Aísáyà 20:1-6
20 Ní ọdún tí Tátánì+ wá sí Áṣídódì,+ nígbà tí Ságónì ọba Ásíríà rán an,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Áṣídódì jagun, ó sì gbà á;+
2 ní àkókò yẹn, Jèhófà tipa ọwọ́ Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì+ sọ̀rọ̀, pé: “Lọ,+ kí o sì tú aṣọ àpò ìdọ̀họ kúrò ní ìgbáròkó rẹ;+ kí o sì bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.”+ Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń rìn káàkiri ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà.+
3 Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Aísáyà ti rìn káàkiri ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà fún ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí àmì+ àti àmì àgbàyanu lòdì sí Íjíbítì+ àti lòdì sí Etiópíà,+
4 bẹ́ẹ̀ ni ọba Ásíríà yóò ṣe kó ẹgbẹ́ àwọn òǹdè Íjíbítì+ àti àwọn ìgbèkùn Etiópíà lọ, ọmọdékùnrin àti àgbàlagbà, ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà, ti àwọn ti ekiti ìdí tí a kò fi aṣọ bò, ìhòòhò Íjíbítì.+
5 Dájúdájú, wọn yóò sì jáyà, ojú yóò sì tì wọ́n fún Etiópíà, ìretí tí wọ́n ń wọ̀nà fún,+ àti fún Íjíbítì ẹwà wọn.+
6 Ó sì dájú pé àwọn olùgbé ilẹ̀ etí òkun yìí yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Bí ìretí tí a ń wọ̀nà fún ti rí nìyẹn, èyí tí a sá lọ bá fún ìrànwọ́, kí a lè dá wa nídè nítorí ọba Ásíríà!+ Báwo sì ni àwa alára yóò ṣe yè bọ́?’”