn òrùka méjì tó wà ní igun aṣọ ìgbàyà náà.
18 Wọ́n wá ki etí okùn méjèèjì bọnú ìtẹ́lẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ àwọn aṣọ èjìká éfódì náà níwájú.
19 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì fi wọ́n sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà ní inú, ó dojú kọ éfódì náà.+
20 Wọ́n tún ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì fi wọ́n síwájú éfódì náà, nísàlẹ̀ àwọn aṣọ èjìká méjèèjì éfódì náà, nítòsí ibi tí wọ́n ti so pọ̀, ní òkè ibi tí àmùrè* tí wọ́n hun ti so mọ́ éfódì náà.
21 Níkẹyìn, wọ́n fi okùn aláwọ̀ búlúù so àwọn òrùka aṣọ ìgbàyà náà mọ́ àwọn òrùka éfódì náà, kí aṣọ ìgbàyà náà lè dúró lórí éfódì náà, lókè àmùrè* tí wọ́n hun, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
22 Lẹ́yìn náà, ó ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá sí éfódì náà, ẹni tó ń hun aṣọ fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe é látòkè délẹ̀.+
23 Ó yọ ọrùn sí aṣọ àwọ̀lékè náà ní àárín, bí ọrùn ẹ̀wù irin. Ó ṣe ìgbátí sí ọrùn rẹ̀ yí ká, kó má bàa ya.
24 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí wọ́n lọ́ pọ̀ ṣe pómégíránétì sí etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà.
25 Wọ́n fi ògidì wúrà ṣe àwọn agogo, wọ́n sì fi àwọn agogo náà sáàárín àwọn pómégíránétì yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà, láàárín àwọn pómégíránétì;
26 wọ́n to agogo kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan, agogo kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
27 Wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe aṣọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ẹni tó ń hun aṣọ ló ṣe é,+
28 wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa ṣe láwàní+ àti aṣọ tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ tí wọ́n máa wé sórí,+ wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe àwọn ṣòkòtò péńpé,*+
29 wọ́n tún fi aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí wọ́n hun pọ̀ ṣe ọ̀já, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
30 Níkẹyìn, wọ́n fi ògidì wúrà ṣe irin pẹlẹbẹ tó ń dán, tó jẹ́ àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́,* wọ́n sì fín ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ bí ẹni fín èdìdì, pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.”+
31 Wọ́n so okùn tí wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe mọ́ ọn, kí wọ́n lè dè é mọ́ láwàní náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
32 Wọ́n wá parí gbogbo iṣẹ́ àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
33 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àgọ́ ìjọsìn+ náà wá sọ́dọ̀ Mósè, àgọ́ náà+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀: àwọn ìkọ́ rẹ̀,+ àwọn férémù rẹ̀,+ àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀+ àti àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀;+
34 ìbòrí rẹ̀ tí wọ́n fi awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa ṣe,+ ìbòrí rẹ̀ tí wọ́n fi awọ séálì ṣe, aṣọ tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà;+
35 àpótí Ẹ̀rí àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ àti ìbòrí náà;+
36 tábìlì, gbogbo ohun èlò rẹ̀+ àti búrẹ́dì àfihàn;
37 ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, àwọn fìtílà rẹ̀,+ ọ̀wọ́ àwọn fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀+ àti òróró tí wọ́n á máa fi tan iná;+
38 pẹpẹ+ wúrà, òróró àfiyanni,+ tùràrí onílọ́fínńdà,+ aṣọ* tí wọ́n máa ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́;
39 pẹpẹ bàbà+ àti àgbàyan* rẹ̀ tí wọ́n fi bàbà ṣe, àwọn ọ̀pá rẹ̀,+ gbogbo ohun èlò rẹ̀,+ bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀;+
40 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n máa ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá, àwọn okùn àgọ́ rẹ̀ àti àwọn èèkàn àgọ́ rẹ̀+ àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n máa fi ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn náà, ní àgọ́ ìpàdé;
41 àwọn aṣọ tí wọ́n hun dáadáa láti máa fi ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ ti àlùfáà Áárónì+ àti àwọn aṣọ tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa fi ṣiṣẹ́ àlùfáà.
42 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo iṣẹ́ náà bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.+
43 Nígbà tí Mósè yẹ gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe wò, ó rí i pé wọ́n ṣe é gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ; Mósè sì súre fún wọn.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
^ Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). Wo Àfikún B14.
^ Òkúta iyebíye kan tí a ò mọ bó ṣe rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òkúta áńbérì, háyásíǹtì, ópálì tàbí tọ́málínì.
^ Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
^ Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
^ Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Tàbí “adé mímọ́.”
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
^ Tàbí “ayanran.”
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”