Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni​—Fídíò

Kọ́ àwọn nǹkan pàtàkì tó máa jẹ́ kó o lè kàwé, kó o sì lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó dára.

Ẹ̀KỌ́ 1

Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Kí lo lè ṣe tó máa jẹ́ kó wu àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ?

Ẹ̀KỌ́ 2

Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀wérọ̀

Báwo lo ṣe lè mú kí ara tu àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ?

Ẹ̀KỌ́ 3

Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ

Báwo lo ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà táá mú kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ronú jinlẹ̀, kí ọkàn wọn wà nínú ohun tí ò ń sọ, tí àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ á sì yọ?

Ẹ̀KỌ́ 4

Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ

Kí lo lè ṣe káwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lè jàǹfààní púpọ̀ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà?

Ẹ̀KỌ́ 5

Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́

Kí ló yẹ kó o ṣe kó o bàa lè ka ohun tó wà nínú ìwé sókè bó ṣe wà níbẹ̀ gẹ́lẹ́?

Ẹ̀KỌ́ 6

Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere

Kí lo lè ṣe tó o bá ń ka Ìwé Mímọ́ àti lẹ́yìn tó o bá kà á tán, láti lè mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lóye ìdí tó o fi kà á?

Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà

Báwo lo ṣe lè rí i dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀?

Ẹ̀KỌ́ 8

Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Báwo lo ṣe lè máa lo àpèjúwe lọ́nà tó dára bíi ti Olùkọ́ ńlá náà?

Ẹ̀KỌ́ 9

Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára

Báwo lo ṣe lè lo ohun tá a lè fojú rí lati mú kí kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ yéni tó o bá ń kọ́ni?

Ẹ̀KỌ́ 10

Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ

Báwo lo ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ rẹ yéni, kó sì wọni lọ́kàn tó o bá ń yí ohùn pa dà bó ṣe yẹ?

Ẹ̀KỌ́ 11

Ìtara

Báwo lo ṣe lè lo ìtara láti mú kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o sọ?

Ẹ̀KỌ́ 12

Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò

Tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, kí ló máa jẹ́ kó o lè sọ̀rọ̀ látọkàn wá, kó o sì fọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò?

Ẹ̀KỌ́ 13

Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò

Báwo lo ṣe lè sọ̀rọ̀ lórí kókó kan táwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ á rí bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe wúlò, tí wọ́n á sì ṣe ohun tó yẹ?

Ẹ̀KỌ́ 14

Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere

Tó o bá jẹ́ kí kókó ọ̀rọ̀ rẹ fara hàn kedere, àwọn èèyàn á máa fọkàn bá ẹ lọ, ọ̀rọ̀ rẹ á yé wọn, wọ́n á sì rántí ohun tó o sọ.

Ẹ̀KỌ́ 15

Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀

Báwo lo ṣe lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ tó o bá ń sọ àsọyé tàbí tó o bá ń wàásù?

Ẹ̀KỌ́ 16

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní

Ohun mẹ́ta wo lo máa jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fáwọn èèyàn níṣìírí, táá sì mú kí ìgbésí ayé wọn dára sí i?

Ẹ̀KỌ́ 17

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni

Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún tá a bá ń ran àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa lọ́wọ́ láti lóye ohun tá à ń sọ?

Ẹ̀KỌ́ 18

Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ

Báwo la ṣe lè mú káwọn tó ń gbọ́ wa ronú jinlẹ̀, kí wọ́n sì rí nǹkan gidi jèrè?

Ẹ̀KỌ́ 19

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Kí lo lè sọ tó máa jẹ́ káwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ ní èrò tó dáa?

Ẹ̀KỌ́ 20

Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Bóyá ò ń kọ́ni nínú ìjọ àbí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ìparí ọ̀rọ̀ ẹ dára?

O Tún Lè Wo

ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ

Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni

Ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti suwọ̀n sí i nínú kíkàwé àti kíkọ́ni.