Àìsáyà 61:1-11
61 Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi,+Torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+
Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,Láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú,Pé ojú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì máa là rekete,+
2 Láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà* JèhófàÀti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa,+Láti tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú,+
3 Láti pèsè fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ torí Síónì,Láti fún wọn ní ìwérí dípò eérú,Òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,Aṣọ ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.
A ó sì máa pè wọ́n ní igi ńlá òdodo,Tí Jèhófà gbìn, kó lè ṣe é lógo.*+
4 Wọ́n máa tún àwọn ibi tó ti pa run nígbà àtijọ́ kọ́;Wọ́n máa kọ́ àwọn ibi tó ti dahoro nígbà àtijọ́,+Wọ́n sì máa mú kí àwọn ìlú tó ti pa run pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀,+Àwọn ibi tó ti wà ní ahoro láti ìran dé ìran.+
5 “Àwọn àjèjì máa dúró, wọ́n sì máa tọ́jú àwọn agbo ẹran yín,Àwọn àlejò + máa jẹ́ àgbẹ̀ yín, wọ́n á sì máa bá yín rẹ́wọ́ àjàrà.+
6 Ní tiyín, a ó máa pè yín ní àlùfáà Jèhófà;+Wọ́n á máa pè yín ní òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ máa jẹ ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+Ẹ sì máa fi ògo* wọn yangàn.
7 Dípò ìtìjú, ẹ máa ní ìpín ìlọ́po méjì,Dípò ìdójútì, wọ́n máa kígbe ayọ̀ nítorí ìpín wọn.
Àní, ìpín ìlọ́po méjì ni wọ́n máa gbà ní ilẹ̀ wọn.+
Wọ́n á máa yọ̀ títí ayérayé.+
8 Torí èmi Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo;+Mo kórìíra olè jíjà àti àìṣòdodo.+
Màá fi òótọ́ san èrè iṣẹ́ wọn fún wọn,Màá sì bá wọn dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé.+
9 Wọ́n máa mọ àwọn ọmọ* wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè +Àti àtọmọdọ́mọ wọn láàárín àwọn èèyàn.
Gbogbo àwọn tó bá rí wọn máa dá wọn mọ̀,Pé àwọn ni ọmọ* tí Jèhófà bù kún.”+
10 Màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà.
Gbogbo ara mi* máa yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.+
Torí ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí;+Ó ti fi aṣọ òdodo* bò mí lára,Bí ọkọ ìyàwó tó wé láwàní bíi ti àlùfáà+Àti bí ìyàwó tó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.
11 Torí bí ilẹ̀ ṣe ń mú irúgbìn jáde,Tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí wọ́n gbìn sínú rẹ̀ hù,Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Olúwa Ọba AláṣẹṢe máa mú kí òdodo+ àti ìyìn rú jáde+ níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ojúure.”
^ Tàbí “kó lè bu ẹwà kún un.”
^ Tàbí “ọrọ̀.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “Ọkàn mi.”
^ Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè òdodo tí kò lápá.”