Aísáyà 18:1-7

18  Háà, nítorí ilẹ̀ àwọn kòkòrò akùnrànyìn tí ó ní ìyẹ́ apá, èyí tí ń bẹ ní ẹkùn ilẹ̀ àwọn odò Etiópíà!+  Òun ni ó ń rán àwọn aṣojú+ jáde nípasẹ̀ òkun, àti nípasẹ̀ àwọn ọkọ̀ tí a fi òrépèté ṣe tí ń bẹ lójú omi, pé: “Ẹ lọ, ẹ̀yin ońṣẹ́ yíyára, sí orílẹ̀-èdè gíga àti alára dídán, sí àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ olókun líle tantan àti olùfẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀, tí àwọn odò ti gbá ilẹ̀ rẹ̀ lọ.”+  Gbogbo ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ eléso+ àti ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ ayé, ẹ óò rí ìran gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbé àmì àfiyèsí sókè lórí àwọn òkè ńlá,+ ẹ ó sì gbọ́ ìró gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a fun ìwo.+  Nítorí pé èyí ni Jèhófà sọ fún mi: “Dájúdájú, èmi yóò wà láìní ìyọlẹ́nu, èmi yóò sì máa wo ibi àfìdímúlẹ̀ mi,+ gẹ́gẹ́ bí ooru wíwọnilójú nígbà ìmọ́lẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà ìrì nínú ooru ìkórè.+  Nítorí pé ṣáájú ìkórè, nígbà tí ìtànná yóò wá sí ìjẹ́pípé, tí ìtànná òdòdó yóò sì di èso àjàrà pípọ́n, ẹnì kan yóò fi ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn ké àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ kéékèèké kúrò pẹ̀lú, yóò sì mú àwọn ọwọ́ rẹ̀ kúrò, yóò sì ké wọn dànù.+  A ó fi gbogbo wọn lápapọ̀ sílẹ̀ fún ẹyẹ aṣọdẹ tí ń bẹ ní àwọn òkè ńlá àti fún ẹranko ilẹ̀ ayé.+ Dájúdájú, orí wọn ni ẹyẹ aṣọdẹ yóò ti lo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, orí wọn sì ni gbogbo ẹranko ilẹ̀ ayé yóò ti lo àkókò ìkórè.+  “Ní àkókò yẹn, a óò mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga àti alára dídán,+ àní láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ olókun líle tantan àti olùfẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀, tí àwọn odò ti gbá ilẹ̀ rẹ̀ lọ, sí ibi orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Òkè Ńlá Síónì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé