Ẹ́kísódù 29:1-46

  • Fífi iṣẹ́ lé àwọn àlùfáà lọ́wọ́ (1-37)

  • Ọrẹ ojoojúmọ́ (38-46)

29  “Ohun tí o máa ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi nìyí: Mú ọmọ akọ màlúù kan, àgbò méjì tí kò ní àbùkù,+  búrẹ́dì aláìwú, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+ Ìyẹ̀fun àlìkámà* tó kúnná ni kí o fi ṣe wọ́n.  kí o wá kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì fi apẹ̀rẹ̀ náà gbé e wá,+ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà.  “Kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+  Kí o wá kó àwọn aṣọ náà,+ kí o sì wọ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ fún Áárónì, pẹ̀lú aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tó máa wà lábẹ́ éfódì, kí o wọ éfódì náà fún un àti aṣọ ìgbàyà, kí o sì so àmùrè éfódì tí wọ́n hun* náà mọ́ ìbàdí rẹ̀ pinpin.+  Kí o wé láwàní náà sí i lórí, kí o sì fi àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́* sára láwàní náà;+  kí o mú òróró àfiyanni,+ kí o sì dà á sí i lórí láti fòróró yàn án.+  “Kí o wá mú àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, kí o sì wọ aṣọ fún wọn,+  kí o fi àwọn ọ̀já náà di Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lámùrè, kí o sì wé aṣọ sí wọn lórí; àwọn ni yóò máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà, kí èyí jẹ́ ìlànà tó máa wà títí láé.+ Bí o ṣe máa sọ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ di àlùfáà* nìyí.+ 10  “Kí o mú akọ màlúù náà wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ màlúù náà.+ 11  Kí o pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 12  Fi ìka rẹ mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, kí o fi sórí àwọn ìwo pẹpẹ,+ kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 13  Kí o wá mú gbogbo ọ̀rá+ tó bo ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn, kí o fi iná sun wọ́n kí wọ́n lè rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 14  Àmọ́ kí o fi iná sun ẹran akọ màlúù náà pẹ̀lú awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde àgọ́. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 15  “Kí o wá mú ọ̀kan lára àwọn àgbò náà, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 16  Kí o pa àgbò náà, kí o mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 17  Gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ ìfun rẹ̀+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì to àwọn ègé ẹran náà pẹ̀lú orí rẹ̀. 18  Kí o sun àgbò náà lódindi, jẹ́ kó rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ló jẹ́ sí Jèhófà, olóòórùn dídùn.*+ Ó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 19  “Lẹ́yìn náà, kí o mú àgbò kejì, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 20  Kí o pa àgbò náà, kí o mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún àwọn ọmọ rẹ̀, kí o tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, kí o sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà. 21  Kí o wá mú lára ẹ̀jẹ̀ tó wà lórí pẹpẹ àti lára òróró àfiyanni náà,+ kí o sì wọ́n ọn sára Áárónì àti aṣọ rẹ̀ àti sára àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn, kí òun àti aṣọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn lè jẹ́ mímọ́.+ 22  “Kí o yọ ọ̀rá lára àgbò náà, kí o gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá, ọ̀rá tó bo ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn,+ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún, torí ó jẹ́ àgbò àfiyanni.+ 23  Kí o tún mú búrẹ́dì ribiti kan àti búrẹ́dì tí wọ́n fi òróró sí tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan látinú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó wà níwájú Jèhófà. 24  Kí o kó gbogbo wọn sí ọwọ́ Áárónì àti sí ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà. 25  Kí o wá gbà á lọ́wọ́ wọn, kí o sì sun ún lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun, kó lè mú òórùn dídùn* jáde níwájú Jèhófà. Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ló jẹ́. 26  “Kí o gé igẹ̀ àgbò àfiyanni náà,+ tí o fi rúbọ torí Áárónì, kí o sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, yóò sì di ìpín tìrẹ. 27  Kí o ya igẹ̀ ọrẹ fífì náà sí mímọ́, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ tí o fì, èyí tí o gé lára àgbò àfiyanni náà,+ látinú ohun tí o fi rúbọ torí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. 28  Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa pa mọ́ títí láé, torí ìpín mímọ́ ló jẹ́, yóò sì di ìpín mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa fún wọn.+ Ìpín mímọ́ wọn fún Jèhófà ni, látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wọn.+ 29  “Àwọn aṣọ mímọ́+ tó jẹ́ ti Áárónì ni àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa lò+ tí wọ́n bá ti fòróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì di àlùfáà. 30  Kí àlùfáà tó bá rọ́pò rẹ̀ lára àwọn ọmọ rẹ̀ tó sì wá sínú àgọ́ ìpàdé láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ wọ àwọn aṣọ náà fún ọjọ́ méje.+ 31  “Kí o mú àgbò àfiyanni, kí o sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́.+ 32  Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ+ ẹran àgbò náà àti búrẹ́dì tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 33  Kí wọ́n jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti sọ wọ́n di àlùfáà,* kí wọ́n sì di mímọ́. Àmọ́ ẹni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i* ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, torí ohun mímọ́ ni.+ 34  Bí èyíkéyìí nínú ẹran tí o fi rú ẹbọ ìyannisípò àti búrẹ́dì náà bá ṣẹ́ kù di àárọ̀, kí o fi iná sun ohun tó ṣẹ́ kù.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, torí ohun mímọ́ ni. 35  “Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ yìí ni kí o ṣe fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ọjọ́ méje ni kí o lò láti sọ wọ́n di àlùfáà.*+ 36  Kí o máa fi akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rúbọ lójoojúmọ́ láti fi ṣe ètùtù, kí o sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára rẹ̀, kí o sì fòróró yàn án láti sọ ọ́ di mímọ́.+ 37  Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà, kí o sì sọ ọ́ di mímọ́ kó lè di pẹpẹ mímọ́ jù lọ.+ Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan pẹpẹ náà ti gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. 38  “Ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà nìyí: ọmọ àgbò méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan lójoojúmọ́ títí lọ.+ 39  Kí o fi ọmọ àgbò kan rúbọ ní àárọ̀, kí o sì fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́.*+ 40  Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì. 41  Kí o fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́,* pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu kan náà bíi ti àárọ̀. Kí o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 42  Kí ẹ máa rú ẹbọ sísun yìí nígbà gbogbo jálẹ̀ àwọn ìran yín ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Jèhófà, níbi tí màá ti pàdé yín láti bá yín sọ̀rọ̀.+ 43  “Màá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níbẹ̀, ògo mi yóò sì sọ ọ́ di mímọ́.+ 44  Màá sọ àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ di mímọ́, màá sì sọ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀+ di mímọ́, kí wọ́n lè di àlùfáà mi. 45  Èmi yóò máa gbé láàárín* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 46  Ó sì dájú pé wọ́n á mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì kí n lè máa gbé láàárín wọn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “adé mímọ́.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ Áárónì àti ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ wọn.”
Ní Héb., “àjèjì,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ wọn.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “pàgọ́ sí àárín.”