Jóṣúà 18:1-28

18  Nígbà náà ni gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé jọpọ̀ ní Ṣílò,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àgọ́ ìpàdé kalẹ̀ níbẹ̀,+ nítorí a ti tẹ ilẹ̀ náà lórí ba níwájú wọn wàyí.+  Ṣùgbọ́n ó ṣì kù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn kò tí ì pín ogún fún, èyíinì jẹ́, ẹ̀yà méje.  Nítorí náà, Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa lọ́ tìkọ̀ nípa wíwọlé láti gba ilẹ̀+ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín fi fún yín?+  Ẹ mú ọkùnrin mẹ́ta jáde láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí èmi sì rán wọn jáde, kí wọ́n lè dìde, kí wọ́n sì rìn káàkiri ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ṣètò ìpín rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ogún wọn, kí wọ́n sì wá sọ́dọ̀ mi.+  Kí wọ́n sì pín in láàárín ara wọn sí ìpín méje.+ Júdà yóò dúró sórí ìpínlẹ̀ rẹ̀ níhà gúúsù,+ ilé Jósẹ́fù yóò sì máa bá a nìṣó láti dúró sórí ìpínlẹ̀ wọn níhà àríwá.+  Ní tiyín, ẹ ó ṣètò ìpín ilẹ̀ náà sí ìpín méje, kí ẹ sì mú wọn wá síhìn-⁠ín lọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì ṣẹ́ kèké+ níhìn-⁠ín fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa.  Nítorí àwọn ọmọ Léf ì kò ní ìpín láàárín yín,+ nítorí pé iṣẹ́ àlùfáà Jèhófà ni ogún+ wọn; Gádì àti Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ti gba ogún wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì níhà ìlà-oòrùn, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fi fún wọn.”+  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin náà dìde láti lọ, Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí pàṣẹ+ fún àwọn tí yóò lọ ṣètò ìpín ilẹ̀ náà pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì rìn káàkiri ní ilẹ̀ náà, kí ẹ ṣètò ìpín rẹ̀, kí ẹ sì padà sọ́dọ̀ mi, ìhín sì ni ibi tí èmi yóò ti ṣẹ́ kèké+ fún yín níwájú Jèhófà ní Ṣílò.”+  Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà kọjá, wọ́n sì ṣètò ìpín+ rẹ̀ ní ìlú ńlá, ìlú ńlá, sí ìpín méje, sínú ìwé kan. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wá sọ́dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ní Ṣílò, 10  Jóṣúà sì ṣẹ́ kèké fún wọn ní Ṣílò níwájú Jèhófà.+ Nípa báyìí, níbẹ̀ ni Jóṣúà ti pín ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti inú ìpín+ wọn. 11  Nígbà náà ni kèké+ yan ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ nípa ìdílé wọn, ìpínlẹ̀ ìpín wọn sì wà láàárín àwọn ọmọ Júdà+ àti àwọn ọmọ Jósẹ́fù.+ 12  Ààlà wọn sì wá wà ní igun ìhà àríwá láti Jọ́dánì, ààlà náà sì gòkè lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò+ ní àríwá, ó sì gòkè lọ dé òkè ńlá ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi tí ó sì dópin sí ni aginjù Bẹti-áfénì.+ 13  Ààlà náà sì ré kọjá láti ibẹ̀ lọ sí Lúsì,+ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìhà gúúsù Lúsì, èyíinì ni, Bẹ́tẹ́lì;+ ààlà náà sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ataroti-ádárì+ lórí òkè ńlá tí ó wà ní gúúsù Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀.+ 14  A sì sàmì sí ààlà náà, ó sì yí lọ ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀-oòrùn dé ìhà gúúsù láti ibi òkè ńlá tí ó dojú kọ Bẹti-hórónì síhà gúúsù; ibi tí ó sì dópin sí ni Kiriati-báálì, èyíinì ni, Kiriati-jéárímù,+ ìlú ńlá àwọn ọmọ Júdà. Èyí ni ẹ̀gbẹ́ ti ìwọ̀-oòrùn. 15  Ẹ̀gbẹ́ ti gúúsù sì jẹ́ láti ìkángun Kiriati-jéárímù, ààlà náà sì lọ síhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì lọ dé ìsun omi Néfítóà.+ 16  Ààlà náà sì sọ̀ kalẹ̀ lọ dé ìkángun òkè ńlá tí ó dojú kọ àfonífoj ì àwọn ọmọ Hínómù,+ èyí tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Réfáímù+ ní ìhà àríwá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ dé àfonífoj ì Hínómù, lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ẹ́ń-rógélì.+ 17  A sì sàmì sí i lọ síhà àríwá, ó sì jáde sí Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì àti jáde lọ sí Gélílótì, èyí tí ó wà ní iwájú ìgòkè Ádúmímù;+ ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ dé òkúta+ Bóhánì+ ọmọkùnrin Rúbẹ́nì. 18  Ó sì ré kọjá sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìhà àríwá ní iwájú Árábà, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ dé Árábà. 19  Ààlà náà sì ré kọjá sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìhà àríwá Bẹti-hógílà,+ (ojú ààlà) ibi tí ó dópin sí sì jẹ́ ìyawọ̀ omi ìhà àríwá Òkun Iyọ̀,+ ní ìpẹ̀kun ìhà gúúsù Jọ́dánì. Èyí ni ààlà ìhà gúúsù. 20  Jọ́dánì sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti ìhà ìlà-oòrùn. Èyí ni ogún àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì nípa àwọn ìdílé wọn, nípa àwọn ààlà rẹ̀ ní gbogbo àyíká. 21  Àwọn ìlú ńlá ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì nípa àwọn ìdílé wọn sì jẹ́ Jẹ́ríkò+ àti Bẹti-hógílà àti Emeki-késísì, 22  àti Bẹti-árábà+ àti Sémáráímù àti Bẹ́tẹ́lì,+ 23  àti Áfímù àti Párà àti Ọ́fírà,+ 24  àti Kefari-ámónì àti Ófínì àti Gébà;+ ìlú ńlá méj ì lá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 25  Gíbéónì+ àti Rámà àti Béérótì, 26  àti Mísípè+ àti Kéfírà+ àti Mósáhì, 27  àti Rékémù àti Iripéélì àti Tárálà, 28  àti Séélà,+ Ha-éléf ì àti Jẹ́búsì, èyíinì ni, Jerúsálẹ́mù,+ Gíbí à+ àti Kíríátì; ìlú ńlá mẹ́rìnlá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. Èyí ni ogún àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì nípa àwọn ìdílé wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé