Aísáyà 25:1-12
25 Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi.+ Mo gbé ọ ga,+ mo gbé orúkọ rẹ lárugẹ,+ nítorí pé o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu,+ àwọn ìpinnu+ láti àwọn àkókò ìjímìjí, nínú ìṣòtítọ́,+ nínú ìṣeégbẹ́kẹ̀lé.+
2 Nítorí pé ìwọ ti sọ ìlú ńlá kan di ìtòjọpelemọ òkúta, o ti sọ ìlú olódi di ìrúnwómúwómú, o ti sọ ilé gogoro ibùgbé àwọn àjèjì di èyí tí kì í ṣe ìlú ńlá mọ́, tí a kì yóò tún kọ́, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
3 Ìdí nìyẹn tí àwọn alágbára ènìyàn yóò fi yìn ọ́ lógo; ìlú àwọn orílẹ̀-èdè afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, wọn yóò bẹ̀rù rẹ.+
4 Nítorí pé ìwọ ti di ibi odi agbára fún ẹni rírẹlẹ̀, ibi odi agbára fún òtòṣì nínú wàhálà tí ó dé bá a,+ ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, ibòji+ kúrò lọ́wọ́ ooru, nígbà tí ẹ̀fúùfù òjijì àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ dà bí ìjì òjò lára ògiri.
5 Bí ooru ní ilẹ̀ aláìlómi, ariwo àwọn àjèjì ni ìwọ mú rọlẹ̀, ooru pẹ̀lú òjìji àwọsánmà.+ Àní orin atunilára àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ di ohun tí a tẹ̀ rì.+
6 Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ́ tí a fi òróró dùn+ fún gbogbo àwọn ènìyàn+ ní òkè ńlá yìí,+ àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ́ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn,+ ti wáìnì+ sísẹ́,+ èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.
7 Àti pé ní òkè ńlá yìí, dájúdájú, òun yóò gbé ojú ìràgàbò náà mì, èyí tí ó ràgà bo gbogbo ènìyàn,+ àti ohun híhun tí a hun pọ̀ sórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
8 Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé,+ dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.+ Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yòò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé,+ nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.
9 Dájúdájú, ẹnì kan yóò sì sọ ní ọjọ́ yẹn pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí.+ Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀,+ òun yóò sì gbà wá là.+ Jèhófà nìyí.+ Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú kí a sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”+
10 Nítorí pé ọwọ́ Jèhófà yóò sọ̀ sórí òkè ńlá yìí,+ Móábù ni a ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀+ ní àyè rẹ̀ bí ìgbà tí a bá tẹ òkìtì ègé koríko mọ́lẹ̀ ní ibi ajílẹ̀.+
11 Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde ní àárín rẹ̀ bí ìgbà tí òmùwẹ̀ bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́, òun yóò sì fi gbígbé tí òun ń gbé ọwọ́ lọ́nà àgálámàṣà rẹ ìrera rẹ̀ wálẹ̀.+
12 Ìlú ńlá olódi, pẹ̀lú àwọn ògiri gíga tí o fi ṣe ààbò, ni òun yóò wó palẹ̀; yóò rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀, yóò bá a kanlẹ̀, àní kan ekuru.+