JỌ́JÍÀ
Mo Fojú Ara Mi Rí Ohun tí Bíbélì Sọ!
Pepo Devidze
-
WỌ́N BÍ I NÍ 1976
-
Ó ṢÈRÌBỌMI 1993
-
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Jọ́jíà ló lọ dàgbà, ó sì máa ń tẹ̀ lé àwọn àṣà wọn délẹ̀délẹ̀. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì, òun àti ọkọ rẹ̀ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ní báyìí, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni wọ́n.
NÍGBÀ tí mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọmọ ilé-ìwé gíga ṣì ni mí ní ìlú Kutaisi. Ará àdúgbò wa kan sọ fún mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lo àwòrán tàbí ère nínú ìjọsìn wọn, wọn ò sì gbà pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè. Èyí ta ko ìgbàgbọ́ tí mo yàn láàyò torí pé onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni mí.
Nígbà tí mo pa dà sílùú mi ní Tsageri, ìyẹn nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1992, mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ìwàásù lọ pẹrẹu níbẹ̀. Ìyá mi ti gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan rere nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ torí pé mi ò gba tiwọn, ìyá mi sọ fún mi pé, “Lọ féti ara ẹ gbọ́ ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni.”
Àwọn arákùnrin méjì kan, ìyẹn Pavle àti Paata, tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ń wá sọ́dọ̀ ìdílé kan ládùúgbò wa. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ládùúgbò ló máa ń gbádùn wọn tí wọ́n bá ti dé, wọ́n á féti sí wọn, wọ́n á sì máa bi wọ́n ní ìbéèrè. Mo
wá ní màá jókòó tì wọ́n tí wọ́n bá tún pa dà wá. Gbogbo ìgbà tí mo bá béèrè ìbéèrè, àwọn arákùnrin náà á ṣí Bíbélì, wọ́n á sì ní kí n kà á fúnra mi. Ó jọ mí lójú gan-an pé mo fojú ara mi rí ohun tí Bíbélì sọ!Kò pẹ́ tí mo fi dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kan tí àwọn arákùnrin náà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún tó tẹ̀ lé e, mẹ́wàá lára wa ló ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, ìyá mi náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Tí mo bá ti rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú mi máa ń dùn pé gbogbo ìgbà ni àwọn arákùnrin náà máa ń jẹ́ kí n ka ìdáhùn fúnra mi látinú Bíbélì nígbà tí mo bá bi wọ́n ní ìbéèrè. Èyí jẹ́ kí ọkàn mi wálẹ̀ bí mo ṣe ń rí i pé ohun tí mo sọ pé mo gbà gbọ́ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Tí mo bá ń rántí àǹfààní tí mo ti rí nínú bí wọ́n ṣe fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè mi, mo máa ń lo ọ̀nà yìí láti jẹ́ kí àwọn míì náà mọyì òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!