Àìsáyà 27:1-13

  • Jèhófà pa Léfíátánì (1)

  • Orin tó fi Ísírẹ́lì wé ọgbà àjàrà (2-13)

27  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà, tòun ti idà rẹ̀ tó mú, tó tóbi, tó sì lágbára,+Máa yíjú sí Léfíátánì,* ejò tó ń yọ́ bọ́rọ́,Sí Léfíátánì, ejò tó ń lọ́,Ó sì máa pa ẹran ńlá tó wà nínú òkun.   Ní ọjọ́ yẹn, ẹ kọrin fún obìnrin náà* pé: “Ọgbà àjàrà tí wáìnì rẹ̀ ń yọ ìfófòó!+   Èmi, Jèhófà ń dáàbò bò ó.+ Gbogbo ìgbà ni mò ń bomi rin ín.+ Mò ń dáàbò bò ó tọ̀sántòru,Kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣe é léṣe.+   Mi ò bínú rárá.+ Ta ló máa wá fi àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò bá mi jagun? Gbogbo wọn ni màá tẹ̀ mọ́lẹ̀, tí màá sì dáná sun pa pọ̀.   Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó rọ̀ mọ́ ibi ààbò mi. Kó wá bá mi ṣàdéhùn àlàáfíà;Àní kó wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”   Lọ́jọ́ iwájú, Jékọ́bù máa ta gbòǹgbò,Ísírẹ́lì máa yọ ìtànná, ó máa rú jáde,+Wọ́n sì máa fi irè oko kún ilẹ̀ náà.+   Ṣé dandan ni kí a fi ẹgba ẹni tó ń lù ú nà án ni? Àbí ṣé dandan ni kí a pa á bí àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n pa?   Igbe tó ń dẹ́rù bani lo máa fi bá a fà á nígbà tí o bá lé e lọ. Atẹ́gùn rẹ̀ tó le ló máa fi lé e jáde ní ọjọ́ afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn.+   Torí náà, báyìí la ṣe máa ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ Jékọ́bù,+Èyí sì ni ohun tó máa jèrè lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nígbà tí a bá mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò: Ó máa ṣe gbogbo òkúta pẹpẹ Bí òkúta ẹfun tí wọ́n lọ̀ lúúlúú,Òpó òrìṣà* àti pẹpẹ tùràrí kankan ò sì ní ṣẹ́ kù.+ 10  Torí wọ́n máa pa ìlú olódi tì;Wọ́n máa pa àwọn ibi ìjẹko tì, wọ́n á sì fi í sílẹ̀ bí aginjù.+ Ibẹ̀ ni ọmọ màlúù á ti máa jẹko, tó sì máa dùbúlẹ̀ sí,Ó sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+ 11  Nígbà tí àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ bá ti gbẹ,Àwọn obìnrin máa wá ṣẹ́ wọn,Wọ́n á sì fi dáná. Torí àwọn èèyàn yìí ò ní òye.+ Ìdí nìyẹn tí Aṣẹ̀dá wọn ò fi ní ṣàánú wọn rárá,Ẹni tó dá wọn ò sì ní ṣojúure kankan sí wọn.+ 12  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lu èso jáde láti Odò* tó ń ṣàn títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ a sì máa kó yín jọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì.+ 13  Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa fun ìwo ńlá kan,+ àwọn tó ń ṣègbé lọ ní ilẹ̀ Ásíríà+ àti àwọn tó fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì+ máa wá, wọ́n á sì forí balẹ̀ fún Jèhófà ní òkè mímọ́, ní Jerúsálẹ́mù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó jọ pé Ísírẹ́lì ló ń tọ́ka sí, ó pè é ní obìnrin, ó sì fi wé ọgbà àjàrà.
Ìyẹn, odò Yúfírétì.