Àìsáyà 18:1-7

  • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Etiópíà (1-7)

18  Ilẹ̀ tí ìyẹ́ àwọn kòkòrò ti ń kùn yùnmù gbé,Ní agbègbè àwọn odò Etiópíà!+   Ó ń rán àwọn aṣojú gba ojú òkun,Wọ́n gba orí omi nínú àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi òrépèté ṣe, ó ní: “Ẹ lọ, ẹ̀yin ìránṣẹ́ tó yára kánkán,Sí orílẹ̀-èdè tó ga, tí ara rẹ̀ sì ń dán,*Sí àwọn èèyàn tí wọ́n ń bẹ̀rù níbi gbogbo,+Sí orílẹ̀-èdè tó lágbára, tó máa ń ṣẹ́gun,*Tí àwọn odò ti wọ́ ilẹ̀ rẹ̀ lọ.”   Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ náà àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ayé,Ohun tí ẹ máa rí máa dà bí àmì* tí wọ́n gbé sókè lórí àwọn òkè,Ẹ sì máa gbọ́ ìró tó dà bí ìgbà tí wọ́n ń fun ìwo.   Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Màá wà láìsí ẹni tó máa yọ mí lẹ́nu, màá sì máa wo* ibi tí mo fìdí múlẹ̀ sí,Bí ooru tó rọra ń mú nínú ìtànṣán oòrùn,Bí ìrì tó ń sẹ̀ látinú ìkùukùu* nínú ooru ìgbà ìkórè.   Torí kó tó di ìgbà ìkórè,Tí ìtànná bá yọ tán, tí ìtànná òdòdó sì ti di èso àjàrà tó pọ́n,Wọ́n máa fi ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn gé àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ kúrò,Wọ́n máa gé àwọn ọwọ́ rẹ̀ kúrò, wọ́n á sì kó o dà nù.   Wọ́n á fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ aṣọdẹ lórí òkèÀti àwọn ẹranko orí ilẹ̀. Orí wọn ni àwọn ẹyẹ aṣọdẹ ti máa lo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,Gbogbo ẹranko orí ilẹ̀ sì máa lo ìgbà ìkórè lórí wọn.   Ní àkókò yẹn, wọ́n máa mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Látọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè tó ga, tí ara rẹ̀ sì ń dán,*Látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń bẹ̀rù níbi gbogbo,Látọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè tó lágbára, tó máa ń ṣẹ́gun,*Tí àwọn odò ti wọ́ ilẹ̀ rẹ̀ lọSí ibi tó ń jẹ́ orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Òkè Síónì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “tí a fà sókè, tí a sì bó lára.”
Tàbí “tó lókun dáadáa, tó sì ń tẹni mọ́lẹ̀.”
Tàbí “òpó tí wọ́n fi ṣe àmì.”
Tàbí kó jẹ́, “wò láti.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “tí a fà sókè, tí a sì bó lára.”
Tàbí “tó lókun dáadáa, tó sì ń tẹni mọ́lẹ̀.”