Aísáyà 46:1-13
46 Bélì+ ti tẹ̀ ba,+ Nébò tẹ̀ ba síwájú; àwọn òrìṣà+ wọn ti wá wà fún àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti fún àwọn ẹran agbéléjẹ̀, ẹrù wọn, ẹrù àjò wọn lẹ́yọ-lẹ́yọ, jẹ́ ẹrù ìnira fún àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀.
2 Wọn yóò tẹ̀ ba síwájú; olúkúlùkù wọn yóò tẹ̀ ba bákan náà; wọn kò tilẹ̀ lè pèsè àsálà+ fún ẹrù ìnira, ṣùgbọ́n oko òǹdè ni ọkàn wọn yóò lọ.+
3 “Fetí sí mi, ìwọ ilé Jékọ́bù, àti gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́ kù lára ilé Ísírẹ́lì,+ ẹ̀yin tí mo gbé láti inú ikùn, ẹ̀yin tí mo gbé láti inú ilé ọlẹ̀.+
4 Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí;+ àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú.+ Dájúdájú, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀,+ kí èmi fúnra mi lè gbé, kí èmi fúnra mi sì lè rù, kí n sì pèsè àsálà.+
5 “Ta ni ẹ ó fi mí wé,+ tàbí tí ẹ óò mú mi bá dọ́gba tàbí tí ẹ ó fi mí ṣe àkàwé kí a lè jọra?+
6 Àwọn kan wà tí ń da wúrà jáde yàlàyàlà láti inú àpò, wọ́n sì fi ọ̀pá àfiwọn-nǹkan wọn fàdákà. Wọ́n háyà oníṣẹ́ irin, ó sì fi í ṣe ọlọ́run kan.+ Wọ́n ń wólẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń tẹrí ba.+
7 Wọ́n gbé e sí èjìká,+ wọ́n rù ú, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ kí ó lè dúró bọrọgidi. Kò ṣísẹ̀ kúrò ní ibi tí ó dúró sí.+ Ẹnì kan tilẹ̀ ń ké jáde sí i, ṣùgbọ́n kò dáhùn; kò gbani là kúrò nínú wàhálà ẹni.+
8 “Ẹ rántí èyí, kí ẹ lè máyàle. Ẹ fi í sínú ọkàn-àyà,+ ẹ̀yin olùrélànàkọjá.+
9 Ẹ rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ pé èmi ni Olú Ọ̀run,+ kò sì sí Ọlọ́run mìíràn,+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi;+
10 Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin,+ tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe;+ Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró,+ gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe’;+
11 Ẹni tí ń pe ẹyẹ aṣọdẹ+ láti yíyọ oòrùn wá, tí ń pe ọkùnrin tí yóò mú ìpinnu mi ṣẹ+ ní kíkún láti ilẹ̀ jíjìnnà wá. Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú.+ Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.+
12 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ alágbára ní ọkàn-àyà,+ ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré sí òdodo.+
13 Mo ti mú òdodo mi sún mọ́ tòsí.+ Kò jìnnà réré,+ ìgbàlà mi kì yóò sì pẹ́.+ Dájúdájú, èmi yóò pèsè ìgbàlà ní Síónì, èmi yóò fún Ísírẹ́lì ní ẹwà mi.”+