Jóòbù 26:1-14
26 Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Wo bí o ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá tó fún ẹni tí kò lágbára!Wo bí o ti gba apá tí kò lókun là!+
3 O mà kúkú ti fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n ní àmọ̀ràn o,+Ìwọ sì ti sọ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ pàápàá di mímọ̀ fún ògìdìgbó!
4 Ta ni ìwọ bá sọ̀rọ̀,Èémí ta sì ni ó ti ọ̀dọ̀ rẹ jáde wá?
5 Àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú ń wárìrìLábẹ́ omi àti àwọn tí ń gbé inú wọn.+
6 Ṣìọ́ọ̀lù wà ní ìhòòhò ní iwájú rẹ̀,+Ibi ìparun kò sì ní ìbòjú.
7 Ó na àríwá sórí ibi ṣíṣófo,+Ó so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo;
8 Ó pọ́n omi sínú àwọsánmà rẹ̀,+Tí ó fi jẹ́ pé ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà kò pínyà lábẹ́ wọn;
9 Ó bo ojú ìtẹ́ yí ká,Ní títẹ́ àwọsánmà rẹ̀ sí i lórí.+
10 Ó pa òbìrìkìtì sí ojú omi,+Títí dé ibi tí ìmọ́lẹ̀ dópin sí nínú òkùnkùn.
11 Àní àwọn ọwọ̀n ọ̀run mì,Kàyéfì sì ṣe wọ́n nítorí ìbáwí mímúná rẹ̀.
12 Ó ti ru òkun sókè nípa agbára rẹ̀,+Ó sì ti fọ́ afipárọ́luni+ sí wẹ́wẹ́+ nípa òye rẹ̀.
13 Àní ó ti mú ọ̀run dán nípa ẹ̀fúùfù rẹ̀,+Ọwọ́ rẹ̀ ti gún ejò tí ń yọ́ bẹ̀rẹ́ ní àgúnyọ.+
14 Wò ó! Ìwọ̀nyí jẹ́ bèbè àwọn ọ̀nà rẹ̀,+Àhegbọ́ mà ni ohun tí a sì gbọ́ nípa rẹ̀!Ṣùgbọ́n nípa ààrá agbára ńlá rẹ̀, ta ní lè lóye rẹ̀?”+