Àìsáyà 8:1-22
8 Jèhófà sọ fún mi pé: “Mú wàláà+ ńlá kan, kí o sì fi kálàmù lásán,* kọ ‘Maheri-ṣalali-háṣí-básì’* sára rẹ̀.
2 Mo fẹ́ rí i dájú pé àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fọwọ́ sí i,* ìyẹn àlùfáà Ùráyà+ àti Sekaráyà ọmọ Jeberekáyà.”
3 Lẹ́yìn náà, mo bá wòlíì obìnrin náà* ní àṣepọ̀,* ó sì lóyún, ó wá bí ọmọkùnrin kan.+ Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Sọ ọmọ náà ni Maheri-ṣalali-háṣí-básì,
4 torí kí ọmọ náà tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe, ‘Bàbá mi!’ àti ‘Ìyá mi!’ wọ́n máa kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù àti ẹrù ogun Samáríà lọ níwájú ọba Ásíríà.”+
5 Jèhófà tún sọ fún mi pé:
6 “Torí pé àwọn èèyàn yìí ti pa omi Ṣílóà* tó rọra ń ṣàn tì,+Tí wọ́n sì ń yọ̀ torí Résínì àti ọmọ Remaláyà,+
7 Torí náà, wò ó! Jèhófà máa mú kíIbú omi Odò ńlá* náà ya lù wọ́n,Ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.
Ó máa wá sórí gbogbo ibi tí omi rẹ̀ ń ṣàn gbà,Ó máa kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,
8 Ó sì máa rọ́ gba Júdà kọjá.
Ó máa kún bò ó, ó sì máa gbà á kọjá, ó máa kún dé ọrùn rẹ̀;+Ìyẹ́ rẹ̀ tó nà jáde máa bo ìbú ilẹ̀ rẹ,Ìwọ Ìmánúẹ́lì!”*+
9 Ẹ ṣe wọ́n léṣe, ẹ̀yin èèyàn, àmọ́ a máa fọ́ ẹ̀yin náà sí wẹ́wẹ́.
Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wá láti apá ibi tó jìnnà ní ayé!
Ẹ múra ogun,* àmọ́ a máa fọ́ yín sí wẹ́wẹ́!+
Ẹ múra ogun, àmọ́ a máa fọ́ yín sí wẹ́wẹ́!
10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, àmọ́ a máa dà á rú!
Ẹ sọ ohun tó wù yín, àmọ́ kò ní yọrí sí rere,Torí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!*+
11 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lára mi, ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, láti kìlọ̀ fún mi kí n má bàa tẹ̀ lé ọ̀nà àwọn èèyàn yìí:
12 “Tí àwọn èèyàn yìí bá ń pe nǹkan ní ọ̀tẹ̀, ẹ ò gbọ́dọ̀ pè é ní ọ̀tẹ̀!
Ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n bẹ̀rù;Ẹ má ṣe jẹ́ kó kó jìnnìjìnnì bá yín.
13 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ẹni tó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́,+Òun ni Ẹni tó yẹ kí ẹ bẹ̀rù,Òun sì ni Ẹni tó yẹ kó mú kí ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì.”+
14 Ó máa dà bí ibi mímọ́,Àmọ́ ó máa dà bí òkúta tí wọ́n á kọ lùÀti àpáta tó ń múni kọsẹ̀+Fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì,Bíi pańpẹ́ àti ìdẹkùn,Fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.
15 Ọ̀pọ̀ nínú wọn máa kọsẹ̀, wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì fọ́;Wọ́n máa dẹkùn fún wọn, ọwọ́ á sì tẹ̀ wọ́n.
16 Ká ẹ̀rí tó wà lákọsílẹ̀;*Gbé èdìdì lé òfin* náà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi!
17 Màá máa dúró de* Jèhófà,+ ẹni tó ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ilé Jékọ́bù,+ màá sì ní ìrètí nínú rẹ̀.
18 Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ tí Jèhófà fún mi+ dà bí àmì+ àti iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ẹni tó ń gbé lórí Òkè Síónì.
19 Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò tàbí àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àwọn tó ń ké ṣíoṣío, tí wọ́n sì ń jẹnu wúyẹ́wúyẹ́,” ṣebí ọwọ́ Ọlọ́run wọn ló yẹ kí àwọn èèyàn ti lọ wádìí? Ṣé ó yẹ kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú nítorí alààyè?+
20 Kàkà bẹ́ẹ̀, inú òfin àti ẹ̀rí tó wà ní àkọsílẹ̀* ló yẹ kí wọ́n ti wádìí!
Tí wọn ò bá sọ ohun tó bá ọ̀rọ̀ yìí mu, wọn ò ní ìmọ́lẹ̀.*+
21 Kálukú máa gba ilẹ̀ náà kọjá, ìyà á jẹ wọ́n, ebi á sì pa wọ́n;+ torí ebi tó ń pa á àti inú tó ń bí i, á máa gégùn-ún fún ọba rẹ̀ àti Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe ń wòkè.
22 Ó máa wá wo ayé, ìdààmú àti òkùnkùn nìkan ló sì máa rí, ìríran bàìbàì àti àkókò tó le, ìṣúdùdù, láìsí ìmọ́lẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Yára Sún Mọ́ Ẹrù Ogun, Tètè Lọ Síbi Ẹrù Ogun.”
^ Ní Héb., “kálámù ẹni kíkú.”
^ Tàbí “jẹ́rìí sí i; kọ̀wé sí i.”
^ Ìyẹn, ìyàwó Àìsáyà.
^ Ní Héb., “sún mọ́ wòlíì obìnrin náà.”
^ Ṣílóà ni ibi tí omi ń gbà kọjá.
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Tàbí “Ẹ dira.”
^ Tàbí “àkọsílẹ̀ tí wọ́n jẹ́rìí sí.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Tàbí “fojú sọ́nà fún.”
^ Tàbí “àkọsílẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ sí.”
^ Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀ àárọ̀.”