Aísáyà 10:1-34
10 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi àwọn ìlànà tí ń pani lára+ lélẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ pé, ní kíkọ̀wé ṣáá, wọ́n ti kọ̀wé ìjàngbọ̀n gbáà,
2 kí wọ́n lè ti ẹni rírẹlẹ̀ dànù nínú ẹjọ́, kí wọ́n sì lọ́ ìdájọ́ òdodo gbà lọ́wọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn mi,+ kí àwọn opó lè di ohun ìfiṣèjẹ wọn, kí wọ́n sì lè piyẹ́ àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba pàápàá!+
3 Kí sì ni ẹ ó ṣe ní ọjọ́ tí a óò fún yín ní àfiyèsí+ àti nígbà ìparun, nígbà tí ó bá dé láti ibi jíjìnnàréré?+ Ọ̀dọ̀ ta ni ẹ óò sá lọ fún ìrànwọ́,+ ibo sì ni ẹ ó fi ògo yín sílẹ̀ sí,+
4 bí kò ṣe pé ènìyàn yóò tẹrí ba lábẹ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti pé àwọn ènìyàn yóò máa ṣubú lábẹ́ àwọn tí a ti pa?+ Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.+
5 “Àháà, ará Ásíríà,+ ọ̀pá tí ó wà fún ìbínú mi,+ àti póńpó tí ó wà ní ọwọ́ wọn fún ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá!
6 Èmi yóò rán an sí orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà,+ èmi yóò sì pàṣẹ fún un+ lòdì sí àwọn ènìyàn ìbínú kíkan mi, pé kí ó kó ohun ìfiṣèjẹ púpọ̀, kí ó sì piyẹ́ ohun púpọ̀, kí ó sì sọ ọ́ di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ àwọn ojú pópó.+
7 Bí òun kò bá tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, òun yóò ní ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀; bí ọkàn-àyà rẹ̀ kò bá tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òun yóò pète-pèrò bẹ́ẹ̀, nítorí pé láti pa rẹ́ ráúráú ni ó wà ní ọkàn-àyà rẹ̀,+ àti láti ké àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe díẹ̀ kúrò.+
8 Nítorí òun yóò wí pé, ‘Àwọn ọmọ aládé mi kì í ha ṣe ọba bákan náà?+
9 Kálínò+ kò ha rí bí Kákémíṣì?+ Hámátì+ kò ha rí bí Áápádì?+ Samáríà+ kò ha rí bí Damásíkù?+
10 Ìgbàkigbà tí ọwọ́ mi bá tẹ àwọn ìjọba tí ó jẹ́ ti ọlọ́run tí kò ní láárí, tí àwọn ère fífín wọn pọ̀ ju àwọn èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Samáríà,+
11 kì yóò ha jẹ́ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí Samáríà àti sí àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí,+ àní bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí Jerúsálẹ́mù àti sí àwọn òrìṣà rẹ̀?’+
12 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jèhófà bá mú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀ ní Òkè Ńlá Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, èmi yóò béèrè ìjíhìn nítorí èso àfojúdi ti ọkàn-àyà ọba Ásíríà àti nítorí ìkara-ẹni-sí-pàtàkì ti ìgafíofío ojú rẹ̀.+
13 Nítorí ó sọ pé, ‘Agbára ọwọ́ mi ni èmi yóò fi gbé ìgbésẹ̀ dájúdájú,+ àti pẹ̀lú ọgbọ́n mi, nítorí mo ní òye; èmi yóò sì mú àwọn ààlà àwọn ènìyàn kúrò,+ àwọn nǹkan tí wọ́n sì tò jọ pa mọ́ ni èmi yóò kó ní ìkógun dájúdájú,+ èmi yóò sì rẹ àwọn olùgbé ibẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alágbára.+
14 Gẹ́gẹ́ bí ìtẹ́ ẹyẹ, ọwọ́ mi+ yóò sì tẹ ohun àmúṣọrọ̀+ àwọn ènìyàn; gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn kó àwọn ẹyin tí a fi sílẹ̀ jọ, èmi fúnra mi yóò kó gbogbo ilẹ̀ ayé pàápàá jọ, dájúdájú, kì yóò sí èyí tí yóò máa gbọn ìyẹ́ apá rẹ̀ bàlàbàlà tàbí tí yóò máa la ẹnu rẹ̀ tàbí tí yóò máa ké ṣíoṣío.’”
15 Àáké yóò ha gbé ara rẹ̀ lékè ẹni tí ń fi í gé nǹkan, tàbí kẹ̀, ayùn yóò ha gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tí ń mú kí ó lọ síwá-sẹ́yìn, bí ẹni pé ọ̀gọ ni ó mú kí àwọn tí ó gbé e sókè lọ síwá-sẹ́yìn, bí ẹni pé ọ̀pá ni ó gbé ẹni tí kì í ṣe igi sókè?+
16 Nítorí náà, Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò máa rán òkùnrùn amúnijoro+ sára àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó sanra, àti pé lábẹ́ ògo rẹ̀, jíjó kan yóò máa jó nìṣó bí jíjó iná.+
17 Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì+ yóò sì di iná,+ Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò sì di ọwọ́ iná;+ yóò sì jó, yóò sì jẹ èpò àti àwọn igi kéékèèké rẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún+ run ní ọjọ́ kan.
18 Ògo igbó rẹ̀ àti ti ọgbà igi eléso rẹ̀ ni Òun yóò sì mú wá sí òpin,+ àní láti ọkàn títí lọ dé ẹran ara, yóò sì dà bí yíyọ́dànù ẹni tí ń ṣòjòjò.+
19 Àti ìyókù àwọn igi igbó rẹ̀—wọn yóò di èyí tí ọmọdékùnrin kan lásán yóò lè kọ iye wọn sílẹ̀.+
20 Dájúdájú, yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì+ àti àwọn tí ó ti sá àsálà lára ilé Jékọ́bù kì yóò tún gbé ara wọn lé ẹni tí ń lù wọ́n+ mọ́, dájúdájú, wọn yóò gbé ara wọn lé Jèhófà, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ nínú òótọ́.+
21 Àṣẹ́kù lásán ni yóò padà, àṣẹ́kù Jékọ́bù, sọ́dọ̀ Ọlọ́run Alágbára Ńlá.+
22 Nítorí pé, bí àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì, bá tilẹ̀ rí bí àwọn egunrín iyanrìn òkun,+ àṣẹ́kù lásán ni yóò padà lára wọn.+ Ìparun pátápátá+ tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí yóò ya kọjá nínú òdodo,+
23 nítorí pé ìparun pátápátá+ àti ìpinnu àìyẹhùn ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò mú ṣẹ ní kíkún ní àárín gbogbo ilẹ̀ náà.+
24 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, wí: “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ń gbé ní Síónì,+ ẹ má fòyà nítorí ará Ásíríà náà, tí ó ti máa ń fi ọ̀pá lù ọ́,+ tí ó sì ti máa ń gbé ọ̀gọ rẹ̀ sókè sí ọ bí Íjíbítì ti ṣe.+
25 Nítorí pé ní ìgbà díẹ̀ sí i—ìdálẹ́bi+ náà yóò ti wá sí òpin, àti ìbínú mi, yóò ti rọlẹ̀.+
26 Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ju pàṣán+ kan fìrìfìrì lára rẹ̀ bí ti ìgbà ìṣẹ́gun Mídíánì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpáta Órébù;+ ọ̀gọ rẹ̀ yóò sì wà lórí òkun,+ yóò sì gbé e sókè dájúdájú bí ó ti ṣe sí Íjíbítì.+
27 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé ẹrù rẹ̀ yóò kúrò ní èjìká rẹ,+ àjàgà rẹ̀ yóò sì kúrò ní ọrùn rẹ,+ a ó sì ba àjàgà náà jẹ́+ dájúdájú nítorí òróró.”
28 Òun ti dé bá Áyátì;+ ó ti gba Mígírónì kọjá; Míkímáṣì+ ni ó kó àwọn ohun èlò rẹ̀ lélẹ̀ sí.
29 Wọ́n ti ré ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò kọjá, Gébà+ ni ibi tí wọ́n wọ̀ sí ní òru, Rámà+ wárìrì, Gíbíà+ ti Sọ́ọ̀lù pàápàá ti sá lọ.
30 Gbé ohùn rẹ sókè nínú igbe híhan gan-an-ran, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù.+ Fetí sílẹ̀, ìwọ Láíṣà. Ìwọ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, Ánátótì!+
31 Mádíménà ti fẹsẹ̀ fẹ. Àwọn olùgbé Gébímù alára ti wá ibi ààbò.
32 Ọjọ́ kò tíì lọ ní Nóbù+ fún dídẹsẹ̀dúró. Ó mi ọwọ́ lọ́nà ìhalẹ̀mọ́ni sí òkè ńlá ọmọbìnrin Síónì, òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.+
33 Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ń fi ìwólulẹ̀ túútúú tí ń jáni láyà ké àwọn ẹ̀tun dànù;+ àwọn tí ó ga ní ìdúró ni ó sì ń ké lulẹ̀, àwọn èyí tí ó ga pàápàá a sì di rírẹ̀sílẹ̀.+
34 Ó sì ti fi irinṣẹ́ tí a fi irin ṣe ṣá ìgbòrò igbó balẹ̀, Lẹ́bánónì alára yóò sì ti ọwọ́ alágbára kan ṣubú.+