alfa27/stock.adobe.com

Jésù Máa Fòpin sí Ìwà Ìkà

Jésù Máa Fòpin sí Ìwà Ìkà

 Jésù mọ ìrora tí ìwà ìkà àti àìṣèdájọ́ òdodo máa ń fà. Bí àpẹẹrẹ nígbà tó wà láyé, wọ́n parọ́ mọ́ ọn, wọ́n nà án láìṣẹ̀, wọ́n dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ọ̀daràn ni, wọ́n pa á ní ìpa ìkà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ó ṣe ohun tó fi hàn pé kò mọ tara ẹ̀ nìkan torí ó fínnúfíndọ̀ fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13) Ní báyìí, Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ kárí ayé, áá sì fòpin sí ìwà ìkà.—Àìsáyà 42:3.

 Báwo ni ayé ṣe máa rí tí Jésù bá fòpin sí ìwà ìkà? Bíbélì sọ pé:

  •   “Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́; wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọn ò ní sí níbẹ̀. Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ti ṣe fún wa àtohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká gbìyànjú láti mọ púpọ̀ sí i nípa “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Ìhìn rere yìí náà sì ni Jésù wàásù nígbà tó wà láyé. (Lúùkù 4:43) Ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?