Aísáyà 22:1-25

22  Ọ̀rọ̀ ìkéde nípa àfonífojì ìran:+ Kí wá ni ó ṣe ọ́, tí o fi gòkè lọ pátápátá sórí àwọn òrùlé?+  Ìwọ kún fún yánpọnyánrin, ìlú ńlá aláriwo líle, ìlú tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà.+ Àwọn ènìyàn rẹ tí a pa kì í ṣe àwọn tí a fi idà pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe àwọn tí ó kú nínú ìjà ogun.+  Gbogbo àwọn apàṣẹwàá+ rẹ pàápàá ti sá lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.+ Láìnílò ọrun, a ti mú wọn ní ẹlẹ́wọ̀n. Gbogbo àwọn tí a rí nínú rẹ ni a mú ní ẹlẹ́wọ̀n pa pọ̀.+ Wọ́n ti fẹsẹ̀ fẹ lọ sí ibi jíjìnnàréré.  Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé: “Yí ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi. Dájúdájú, èmi yóò fi ìkorò hàn nínú ẹkún sísun.+ Ẹ má tẹpẹlẹ mọ́ títù mí nínú nítorí fífi tí a fi ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi ṣe ìjẹ.+  Nítorí pé ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀+ àti ìfẹsẹ̀tẹ̀mọ́lẹ̀+ àti mímú ẹnu wọhò+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ti ṣètò ní àfonífojì ìran. Olùwó ògiri palẹ̀+ ń bẹ, àti igbe sí òkè ńlá.+  Élámù+ alára sì ti gbé apó, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun ti ará ayé, tí ó ní àwọn ẹṣin ogun; Kírì+ alára sì ti ṣí apata sílẹ̀.  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ààyò jù lọ nínú àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ rẹ yóò kún fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun, àwọn ẹṣin ogun gan-an yóò sì to ara wọn sí ẹnubodè láìkùnà,  ẹnì kan yóò sì mú àtabojú Júdà kúrò. Ìwọ yóò sì wo ìhà ìhámọ́ra+ ilé igbó+ ní ọjọ́ yẹn,  dájúdájú, ẹ ó sì rí, àní àwọn àlàfo Ìlú Ńlá Dáfídì, nítorí pé wọn yóò pọ̀+ ní tòótọ́. Ẹ ó sì gbá omi odò adágún ìsàlẹ̀+ jọ. 10  Ẹ ó sì ka ilé Jerúsálẹ́mù ní tòótọ́. Ẹ ó sì bi àwọn ilé wó pẹ̀lú láti lè sọ ògiri+ di ibi tí kò ṣeé dé. 11  Bàsíà agbomidúró yóò sì wà tí ẹ ó ṣe sáàárín ògiri méjì fún omi odò adágún àtijọ́.+ Dájúdájú, ẹ kì yóò sì wo Olùṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá, ṣe ni ẹ kì yóò rí ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. 12  “Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò sì pè ní ọjọ́ yẹn fún ẹkún+ àti fún ọ̀fọ̀ àti fún orí pípá àti fún sísán aṣọ àpò ìdọ̀họ.+ 13  Ṣùgbọ́n, wò ó! ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀, pípa màlúù àti pípa àgùntàn, jíjẹ ẹran àti mímu wáìnì,+ ‘Kí jíjẹ àti mímu ṣẹlẹ̀, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.’”+ 14  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ṣí ara rẹ̀ payá ní etí+ mi pé: “‘A kì yóò ṣètùtù ìṣìnà yìí+ fún yín títí ẹ ó fi kú,’+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” 15  Èyí ni ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹ̀gbẹ́ ọmọ ogun, wí: “Lọ, wọlé tọ ìríjú yìí lọ, èyíinì ni Ṣébínà,+ ẹni tí ń ṣe àbójútó ilé,+ 16  ‘Kí ni ó jẹ́ tìrẹ níhìn-ín, ta sì ni ó jẹ́ tìrẹ níhìn-ín, tí o fi gbẹ́ ibi ìsìnkú síhìn-ín fún ara rẹ?’+ Ibi gíga ni ó ń gbẹ́ ibi ìsìnkú rẹ̀ sí; inú àpáta gàǹgà ni ó ń gbẹ́ ibùgbé sí fún ara rẹ̀. 17  ‘Wò ó! Ìfisọ̀kò lílenípá ni Jèhófà yóò fi fi ọ́ sọ̀kò sísàlẹ̀, ìwọ abarapá ọkùnrin, òun yóò sì fi ipá gbá ọ mú. 18  Láìkùnà, òun yóò dì ọ́ le dan-in dan-in, bí bọ́ọ̀lù fún ilẹ̀ gbígbòòrò. Ibẹ̀ ni ìwọ yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ògo rẹ yóò ti jẹ́ àbùkù ilé ọ̀gá rẹ. 19  Ṣe ni èmi yóò tì ọ́ kúrò ní ipò rẹ; ẹnì kan yóò sì ya ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ìdúró ipò àṣẹ rẹ.+ 20  “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, ṣe ni èmi yóò pe ìránṣẹ́ mi,+ èyíinì ni, Élíákímù+ ọmọkùnrin Hilikáyà.+ 21  Èmi yóò sì fi aṣọ oyè rẹ wọ̀ ọ́, èmi yóò sì fi ìgbàjá rẹ gbà á gírígírí,+ èmi yóò sì fi àgbègbè ìṣàkóso rẹ lé e lọ́wọ́; yóò sì di baba àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti ilé Júdà.+ 22  Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́+ ilé Dáfídì lé èjìká rẹ̀, yóò sì ṣí láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò tì, yóò sì tì láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò ṣí.+ 23  Èmi yóò sì gbá a wọlé gẹ́gẹ́ bí èèkàn+ sí ibi wíwà pẹ́ títí, yóò sì dà bí ìtẹ́ ògo fún ilé baba rẹ̀.+ 24  Wọn yóò sì gbé gbogbo ògo ilé baba rẹ̀ kọ́ sára rẹ̀, àwọn ọmọ ìran àti èéhù, gbogbo ohun èlò irú èyí tí ó kéré, àwọn ohun èlò irú èyí tí ó jẹ́ àwokòtò àti gbogbo ohun èlò tí ó jẹ́ àwọn ìṣà títóbi. 25  “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘èèkàn+ tí a gbá wọ ibi wíwà pẹ́ títí ni a óò mú kúrò,+ a ó sì gbẹ́ ẹ kanlẹ̀, yóò sì ṣubú, ẹrù tí ó wà lára rẹ̀ sì ni a óò ké kúrò, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé