Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà kárí ayé. Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè tó dá ọ̀run àti ayé là ń jọ́sìn. (Sáàmù 83:18; Ìfihàn 4:11) Kristẹni ni wá, a sì gbà gbọ́ pé Jésù Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run, òun sì ni Olùgbàlà wa. (Jòhánù 3:16; Ìṣe 4:10-12) Inú Bíbélì la ti rí gbogbo ohun tá a gbà gbọ́. (2 Tímótì 3:16) A rọ̀ ẹ́ pé kó o wo àwọn ohun tá a gbà gbọ́ lórí ìkànnì yìí, gbé Bíbélì ẹ dání, kó o sì máa wo àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí nínú Bíbélì ẹ.

Wàá mọ púpọ̀ sí i nípa wa tó o bá wo fídíò Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Iye

Ìsọfúnni Nípa Agbègbè Kọ̀ọ̀kan

Frequently Asked Questions

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Ní ṣókì, wo ohun mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tá a gbà gbọ́.

Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Ṣe Àwọn Ayẹyẹ Kan?

Wo bá a ṣe dáhùn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá di ọ̀rọ̀ ayẹyẹ àtàwọn àjọ̀dún táwọn èèyàn máa ń ṣe.

Kí Nìdí Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fí Ṣe Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí?

Gbé àwọn kókó mẹ́rin nípa ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí i yẹ̀ wò.

Ṣé Kristẹni Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Jọ̀wọ́ ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe yàtọ̀ sí àwọn míì tí wọ́n ń pè ní Kristẹni.

Àwọn ìbéèrè míì táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè

Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó o ní nípa wa.

Contact Us

Ṣé O Fẹ́ Ká Wá Ẹ Wá

O lè mọ̀ sí i nípa Bíbélì tàbí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lọ sí ìpàdé ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Wàá mọ ohun tá a máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa, wàá sì mọ ibi tá a ti ń ṣèpàdé tó sún mọ́ ẹ.

Kàn sí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìsọfúnni nípa bí ẹ ṣe lè kàn sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jákèjádò ayé.

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

O lè wá ibì kan tó sún mọ́ ẹ tó o lè ṣèbẹ̀wò sí.