Aísáyà 57:1-21

57  Olódodo pàápàá ti ṣègbé,+ ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi èyí sí ọkàn-àyà.+ Àwọn ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni a ń kó jọ sọ́dọ̀ àwọn òkú,+ nígbà tí kò sí ẹni tí ó fi òye mọ̀ pé nítorí ìyọnu àjálù ni a fi kó olódodo lọ.+  Ó wọnú àlàáfíà;+ wọ́n ń sinmi+ lórí ibùsùn wọn,+ olúkúlùkù tí ń rìn lọ́nà títọ́.+  “Ní tiyín, ẹ sún mọ́ ìhín,+ ẹ̀yin ọmọ obìnrin oníṣẹ́ àfọ̀ṣẹ,+ ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti ti obìnrin tí ń ṣe kárùwà:+  Ta ni ẹ̀yin ń gbádùn àkókò onímùkẹ́ẹ̀kẹ̀ lé lórí?+ Ta ni ẹ̀yin ń la ẹnu gbàù sí, tí ẹ ń yọ ahọ́n síta sí?+ Ọmọ ìrélànàkọjá ha kọ́ ni yín, àní irú-ọmọ èké,+  ẹ̀yin tí ń ru ìfẹ́ onígbòónára sókè láàárín àwọn igi ńlá,+ lábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+ ẹ̀yin tí ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta gàǹgà?+  “Ìpín rẹ wà pẹ̀lú àwọn òkútà jíjọ̀lọ̀ tí ó wà ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá.+ Àwọn—àwọn ni ìpín rẹ.+ Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ni ìwọ da ọrẹ ẹbọ ohun mímu sí,+ tí o fi ẹ̀bùn rúbọ sí. Èmi yóò ha tu ara mi nínú nítorí nǹkan wọ̀nyí?+  Orí òkè ńlá gíga tí ó sì gbé sókè ni o gbé ibùsùn rẹ kalẹ̀ sí.+ Ibẹ̀ pẹ̀lú ni o gòkè lọ láti rú ẹbọ.+  Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn àti òpó ilẹ̀kùn ni o gbé ìrántí rẹ kalẹ̀ sí.+ Nítorí pé o tú ara rẹ sí ìhòòhò fún àwọn ẹlòmíràn dípò mi, o sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ; o sọ ibùsùn rẹ di aláyè gbígbòòrò.+ O sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn dá májẹ̀mú fún ara rẹ. Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ibùsùn pẹ̀lú wọn.+ Ẹ̀yà ara akọ ni ìwọ rí.  Ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Mélékì ti ìwọ ti òróró, o sì ń mú kí àwọn òróró ìkunra rẹ pọ̀ yanturu.+ O sì ń bá a lọ ní rírán àwọn aṣojú rẹ sí ibi jíjìnnàréré, tí ìwọ fi rẹ àwọn ọ̀ràn wálẹ̀ sí Ṣìọ́ọ̀lù.+ 10  O ti ṣe làálàá nínú ògìdìgbó àwọn ọ̀nà rẹ.+ Ìwọ kò wí pé, ‘Ìrètí kò sí!’ Ìwọ ti rí ìmúsọjí láti inú agbára rẹ.+ Ìdí nìyẹn tí ìwọ kò tíì fi ṣàìsàn.+ 11  “Ta ni jìnnìjìnnì bá ọ nítorí rẹ̀, tí o sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù,+ tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí purọ́?+ Ṣùgbọ́n èmi kọ́ ni ẹni tí ìwọ rántí.+ Ìwọ kò fi nǹkan kan sí ọkàn-àyà.+ Èmi kò ha dákẹ́, tí mo sì fi àwọn ọ̀ràn pa mọ́?+ Nítorí náà ni ìwọ kò ṣe bẹ̀rù èmi pàápàá.+ 12  Èmi fúnra mi yóò sọ nípa òdodo+ rẹ àti iṣẹ́+ rẹ, tí wọn kì yóò fi ṣe ọ́ láǹfààní.+ 13  Nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àwọn nǹkan tí o kó jọ kì yóò dá ọ nídè,+ ṣùgbọ́n ẹ̀fúùfù yóò gbé gbogbo wọn pàápàá lọ.+ Èémí àmíjáde yóò gbé wọn lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sá di mí+ ni yóò jogún ilẹ̀ náà, tí yóò sì gba òkè ńlá mímọ́ mi.+ 14  Dájúdájú, ẹnì kan yóò sì wí pé, ‘Ẹ kọ bèbè, ẹ kọ bèbè! Ẹ tún ọ̀nà ṣe.+ Ẹ mú ohun ìdìgbòlù èyíkéyìí kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.’”+ 15  Nítorí pé èyí ni ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Gíga Fíofío,+ tí ń gbé títí láé+ àti ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ mímọ́,+ wí: “Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni ibi tí mo ń gbé,+ àti pẹ̀lú ẹni tí a tẹ̀ rẹ́, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,+ láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.+ 16  Nítorí pé kì í ṣe fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò máa báni fà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe títí lọ fáàbàdà ni èmi yóò kún fún ìkannú;+ nítorí pé ẹ̀mí pàápàá yóò di ahẹrẹpẹ+ nítorí mi, àní àwọn ẹ̀dá eléèémí tí èmi fúnra mi ṣẹ̀dá.+ 17  “Nítorí ìṣìnà èrè rẹ̀ aláìbá ìdájọ́ òdodo mu+ ni ìkannú mi ṣe ru, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù ú, mo fi ojú mi pa mọ́,+ nígbà tí ìkannú mi ru. Ṣùgbọ́n ó ń rìn ṣáá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dalẹ̀+ ní ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ̀. 18  Mo ti rí àwọn ọ̀nà rẹ̀ gan-an; mo sì bẹ̀rẹ̀ sí mú un lára dá,+ mo sì darí rẹ̀,+ mo sì fi ìtùnú+ san àsanfidípò fún un àti fún àwọn tirẹ̀ tí ń ṣọ̀fọ̀.”+ 19  “Èmi yóò dá èso ètè.+ Àlàáfíà tí ń bá a lọ ni yóò wà fún ẹni tí ó jìnnà réré àti fún ẹni tí ó wà nítòsí,”+ ni Jèhófà wí, “èmi yóò sì mú un lára dá dájúdájú.”+ 20  “Ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tí a ń bì síwá bì sẹ́yìn, nígbà tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀, èyí tí omi rẹ̀ ń sọ èpò òkun àti ẹrẹ̀ sókè. 21  Àlàáfíà kò sí fún àwọn ẹni burúkú,”+ ni Ọlọ́run mi wí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé