APÁ 4
Ìjọba Ọlọ́run Jagun Mólú—A Fi Ìdí Ìhìn Rere Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin
KÁ SỌ pé lọ́jọ́ kan tí ò ń wàásù láti ilé dé ilé, o gbọ́ ìró fèrè ọkọ̀ ọlọ́pàá tó ń dún kíkankíkan, tó sì ń sún mọ́ tòsí. Bí o ṣe ń bá ẹni tó wà nílé tó kàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹni tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ń wo ọkọ̀ ọlọ́pàá náà bó ṣe wá dúró lọ́dọ̀ yín. Ọ̀kan lára wọn sọ̀ kalẹ̀, ó sì bi yín pé: “Ṣé ẹ̀yin méjèèjì lẹ̀ ń lọ sílé àwọn èèyàn, tẹ́ ẹ̀ ń báwọn sọ̀rọ̀ Bíbélì? Àwọn èèyàn ti ń fẹjọ́ yín sùn wá!” O dá wọn lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, o sì sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?
Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá máa nípa gan-an lórí ibi tọ́rọ̀ yìí máa já sí. Báwo ni ìjọba ṣe ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà látẹ̀yìn wá níbi tí ò ń gbé? Ǹjẹ́ wọ́n gbà wọ́n láyè láti máa ṣe ẹ̀sìn wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé akitiyan tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ṣe gan-an láti fi “ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin” láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. (Fílí. 1:7) Ibi yòówù kó o máa gbé, ìgbàgbọ́ rẹ máa túbọ̀ lágbára tó o bá ń ronú lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nínú àwọn ẹjọ́ tó ti kọjá. Nínú apá yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ẹjọ́ mánigbàgbé tó wáyé. Àwọn ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀ mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìjọba tó ti ń ṣàkóso lóòótọ́ ni Ìjọba Ọlọ́run, torí pé a ò lè ṣe àwọn àṣeyọrí yìí lágbára tiwa!
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 13
Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́
Àwọn adájọ́ láwọn kóòtù òde òní ṣe bíi Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ olùkọ́ Òfin nígbà àtijọ́.
ORÍ 14
Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo Là Ń Tì Lẹ́yìn
Sátánì ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọn kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú àti ogun, àmọ́ àwọn kan tí a kò ronú kàn ti gbé “odò” inúnibíni náà mì.
ORI 15
Bí A Ṣe Jà fún Òmìnira Láti Lè Máa Sin Jèhófà Láìsí Ìdíwọ́
Àwọn èèyàn Ọlọ́run ti jà fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa pa àwọn àṣẹ Ìjọba Ọlọ́run mọ́.