Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Become Jehovah’s Friend—Sing With Us

Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ (Orin 2)

Fi orin yìí yin orúkọ Jèhófà lógo.

Bá A Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà (Orin 28)

Ṣé wàá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Ọ̀rọ̀ orin yìí lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára (Orin 60)

Jèhófà lè fún ẹ lágbára kó o lè ṣe ohun tó tọ́.

Jọ̀wọ́ Gbọ́ Àdúrà Mi (Orin 41)

Ibi yòówù kó o wà, tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó máa gbọ́ ẹ.

A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Rẹ Jèhófà (Orin 46)

Kí nìdí tó fi yẹ kí o dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà? Wo àwọn ìdí tá a ní bí a ṣe ń kọ orin yìí.

À Ń Wàásù fún Gbogbo Onírúurú Èèyàn (Orin 142)

Ṣé gbogbo èèyàn lo máa ń wàásù fún, láìka bí wọ́n ṣe rí sí?

“Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà” (Orin 67)

Ṣé o ti ṣe tán láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kíkọ́ orin nípa wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Fún Wa Ní Ìgboyà (Orin 73)

Jèhófà lè mú kó o nígboyà kó o lè máa sọ̀rọ̀ nípa orúkọ rẹ̀.

Ìgbé Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà (Orin 81)

Ṣé wà á fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà, kó o lè máa rí ìbùkún Jèhófà.

“Láti Ilé dé Ilé” (Orin 83)

Ìwọ náà lè lọ́wọ́ sí iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà!

Wá Wọn Lọ (Orin 150)

Oríṣiríṣi ọ̀nà ló wà tó o lè fi wá àwọn míì lọ kó o lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún (Orin 89)

Kí ìwọ pẹ̀lú Kọ́lá àti Tósìn jọ kọrin yìí kó o sì mọ ìdí tí a fi ń láyọ̀ tá a bá ń ṣègbọràn.

Bu Kun Ipejo Wa (Orin 93)

Maa ko orin yii bo o se n wo fidio taa je ko o mo ohun ti awon ore re kan maa n se ki won le lo si awon ipade wa.

Ṣíṣiṣẹ́ Pa Pọ̀ ní Ìṣọ̀kan (Orin 101)

Wo ìṣọ̀kan tó wà láàárín ẹgbẹ́ ará wa tó kárí ayé.

Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀ (Orin 111)

Kí ló ń fú ẹ láyọ̀?

Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́ (Orin 133)

Ránti Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà tó o ṣì kéré.

Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí (Orin 134)

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni àwọn ọmọ jẹ́? Kọ́ ọ̀rọ̀ inú orín yìí kó o bàa lè dara pọ̀ mọ́ kíkọ́ orin náà.

Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n” (Orin 135)

Ṣé o máa sapá gan-an láti mú ọkàn Jèhófà yọ̀? Wo fídíò yìí láti mọ bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìngbẹ́yín! (Orin 140)

Fojú inú wo ara rẹ bíi pé o wà láàyè títí láé nínú Párádísè bó o ṣe ń kọ orin yìí.

Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́ (Orin 141)

Fi orin yìí dánra wò fúngbà díẹ̀ kí o báa lè kọ ọ́ dáadáa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Tẹjú Mọ́ Èrè Náà! (Orin 144)

Bó o ṣe ń kọ orin yìí, máa ronú nípa bí ayé ṣe máa dùn tó nínu Párádísè.