Jóṣúà 3:1-17

3  Jóṣúà sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, òun àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí kúrò ní Ṣítímù,+ wọ́n sì lọ títí dé Jọ́dánì; wọ́n sì sùn ibẹ̀ mọ́jú, kí wọ́n tó sọdá.  Nítorí náà, ó wá ṣẹlẹ̀ ní òpin ọjọ́ mẹ́ta+ pé, àwọn onípò àṣẹ+ bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ní àárín ibùdó,  wọ́n sì ń pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Gbàrà tí ẹ bá ti rí àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, àti àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léf ì, tí ó rù ú,+ nígbà náà ni kí ẹ̀yin fúnra yín ṣí kúrò ní àyè yín, kí ẹ sì tẹ̀ lé e, 4​ —⁠kìkì pé kí ẹ jẹ́ kí àlàfo tí ó tó nǹkan bí ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ ní ìwọ̀n+ wà láàárín ti ẹ̀yin tirẹ̀; ẹ má ṣe sún mọ́ ọn⁠—​kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà lọ, nítorí ẹ̀yin kò tí ì gba ọ̀nà yẹn kọjá rí.”  Wàyí o, Jóṣúà wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ sọ ara yín di mímọ́,+ nítorí ní ọ̀la, Jèhófà yóò ṣe àwọn ohun àgbàyanu láàárín yín.”+  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà wí fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gbé àpótí májẹ̀mú+ náà, kí ẹ sì kọjá sí iwájú àwọn ènìyàn náà.” Nítorí náà, wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú náà, wọ́n sì lọ sí iwájú àwọn ènìyàn náà.  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Jóṣúà pé: “Òní yìí ni èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí mú kí o di ẹni ńlá ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí èmi ti wà pẹ̀lú Mósè+ ni èmi yóò ṣe wà pẹ̀lú rẹ.+  Àti pé ìwọ​—⁠kí ìwọ pàṣẹ+ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí májẹ̀mú náà pé, ‘Gbàrà tí ẹ bá ti lọ títí dé etí omi Jọ́dánì, kí ẹ dúró+ jẹ́ẹ́ ní Jọ́dánì.’ ”  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ sún mọ́ ìhín, kí ẹ sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín.” 10  Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà wí pé: “Nípa èyí ni ẹ ó fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè kan wà láàárín+ yín, àti pé, láìkùnà, òun yóò lé àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Híf ì àti àwọn Pérísì àti àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn Ámórì àti àwọn ará Jébúsì+ kúrò níwájú yín. 11  Wò ó! Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé ń ṣíwájú yín kọjá sínú Jọ́dánì. 12  Wàyí o, ẹ mú ọkùnrin méj ì lá fún ara yín láti inú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.+ 13  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ní kété tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Jèhófà, Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé, bá ti kanlẹ̀ nínú omi Jọ́dánì, omi Jọ́dánì ni a óò ké kúrò, omi tí ń ṣàn wálẹ̀ láti òkè, yóò sì dúró jẹ́ẹ́ bí ìsédò.”+ 14  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ènìyàn náà ṣí kúrò nínú àgọ́ wọn ní gẹ́rẹ́ ṣáájú ríré Jọ́dánì kọjá, tí àwọn àlùfáà ru àpótí+ májẹ̀mú ní iwájú àwọn ènìyàn náà, 15  àti ní kété tí àwọn olùru Àpótí náà ti lọ títí dé Jọ́dánì, tí àwọn àlùfáà tí ó ru Àpótí náà sì tẹ ẹsẹ̀ wọn bọ etí omi náà (wàyí o, Jọ́dánì kún bo gbogbo bèbè+ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ìkórè), 16  ìgbà náà ni omi tí ń ṣàn wálẹ̀ láti òkè bẹ̀rẹ̀ sí dúró jẹ́ẹ́. Ó dìde dúró bí ìsédò+ kan tí ó j ì nnà réré gan-⁠an ní Ádámù, ìlú ńlá tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì,+ nígbà tí èyí tí ń ṣàn wálẹ̀ síhà òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,+ gbẹ táútáú. A ké wọn kúrò, àwọn ènìyàn náà sì ré kọjá ní iwájú Jẹ́ríkò. 17  Láàárín àkókò náà, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí májẹ̀mú Jèhófà ń bá a lọ ní dídúró láìṣeé-ṣínípò lórí ilẹ̀ gbígbẹ+ ní àárín Jọ́dánì, bí gbogbo Ísírẹ́lì tí ń ré kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi parí ríré Jọ́dánì kọjá.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé