ORIN 86
A Gbọ́dọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà
-
1. Jèhófà ń ké sí gbogbo wa ká wá kẹ́kọ̀ọ́.
Ẹ̀mí àtìyàwó ń sọ pé: “Máa bọ̀.”
Àtìgbàdégbà l’Ọlọ́run ń kọ́ wa
Kí àlàáfíà wa lè pọ̀ yanturu.
-
2. Ó yẹ ká máa wá sípàdé ìjọ déédéé
Ká lè máa kẹ́kọ̀ọ́, ká ṣohun tó tọ́.
Ìpàdé wa yìí ń mú ká nígbàgbọ́,
Ẹ̀mí Ọlọ́run ló sì ń darí rẹ̀.
-
3. Inú wa ńdùn bá a ṣe ń gbọ́ tí àwọn ará
Ń fayọ̀ kọrin ìyìn ní ìpàdé.
Ká máa pàdé pọ̀ pẹ̀láwọn ará,
Ká lè máa fìfẹ́ gbé ara wa ró!
(Tún wo Héb. 10:24, 25; Ìfi. 22:17.)