Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Kò sẹ́ni tó mọ bí Jésù ṣe rí gẹ́lẹ́, torí Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa ìrísí rẹ̀. Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kò ṣe pàtàkì ká mọ bí Jésù ṣe rí. Àmọ́ Bíbélì mẹ́nu ba àwọn nǹkan kan tó lè jẹ́ ká mọ díẹ̀ nípa bí Jésù ṣe rí.
Ìrísí rẹ̀: Júù ni Jésù, ó sì ṣeé ṣe kó rí bí àwọn ará gúúsù ìwọ̀ oòrùn Éṣíà, torí ibẹ̀ ni ìyá rẹ̀ ti wá. (Hébérù 7:14) Kò dájú pé ìrísí rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìgbà kan wà tó rìnrìn àjò láti Gálílì lọ sí Jerúsálẹ́mù láìfu ẹnikẹ́ni lára, wọn ò sì dá a mọ̀. (Jòhánù 7:10, 11) Ó sì jọ pé kò dá yàtọ̀ láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù. Ká máà tún gbàgbé pé ṣe ni Júdásì Ísíkáríótù fún àwọn jàǹdùkú tó fẹ́ wá mú Jésù ní àmì tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tí wọ́n á mú.—Mátíù 26:47-49.
Bí irun rẹ̀ ṣe gùn tó: Kò dájú pé irun Jésù gùn, torí Bíbélì sọ pé “bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.”—1 Kọ́ríńtì 11:14.
Irùngbọ̀n rẹ̀: Jésù ní irùngbọ̀n. Ó máa ń tẹ̀ lé òfin àwọn Júù, èyí tó sọ pé àwọn ọkùnrin tó ti dàgbà ò gbọ́dọ̀ ‘ba eteetí irùngbọ̀n wọn jẹ́.’ (Léfítíkù 19:27; Gálátíà 4:4) Bákan náà, nígbà tí Bíbélì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ìyà tó máa jẹ Jésù, ó mẹ́nu ba irùngbọ̀n rẹ̀.—Aísáyà 50:6.
Ara rẹ̀: Ọ̀pọ̀ nǹkan ló tọ́ka sí i pé ara Jésù le. Nígbà tó ń wàásù lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ló rìnrìn àjò dé. (Mátíù 9:35) Ẹ̀ẹ̀mejì ló fọ tẹ́ńpìlì àwọn Júù mọ́, tó dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé, ìgbà kan sì wà tó fi pàṣán lé àwọn ẹran ọ̀sìn jáde níbẹ̀. (Lúùkù 19:45, 46; Jòhánù 2:14, 15) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ McClintock and Strong’s Cyclopedia sọ pé: “Gbogbo ìtàn iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù ṣe fi hàn pé ara [Jésù] le dáadáa.”—Ìdìpọ̀ Kẹrin, ojú ìwé 884.
Ìrísí ojú rẹ̀: Ara Jésù yá mọ́ọ̀yàn, ó sì lójú àánú. Ó dájú pé èyí máa ń hàn lójú rẹ̀. (Mátíù 11:28, 29) Onírúurú èèyàn ló máa ń wá ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù. (Lúùkù 5:12, 13; 7:37, 38) Kódà, ara máa ń tu àwọn ọmọdé tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀.—Mátíù 19:13-15; Máàkù 9:35-37.
Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa bí Jésù ṣe rí
Èrò tí kò tọ́: Àwọn kan máa ń sọ pé ilẹ̀ Áfíríkà ni Jésù ti wá torí pé ìwé Ìṣípayá fi irun rẹ̀ wé irun àgùntàn, ó sì fi ẹsẹ̀ rẹ̀ wé “idẹ tí ń dán.”—Ìṣípayá 1:14, 15, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.
Òótọ́: “Àmì” làwọn ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá. (Ìṣípayá 1:1) Kì í ṣe bí Jésù ṣe rí nígbà tó wà láyé ni àlàyé tó ṣe nípa irun rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dá lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń ṣàpẹẹrẹ irú ẹni tí Jésù jẹ́ lẹ́yìn tó jíǹde. Nígbà tí Ìṣípayá 1:14 sọ pé “orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí irun àgùntàn funfun, bí ìrì dídì,” kì í ṣe pé ó ń sọ pé irun rẹ̀ fẹ́lẹ́. Ohun tí àwọ̀ funfun yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ni ọgbọ́n tí Jésù ti ní bó ṣe ti wà láàyè látọjọ́ tó ti pẹ́. (Ìṣípayá 3:14) Kì í ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ń sọ ni pé irun Jésù fẹ́lẹ́ bí irun àgùntàn àbí pé ó kúnná lọ́wọ́ bíi yìnyín.
Ẹsẹ̀ Jésù “dà bí bàbà àtàtà nígbà tí ó bá pọ́n yòò nínú ìléru.” (Ìṣípayá 1:15) Bákan náà, ojú rẹ̀ “dà bí oòrùn nígbà tí ó bá ń ràn nínú agbára rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:16) Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé kò sí ẹ̀yà tí àwọ̀ wọn rí báyìí, a jẹ́ pé ohun kan ni ìran yìí ń ṣàpẹẹrẹ, ó ń fi Jésù tó ti jíǹde hàn ní “ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́.”—1 Tímótì 6:16.
Èrò tí kò tọ́: Ọ̀lẹ ni Jésù, kò sì lágbára.
Òótọ́: Jésù kì í ṣojo, akin ni. Bí àpẹẹrẹ, kò fara pa mọ́ fáwọn jàǹdùkú tó wá mú un, ó fìgboyà sọ fún wọn pé òun ni wọ́n ń wá. (Jòhánù 18:4-8) Ó sì dájú pé Jésù lágbára, torí ọ̀lẹ ò lè ṣiṣẹ́ káfíńtà, pẹ̀lú àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n máa ń lò yẹn.—Máàkù 6:3.
Kí wá nìdí tí Jésù fi nílò ẹni tó máa bá a gbé òpó igi oró rẹ̀? Kí sì nìdí tó fi kú ṣáájú àwọn yòókù tí wọ́n kàn mọ́gi bíi tiẹ̀? (Lúùkù 23:26; Jòhánù 19:31-33) Kó tó di pé wọ́n kan Jésù mọ́gi, ó ti rẹ Jésù gan-an. Kò sùn mọ́jú, lára ohun tó sì fà á ni pé ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ rárá. (Lúùkù 22:42-44) Lóru yẹn náà, àwọn Júù ti lù ú, nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, àwọn ará Róòmù fìyà jẹ ẹ́ gan-an. (Mátíù 26:67, 68; Jòhánù 19:1-3) Ara ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tó fi tètè kú nìyẹn.
Èrò tí kò tọ́: Ojú Jésù máa ń le koko, inú rẹ̀ kì í sì í dùn.
Òótọ́: Àwọn ànímọ́ tí Jèhófà, Bàbá Jésù lọ́run ní gẹ́lẹ́ ni Jésù náà ni. Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11; Jòhánù 14:9) Kódà, Jésù kọ́ àwọn míì lóhun tí wọ́n lè ṣe tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. (Mátíù 5:3-9; Lúùkù 11:28) Àwọn kókó yìí fi hàn pé inú Jésù máa ń dùn, ó sì sábà máa ń hàn lójú rẹ̀.