Jóòbù 4:1-21

4  Élífásì+ ará Témánì sì bẹ̀rẹ̀ sí fèsì, ó sì wí pé:   “Bí ẹnì kan bá fi ọ̀rọ̀ dán ọ wò, àárẹ̀ yóò ha mú ọ bí?Ṣùgbọ́n ta ní lè sé ọ̀rọ̀ mọ́nú?   Wò ó! O ti tọ́ ọ̀pọ̀ sọ́nà,+Ọwọ́ aláìlera ni o sì ti fún lókun rí.+   Ọ̀rọ̀ rẹ ń gbé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọsẹ̀ dìde;+Àwọn eékún tí ń yẹ̀ lọ ni ìwọ sì ń mú le gírígírí.+   Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, ó dé bá ọ, àárẹ̀ sì mú ọ;Ó kan ìwọ alára, ìyọlẹ́nu sì dé bá ọ.   Ìfọkànsìn rẹ ha kọ́ ni ìpìlẹ̀ fún ìgbọ́kànlé rẹ?Ìrètí rẹ ha kọ́ ni ìwà títọ́+ àwọn ọ̀nà rẹ?   Jọ̀wọ́, rántí: Ta ni aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tí ó ṣègbé rí?Ibo sì ni a ti pa adúróṣánṣán+ rẹ́ rí?  Gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo rí, àwọn tí ń hùmọ̀ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́Àti àwọn tí ń fúnrúgbìn ìjàngbọ̀n, àwọn fúnra wọn ni yóò ká a.+   Nípasẹ̀ èémí Ọlọ́run, wọn a ṣègbé,Àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ìbínú rẹ̀, wọn a wá sí òpin. 10  Ìkéramúramù kìnnìún ń bẹ, àti ohùn ẹgbọrọ kìnnìún,Ṣùgbọ́n eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ká. 11  Kìnnìún ń ṣègbé lọ nítorí àìsí ẹran ọdẹ,Àwọn ọmọ kìnnìún ni a sì yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara wọn. 12  Wàyí o, a yọ́ mú ọ̀rọ̀ kan tọ̀ mí wá,Etí mi sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ọ wúyẹ́wúyẹ́,+ 13  Nínú àwọn ìrònú agbénilọ́kànsókè ti ìran òru,Nígbà tí oorun àsùnwọra kun ènìyàn. 14  Ìbẹ̀rùbojo dé bá mi, àti ìwárìrì,Ó sì fi ìbẹ̀rùbojo kún ògìdìgbó egungun mi. 15  Ẹ̀mí kan sì ń kọjá lójú mi;Irun ara mi bẹ̀rẹ̀ sí dìde gàn-ùn gàn-ùn. 16  Ó dúró jẹ́ẹ́,Ṣùgbọ́n èmi kò dá ìrísí rẹ̀ mọ̀;Nǹkan kan wà ní iwájú mi;Ìparọ́rọ́ ń bẹ, mo sì wá gbọ́ ohùn kan pé: 17  ‘Ẹni kíkú—ó ha lè máa ṣe ìdájọ́ òdodo ju Ọlọ́run fúnra rẹ̀?Tàbí kẹ̀, abarapá ọkùnrin ha lè mọ́ ju Olùṣẹ̀dá rẹ̀?’ 18  Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,Ó sì ń fi ẹ̀sùn àléébù kan àwọn ońṣẹ́ rẹ̀. 19  Mélòómélòó ni yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní ti àwọn tí ń gbé ilé amọ̀,Àwọn tí ìpìlẹ̀ wọn wà nínú ekuru!+A ń tètè tẹ̀ wọ́n rẹ́ ju òólá. 20  A ń fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ láti òwúrọ̀ di alẹ́;Wọ́n ń ṣègbé títí láé láìsí ẹnikẹ́ni tí ó fi í sí ọkàn-àyà. 21  A kò ha ti fa okùn àgọ́ wọn tí ó wà láàárín wọn tu bí?Wọ́n kú nítorí àìní ọgbọ́n.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé