ORIN 139
Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
-
1. Wo ara rẹ àtèmi náà
Bíi pé a wà nínú ayé tuntun.
Wo bí yóò ṣe rí lára rẹ
Pé gbogbo ayé wà lálàáfíà.
Kò sí èèyàn búburú mọ́;
Ìjọba Ọlọ́run dúró láé.
Àkókò ìtura ti dé fáráyé
A ó máa kọrin ìyìn jáde
látọkàn wá:
(ÈGBÈ)
“A dúpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa.
Ìjọba Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun.
Ayọ̀ kún ọkàn wa, a sì ń kọrin ọpẹ́.
Kí ògo, ìyìn àtọlá jẹ́ tìrẹ láé.”
-
2. Wo ara rẹ, wo èmi náà,
Bá ó ṣe jọ máa gbádùn láyé tuntun.
Ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́;
Kò sóhun tó máa dẹ́rù bà wá.
Ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ:
Àgọ́ rẹ̀ yóò bo gbogbo ayé.
Yóò sì jí àwọn tó ń sùn nínú ikú;
Àwọn àtàwa náà yóò máa
kọrin ọpẹ́:
(ÈGBÈ)
“A dúpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run wa.
Ìjọba Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun.
Ayọ̀ kún ọkàn wa, a sì ń kọrin ọpẹ́.
Kí ògo, ìyìn àtọlá jẹ́ tìrẹ láé.”
(Tún wo Sm. 37:10, 11; Àìsá. 65:17; Jòh. 5:28; 2 Pét. 3:13.)