Aísáyà 11:1-16
11 Ẹ̀ka igi+ kan yóò sì yọ láti ara kùkùté Jésè;+ àti láti ara gbòǹgbò rẹ̀, èéhù+ kan yóò máa so èso.+
2 Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e,+ ẹ̀mí ọgbọ́n+ àti ti òye,+ ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá,+ ẹ̀mí ìmọ̀+ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà;+
3 ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.+
Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́.+
4 Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀,+ yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé. Yóò sì fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀+ lu ilẹ̀ ayé; yóò sì fi ẹ̀mí ètè rẹ̀ fi ikú pa ẹni burúkú.+
5 Òdodo yóò sì jẹ́ ìgbànú ìgbáròkó rẹ̀,+ ìṣòtítọ́ ni yóò sì jẹ́ ìgbànú abẹ́nú rẹ̀.+
6 Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn,+ àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀+ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa,+ gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n.
7 Abo màlúù àti béárì pàápàá yóò máa jẹun; àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pa pọ̀. Kìnnìún pàápàá yóò jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.+
8 Dájúdájú, ọmọ ẹnu ọmú yóò máa ṣeré lórí ihò ṣèbé;+ ihò tí ó ní ìmọ́lẹ̀, tí í ṣe ti ejò olóró ni ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ní ti gidi.
9 Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi;+ nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.+
10 Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn+ pé gbòǹgbò Jésè+ yóò wà tí yóò dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn.+ Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá yóò yíjú sí láti ṣe ìwádìí,+ ibi ìsinmi rẹ̀ yóò sì di ológo.+
11 Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò tún na ọwọ́ rẹ̀, ní ìgbà kejì,+ láti gba àṣẹ́kù àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò ṣẹ́ kù láti Ásíríà+ àti láti Íjíbítì+ àti láti Pátírọ́sì+ àti láti Kúṣì+ àti láti Élámù+ àti láti Ṣínárì+ àti láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù òkun.+
12 Dájúdájú, òun yóò gbé àmì àfiyèsí kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì kó àwọn tí a fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ;+ àwọn tí a tú ká lára Júdà ni òun yóò sì kó jọpọ̀ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.+
13 Owú Éfúráímù yóò sì kúrò,+ àní àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí Júdà ni a óò ké kúrò. Éfúráímù pàápàá kì yóò jowú Júdà, bẹ́ẹ̀ ni Júdà kì yóò fi ẹ̀tanú hàn sí Éfúráímù.+
14 Wọn yóò sì fò lórí èjìká àwọn Filísínì lọ sí ìwọ̀-oòrùn;+ wọn yóò jùmọ̀ piyẹ́ àwọn ọmọ Ìlà-Oòrùn.+ Édómù àti Móábù ni àwọn tí wọn yóò na ọwọ́ wọn lé lórí,+ àwọn ọmọ Ámónì yóò sì jẹ́ ọmọ-abẹ́ wọn.+
15 Jèhófà yóò sì ké ahọ́n òkun+ Íjíbítì kúrò dájúdájú, yóò sì mi ọwọ́ rẹ̀ sí Odò+ nínú ìrànyòò ẹ̀mí rẹ̀. Yóò sì kọlù ú ní ojú ọ̀gbàrá rẹ̀ méjèèje, yóò sì mú kí àwọn ènìyàn fi sálúbàtà wọn rìn ní ti tòótọ́.+
16 Òpópó+ kan yóò sì wá wà láti inú Ásíríà fún àṣẹ́kù+ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò ṣẹ́ kù,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ti wá wà fún Ísírẹ́lì ní ọjọ́ tí ó ń gòkè bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì.