Aísáyà 16:1-14

16  Ẹ fi àgbò ránṣẹ́ sí olùṣàkóso ilẹ̀ náà,+ láti Sẹ́ẹ́là síhà aginjù, sórí òkè ńlá ọmọbìnrin Síónì.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń sá lọ, tí a lé kúrò nínú ìtẹ́ rẹ̀,+ ni àwọn ọmọbìnrin Móábù yóò dà ní àwọn ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò Áánónì.+  “Ẹ mú ìmọ̀ràn wá, ẹ mú ìpinnu ṣẹ ní kíkún.+ “Ṣe òjìji rẹ gẹ́gẹ́ bí òru ní àárín ọ̀sán gangan.+ Fi àwọn tí a fọ́n ká pa mọ́;+ má fi ẹnikẹ́ni tí ń sá lọ léni lọ́wọ́.+  Kí àwọn ènìyàn mi tí a fọ́n ká máa ṣe àtìpó nínú rẹ, ìwọ Móábù.+ Di ibi ìlùmọ́ fún wọn nítorí afiniṣèjẹ.+ Nítorí pé aninilára ti dé òpin rẹ̀; ìfiniṣèjẹ ti kásẹ̀ nílẹ̀; àwọn tí ń tẹ ẹlòmíràn mọ́lẹ̀ ni a ti pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé.+  “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ni a ó fi fìdí ìtẹ́ kan múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in;+ ẹnì kan yóò sì jókòó sórí rẹ̀ nínú òótọ́ nínú àgọ́ Dáfídì,+ yóò máa ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́ òdodo, yóò sì máa ṣe kánmọ́kánmọ́ nínú òdodo.”+  A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù, pé ó gbéra ga gidigidi;+ ìrera rẹ̀ àti ìgbéraga rẹ̀ àti ìbínú kíkan rẹ̀+—ọ̀rọ̀ òfìfo rẹ̀ kì yóò rí bẹ́ẹ̀.+  Nítorí náà, Móábù yóò hu fún Móábù; àní gbogbo rẹ̀ yóò hu.+ Ní tòótọ́, àwọn tí a kọlù yóò kédàárò nítorí àwọn ìṣù èso àjàrà gbígbẹ ti Kiri-hárésétì,+  nítorí pé àwọn ilẹ̀ onípele títẹ́jú Hẹ́ṣíbónì+ pàápàá ti gbẹ. Àjàrà Síbúmà+—àwọn tí ó ni àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá ti ké àwọn ẹ̀ka rẹ̀ pupa fòò lulẹ̀. Wọ́n ti lọ títí dé Jásérì;+ wọ́n ti rìn káàkiri ní aginjù. A ti fi àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ sílẹ̀ láti fúnra wọn gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀; wọ́n ti kọjá lọ sórí òkun.  Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi ẹkún sísun Jásérì sunkún lórí àjàrà Síbúmà.+ Èmi yóò fi omijé mi rin ọ́ gbingbin, ìwọ Hẹ́ṣíbónì+ àti Éléálè,+ nítorí pé àní igbe ti sọ̀ kalẹ̀ sórí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti sórí ìkórè rẹ.+ 10  A sì ti mú ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú kúrò nínú ọgbà igi eléso; àti nínú àwọn ọgbà àjàrà, kò sí fífi ìdùnnú ké jáde, kò sí kíkígbe.+ Ẹni tí ń fẹsẹ̀ tẹ wáìnì ní àwọn ibi ìfúntí kò fẹsẹ̀ tẹ wáìnì kankan jáde.+ Èmi ti mú kí igbe kásẹ̀ nílẹ̀.+ 11  Ìdí nìyẹn tí ìhà inú mi gan-an fi ń pariwo líle gẹ́gẹ́ bí háàpù àní lórí Móábù,+ àti àárín inú mi lórí Kiri-hárésétì.+ 12  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, a rí i pé Móábù ni a tán lókun lórí ibi gíga;+ ó sì wá sí ibùjọsìn rẹ̀ láti gbàdúrà,+ kò sì lè ṣe ohunkóhun ní àṣeparí.+ 13  Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Móábù tẹ́lẹ̀ rí. 14  Wàyí o, Jèhófà ti sọ̀rọ̀, pé: “Láàárín ọdún mẹ́ta, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọdún lébìrà tí a háyà,+ ògo+ Móábù ni a ó fi gbogbo onírúurú arukutu púpọ̀ dójú tì pẹ̀lú, àwọn tí yóò ṣẹ́ kù yóò sì jẹ́ díẹ̀ tí kò tó nǹkan, kì í ṣe alágbára ńlá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé