Johanu Ha Ṣàìní Ìgbàgbọ́ Bí?
Orí 38
Johanu Ha Ṣàìní Ìgbàgbọ́ Bí?
JOHANU Arinibọmi, tí ó ti wà ninu ẹ̀wọ̀n fun nǹkan bíi ọdun kan nisinsinyi, rí ìròhìn gbà nipa ajinde ọmọkunrin opó naa ní Naini. Ṣugbọn Johanu fẹ́ lati gbọ́ tààràtà lati ọ̀dọ̀ Jesu nipa ìjẹ́pàtàkì eyi, nitori naa ó rán meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati lọ beere pe: “Iwọ ni Ẹni Tí Ńbọ̀ naa tabi kí a maa retí ẹni tí ó yàtọ̀?”
Eyiini lè dabi ibeere tí ó ṣàjèjì, paapaa niwọn bi Johanu ti rí ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sì gbọ́ ohùn Ọlọrun nigba tí ó nbaptisi rẹ̀ ní nǹkan bí ọdun meji ṣaaju. Ibeere Johanu lè mú kí awọn kan parí èrò sí pe ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti jórẹ̀hìn. Ṣugbọn eyi kò rí bẹẹ. Jesu kì bá ti sọ̀rọ̀ ìyìn tí ó ga tobẹẹ nipa Johanu, eyi tí oun ṣe ní àkókò yii, kí a sọ pe Johanu ti bẹrẹsii ṣiyèméjì ni. Eeṣe, nigba naa, tí Johanu fi beere ibeere yii?
Johanu wulẹ lè fẹ́ ìmúdánilójú kan lati ọ̀dọ̀ Jesu pe Oun ni Mesaya naa. Eyi yoo fun Johanu lokun gidigidi niwọn bi oun ti ńlálàṣí ninu ẹ̀wọ̀n. Ṣugbọn bí ó ti hàn gbangba ibeere Johanu ní pupọ sí i ninu ju eyiini lọ. Oun dajudaju ńfẹ́ lati mọ̀ boya ẹlomiran yoo wà tí ńbọ̀wá, arọ́pò kan, gẹgẹ bi a ti lè sọ ọ́, tí yoo ṣe àṣepé ìmúṣẹ gbogbo awọn nǹkan tí a ti sọtẹ́lẹ̀ pe a ó ṣe àṣeparí rẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Mesaya naa.
Gẹgẹ bi awọn asọtẹlẹ Bibeli tí Johanu ti mọ̀ ti wí, Ẹni Àmì-òróró Ọlọrun yoo jẹ́ ọba kan, olùdáǹdè kan. Sibẹ, Johanu ni a mú sibẹsibẹ gẹgẹ bi ẹlẹ́wọ̀n kan, àní fun ọpọ oṣu lẹhin tí a ti baptisi Jesu. Nitori naa Johanu ni kedere nbeere lọwọ Jesu pe: ‘Iwọ ha ni ẹni naa tí yoo fi Ijọba Ọlọrun múlẹ̀ ninu agbára ni gbangba, tabi ẹlomiran kan nbẹ, arọ́pò kan, tí awa nilati dúró dè lati mú gbogbo awọn asọtẹlẹ tí ó niiṣe pẹlu ògo Mesaya ṣẹ?’
Dípò sísọ fun awọn ọmọ-ẹhin Johanu pe, ‘Dajudaju emi ni ẹni naa tí ó nilati wá!’ Jesu ní wakati yẹn gan-an ṣe ìfihànsóde tí ó pẹtẹrí nipa mímú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá kuro lọwọ gbogbo oniruuru òkùnrùn ati òjòjò. Lẹhin naa ni ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin naa pe: “Ẹ maa bá ọ̀nà yin lọ, ẹ ròhìn fun Johanu ohun tí ẹ rí tí ẹ sì gbọ́: awọn afọ́jú ńríran, awọn arọ ńrìn, a wẹ awọn adẹ́tẹ̀ mọ́, awọn adití sì ńgbọ́ràn, a ńjí awọn òkú dìde, a ńsọ ihinrere fun awọn òtòṣì.”
Lédè miiran, ibeere Johanu lè túmọ̀sí ìfojúsọ́nà kan pe Jesu yoo ṣe kọjá ohun tí o nṣe ati pe boya yoo sọ Johanu fúnraarẹ̀ di òmìnira. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, ńsọ fun Johanu lati maṣe reti ohun tí ó ju awọn iṣẹ́-ìyanu tí Jesu ńṣe.
Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu lọ kúrò, Jesu yíjúsí ogunlọgọ naa ó sì sọ fun wọn pe Johanu ni “ońṣẹ́” Jehofa tí a sọtẹ́lẹ̀ ní Malaki 3:1 ati pe oun ni wolii Elija tí a sọtẹ́lẹ̀ ní Malaki 4:5, 6. Oun nipa bayii kókìkí Johanu gẹgẹ bi ọgbọọgba pẹlu wolii eyikeyii tí ó ti walaaye ṣaaju rẹ̀, ní ṣíṣàlàyé pe: “Lóòótọ́ ni mo wí fun ẹyin ènìyàn, Láàárín awọn wọnni tí obinrin bí kò sí eyi tí a tíì gbé dìde tí ó tóbi jù Johanu Onírìbọmi; ṣugbọn ẹnikan tí ó kéré jù ninu ijọba awọn ọ̀run tóbi jù ú lọ. Ṣugbọn lati ọjọ́ Johanu Onírìbọmi títí wá di isinsinyi ijọba awọn ọ̀run ni góńgó tí awọn ènìyàn ńsárélé.”
Jesu níhìn-ín ńfihàn pe Johanu kì yoo sí ninu Ijọba ọ̀run naa, niwọn bi ẹni tí ó kéré jù nibẹ ti tóbi jù Johanu lọ. Johanu múra ọ̀nà silẹ fun Jesu ṣugbọn ó kú ṣaaju kí Jesu tó fi èdídí dí majẹmu, tabi àdéhùn naa, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lati jẹ́ alájùmọ̀ṣàkóṣo pẹlu rẹ̀ ninu Ijọba rẹ̀. Ìdí niyẹn tí Jesu fi sọ pe Johanu kì yoo sí ninu Ijọba ọrun naa. Kàkà bẹẹ Johanu yoo jẹ́ ọmọ-abẹ́ Ijọba Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé. Luuku 7:18-30; Matiu 11:2-15.
▪ Eeṣe tí Johanu fi beere boya Jesu ni Ẹni Tí Ńbọ̀ naa boya ẹni ọ̀tọ̀ miiran kan ni a nilati retí?
▪ Awọn asọtẹlẹ wo ni Jesu sọ pe Johanu múṣẹ?
▪ Eeṣe tí Johanu Arinibọmi kì yoo fi sí ní ọ̀run pẹlu Jesu?