Jóòbù 6:1-30
6 Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Ì bá ṣe pé a díwọ̀n ìbìnújẹ́+ mi látòkè délẹ̀,Wọn ì bá sì gbé àgbákò mi lé orí òṣùwọ̀n lẹ́ẹ̀kan náà!
3 Nítorí ó tilẹ̀ wúwo ju iyanrìn òkun nísinsìnyí.Ìdí nìyẹn tí àwọn ọ̀rọ̀ mi fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹhànnà.+
4 Nítorí pé àwọn ọfà Olódùmarè ń bẹ pẹ̀lú mi,+Oró èyí tí ẹ̀mí mi ń mu;+Ìpayà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run to ara wọn gẹ̀ẹ̀rẹ̀ lòdì sí mi.+
5 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ yóò ha ké jáde lórí koríko,Tàbí kẹ̀, akọ màlúù yóò ha ké mùúù lórí oúnjẹ rẹ̀?
6 A ha lè jẹ ohun tí kò dùn láìsí iyọ̀,Tàbí adùn èyíkéyìí ha wà nínú omi yíyọ̀ gbọ̀lọ̀ ti ewébẹ̀ máṣìmalò?
7 Ọkàn mi kọ̀ láti fọwọ́ kan ohunkóhun.Wọ́n dà bí òkùnrùn nínú oúnjẹ mi.
8 Ì bá ṣe pé ìbéèrè mi dé,Kí Ọlọ́run sì fi ìrètí mi pàápàá fún mi!
9 Ọlọ́run ì bá tẹ̀ síwájú, kí ó tẹ̀ mí rẹ́,Òun ì bá tú ọwọ́ rẹ̀, kí ó sì ké mi kúrò!+
10 Àní yóò ṣì jẹ́ ìtùnú mi;Èmi yóò sì tọ sókè fún ìdùnnú+ nígbà ìrora ìrọbí mi,Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kì yóò ní ìyọ́nú, nítorí èmi kò fi àwọn àsọjáde+ Ẹni Mímọ́+ pa mọ́.
11 Kí ni agbára mi, tí èmi yóò fi máa dúró?+Kí sì ni òpin mi, tí èmi yóò fi máa fa ọkàn mi gùn?
12 Agbára mi ha jẹ́ agbára òkúta bí?Tàbí ara mi ha jẹ́ bàbà bí?
13 Ṣé agbára ríran ara ẹni lọ́wọ́ kò sí nínú mi ni,Tí a sì lé ìṣiṣẹ́yọrí lọ kúrò lọ́dọ̀ mi?
14 Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó fawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀,+Òun yóò pa àní ìbẹ̀rù Olódùmarè tì pẹ̀lú.+
15 Àwọn arákùnrin mi ti ṣe àdàkàdekè,+ bí ọ̀gbàrá ìgbà òtútù,Bí ojú ọ̀gbàrá ìgbà òtútù tí ń kọjá lọ ṣáá.
16 Omi dídì mú wọn ṣókùnkùn,Ìrì dídì fara pa mọ́ sórí wọn.
17 Ní àsìkò yíyẹ, wọn a di aláìlómi,+ a ti pa wọ́n lẹ́nu mọ́;Nígbà tí ó gbóná, wọ́n gbẹ dànù kúrò ní ipò wọn.+
18 Ipa ọ̀nà wọn ni a yí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan;Wọn a gòkè lọ sí ibi ṣíṣófo, wọn a sì ṣègbé.
19 Ọ̀wọ́ èrò Témà+ ti wò,Àwùjọ àwọn Sábéà+ tí ń rin ìrìn àjò ti dúró dè wọ́n.
20 Dájúdájú, ojú tì wọ́n nítorí pé wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé;Wọ́n ti wá títí dé ibẹ̀, a sì já wọn kulẹ̀.+
21 Nítorí ẹ kò jámọ́ nǹkan kan nísinsìnyí;+Ẹ rí ìpayà, àyà sì fò yín.+
22 Ṣé nítorí tí mo sọ pé, ‘Ẹ fún mi ní nǹkan,Tàbí pé kí ẹ ṣe ìtọrẹ nítorí mi láti inú agbára yín;
23 Kí ẹ sì gbà mí lọ́wọ́ elénìní,+Kí ẹ sì tún mi rà padà kúrò lọ́wọ́ àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀’?+
24 Ẹ fún mi ní ìtọ́ni, àní èmi, ní tèmi, yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́;+Kí ẹ sì mú mi lóye àṣìṣe tí mo bá ṣe.+
25 Àwọn àsọjáde ìdúróṣánṣán—kò roni lára rárá!+Ṣùgbọ́n kí ni ìfìbáwítọ́sọ́nà ní ìhà ọ̀dọ̀ yín fi ìbáwí tọ́ sọ́nà?+
26 Ṣé àtifi ìbáwí tọ́ àwọn ọ̀rọ̀ sọ́nà ni ẹ ń pète-pèrò ni,Nígbà tí àwọn àsọjáde ẹni tí ó wà nínú ìbọ́hùn+ wà fún ẹ̀fúùfù lásán-làsàn?+
27 Mélòómélòó ni ẹ óò ṣẹ́ kèké lórí ẹni tí ó jẹ́ aláìníbaba+ pàápàá,Tí ẹ ó sì fi alábàákẹ́gbẹ́ yín gba ìpààrọ̀!+
28 Wàyí o, ẹ tẹ̀ síwájú, ẹ fetí sí mi,Kí ẹ sì [rí i] bóyá èmi yóò purọ́ ní ojú yín gan-an.+
29 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ padà—ẹ má ṣe jẹ́ kí àìṣòdodo kankan yọjú—Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ padà—òdodo mi ṣì ń bẹ nínú rẹ̀.+
30 Àìṣòdodo ha wà ní ahọ́n mi,Tàbí òkè ẹnu mi kò ha fi òye mọ àgbákò?