Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
ORÍ 34
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
Ká sọ pé ìwọ àtàwọn ọmọbìnrin méjì kan jọ wà níbi tẹ́ ẹ ti ń jẹun níléèwé yín, lọmọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé bá wọlé wá.
Èyí àkọ́kọ́ sọ fún ẹ pé: “Ṣó o mọ̀ pé Brett gba tìẹ gan-an. Bó ṣe wò ẹ́ ni mo ti mọ̀. Ńṣe ló ń fojú bá ẹ sọ̀rọ̀!”
Èkejì ẹ̀ wá sọ sí ẹ létí pé: “Wò ó, jẹ́ n sọ fún ẹ, bọ̀bọ́ yẹn ò tíì lẹ́ni tó ń fẹ́!”
Ìwọ náà ti rò bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Torí pé, lọ́jọ́ kan báyìí, Brett ti pè ẹ́ pé kó o wá síbi àpèjẹ kan nílé wọn. O ò lọ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ o ti ń ro ibi tí gbogbo ẹ̀ ì bá ti já sí ká ló o lọ ni.
Ọmọbìnrin àkọ́kọ́ yẹn bá já lu nǹkan tó ò ń rò lọ́kàn.
Ó sọ pé: “Ó mà dùn mí pé mo ti ní bọ̀bọ́ tèmi o, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, lọ́wọ́ kan ni màá wọlé sí Brett lára.”
Ó wá wò ẹ́ bákan bákan. O ti ń ronú ibi tọ́rọ̀ yẹn ń lọ.
Ó bá sọ pé, “Kí ló dé tíwọ ò tiẹ̀ fi ní bọ̀bọ́ kankan?”
O kì í fẹ́ gbọ́ ìbéèrè yẹn! Ká sòótọ́, ó wù ẹ́ kí ìwọ náà ní bọ̀bọ́ kan tí wàá máa fẹ́. Àmọ́, wọ́n ti kọ́ ẹ pé ṣe ló yẹ kó o dúró dìgbà tó o bá ṣe tán láti ṣègbéyàwó kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ọkùnrin. Ká ní ò síyẹn ni . . .
Ọmọbìnrin kejì wá béèrè pé, “Ẹ kì í ṣerú ẹ̀ ní ìjọ yín, àbí?”
O wá rò ó lọ́kàn ara ẹ pé, ‘Àbó mọ nǹkan tó wà lọ́kàn mi ni?’
Ó wá fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ìwọ ò tiẹ̀ mọ̀ ju Bíbélì lọ láyé ẹ. Ṣó ò tiẹ̀ lè máa jayé orí ẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni?”
ṢÉ WỌ́N ti fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ rí torí pé ò ń gbìyànjú láti fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè ti máa rò ó pé ìlànà Bíbélì tó o fi ń ṣèwà hù yìí ni ò jẹ́ kó o lè jayé orí ẹ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Deborah pàápàá ti rò bẹ́ẹ̀ rí. Ó sọ pé: “Àwọn ìlànà Bíbélì ká mi lọ́wọ́ kò. Ó wù mí pé kémi náà máa ṣe nǹkan tí mo bá fẹ́ bíi tàwọn ọmọléèwé mi.”
Ṣàyẹ̀wò Ara Ẹ
Kò dìgbà téèyàn bá jìyà kó tó gbọ́n. Ká sòótọ́, ó bọ́gbọ́n mu, ó sì tún bá Ìwé Mímọ́ mu pẹ̀lú pé ká máa fọ̀rọ̀ ẹlòmíì kọ́gbọ́n, bí Ásáfù tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù ti ṣe. Ìgbà kan wà tó ronú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ti ń káni lọ́wọ́ kò jù. Àmọ́ nígbà tó rí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó pa ọ̀nà Ọlọ́run tì, ó túnnú ẹ̀ rò. Ó wá sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nígbà tó yá pé “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” ni wọ́n wà.—Sáàmù 73:18.
Bó o ti ń fọ̀rọ̀ Ásáfù yìí sọ́kàn, wá gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ, ìyẹn àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti fìgbà kan rí kọ àwọn ìlànà Bíbélì sílẹ̀, tí wọ́n sì ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó.
● Àwọn nǹkan wo ló mú kó o ronú bẹ́ẹ̀ yẹn tó sì mú kó o hùwà tó o hù?
Deborah: “Mo máa ń rí i pé gbogbo àwọn ọmọ iléèwé mi ló lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́, ó sì dà bíi pé, ìyẹn ń múnú wọn dùn. Bí mo bá wà láàárín wọn, tí mo sì rí bí wọ́n ṣe ń so mọ́ra wọn tí wọ́n sì ń fẹnu kora wọn lẹ́nu, ńṣe ló máa ń dà bíi pé èmi nìkan ni ò dákan mọ̀. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ronú nípa ọmọkùnrin kan tí mo fẹ́ràn. Ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mí láti máa wà lọ́dọ̀ ẹ̀.”
Mike: “Mo máa ń kàwé tó dá lórí ìbálòpọ̀, mo sì máa ń wo àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n tó máa ń jẹ́ kí ìbálòpọ̀ wù mí. Sísọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ mi túbọ̀ máa ń jẹ́ kó wù mí láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Témi àtọmọge bá dá wà, mo máa ń rò pé mo kàn lè fara rò ó lára láìbá a sùn àti pé mo mọ̀gbà tó yẹ kí n dúró.”
Andrew: “Mo máa ń wo àwòrán oníhòòhò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí lámujù. Mo sì máa ń lọ sóde àríyá pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tí ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà.”
Tracy: “Mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé kò yẹ kí n ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, àmọ́ mi ò kórìíra ẹ̀. Kò wù mí pé kí n ṣe é, àmọ́ bọ́ràn náà ṣe rí lára mi ò jẹ́ kí n lè ronú jinlẹ̀. Ó wá di pé ẹ̀rí ọkàn mi ò dá mi lẹ́bi mọ́.”
● Ṣé inú rẹ dùn sóhun tó o ṣe yẹn?
Deborah: “Inú mi kọ́kọ́ dùn pé kò sẹ́ni tó ń dí mi lọ́wọ́ mọ́ láti ṣe nǹkan tó wù mí àti pé èmi náà ti wá bẹ́gbẹ́ mu. Àmọ́
ayọ̀ yẹn ò tọ́jọ́. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé ìṣekúṣe ni mo ṣe, mi ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé mi ò tíì níbàálòpọ̀ rí, mo wá rí i pé tèmi ti bá mi. Mo wá kábàámọ̀ pé mo ti jẹ́ kẹ́nì kan já ìbálé mi.”Andrew: “Ńṣe ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti máa hùwà àìtọ́. Síbẹ̀, mò ń dára mi lẹ́bi, ohun tí mo ṣe sì bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an.”
Tracy: “Mo ti fi ìṣekúṣe bayé ara mi jẹ́. Ńṣe ni mo rò pé èmi àti bọ̀bọ́ tí mò ń fẹ́ yẹn máa gbádùn ara wa dọ́ba, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ìrora ọkàn, wàhálà àti ìbànújẹ́ la kàn kó ara wa sí. Òròòru ni mo máa ń wa ẹkún mu lórí bẹ́ẹ̀dì mi, mo máa ń kábàámọ̀ pé, ǹ bá sì ti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ o.”
Mike: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé nǹkan kan ti bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́. Mo gbìyànjú láti gbójú fo ẹ̀dùn ọkàn tí mò ń kó bá àwọn ẹlòmíì, àmọ́ kò ṣeé ṣe. Ó máa ń ká mi lára pé mò ń ba àwọn ẹlòmíì lọ́kàn jẹ́ bí mo ṣe ń gbádùn ara mi.”
● Ìmọ̀ràn wo lo ní fáwọn ọ̀dọ́ tó bá ń ṣiyè méjì bóyá àwọn ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà ń káni lọ́wọ́ kò?
Tracy: “Má ṣe fàwọn ìlànà Jèhófà ṣeré, àwọn tó fi ń ṣèwà hù ni kó o sì máa bá rìn. Ìyẹn ló lè fún ẹ láyọ̀.”
Deborah: “Má ṣe ronú láé pé ọ̀rọ̀ ara ẹ nìkan ni, ohun tó bá sì wù ẹ́ lo lè ṣe. Ohun tó o bá ṣe máa nípa lórí àwọn ẹlòmíì. Bó o bá sì kọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run, ìwọ lo máa jìyà tó pọ̀ jù.”
Andrew: “Bó ò bá tíì gbọ́n, ṣe lo máa rò pé báwọn ojúgbà ẹ ṣe ń jayé orí wọn ló dáa. Nìwọ
náà á bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tiwọn. Torí náà, fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó o má bàa kábàámọ̀.”Mike: “Ọ̀wọ̀ ara ẹni wà lára nǹkan pàtàkì tí Jèhófà dá mọ́ wa, kò sì fẹ́ ká máa ṣèṣekúṣe. Ṣe lo máa tara ẹ lọ́pọ̀, bó o bá sọ àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí nù torí pé o ò kóra ẹ níjàánu. Fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí ẹ àtàwọn àgbàlagbà míì. Bó o bá ti ṣàṣìṣe, má bò ó mọ́ra, tètè sọ fún wọn, kó o sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Bó o bá ń ṣe àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn tòótọ́.”
Ṣé Ìlànà Bíbélì Ń Ká Ẹ Lọ́wọ́ Kò Ni àbí Ó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?
“Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ kíwọ náà láyọ̀. (1 Tímótì 1:11; Oníwàásù 11:9) Àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì máa ṣe ẹ́ láǹfààní. O lè máa rò pé àwọn ìlànà yẹn ń ká ẹ lọ́wọ́ kò. Àmọ́, ká sòótọ́, àwọn ìlànà Bíbélì lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà wulẹ̀ ń dáàbò bò ẹ́ ni.
Ó dájú pé o lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì. Bó o bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù, wàá múnú Jèhófà dùn, wàá sì ṣera ẹ láǹfààní.—Aísáyà 48:17.
O lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Wádìí bó o ṣe lè ṣe é.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Aísáyà 48:17.
ÌMỌ̀RÀN
Ronú nípa bó o ṣe lè ṣàlàyé fún àbúrò ẹ pé àwọn ìlànà Bíbélì bọ́gbọ́n mu. Bó o bá ń ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára sí i.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Àjọṣe rere tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lè bà jẹ́ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, àmọ́ ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún láti tún un ṣe.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Ohun tí màá ṣe kí n lè mọ báwọn ìlànà Bíbélì ṣe bọ́gbọ́n mu tó ni pé ․․․․․
Bí ìwà àwọn tí kò fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù bá ń wù mí, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn jìyà kó tó gbọ́n, bó bá dọ̀rọ̀ rírú òfin Ọlọ́run?
● Kí lo rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ Deborah, Mike, Andrew àti Tracy?
● Kí nìdí táwọn kan fi lè máa ronú pé àwọn òfin Ọlọ́run ń ká àwọn lọ́wọ́ kò, àmọ́ kí nìdí tá a fi lè sọ pé wọn ò ro tọjọ́ ọ̀la mọ́ ọn?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 285]
“Ìbẹ̀rù bí wọ́n ṣe máa báàyàn wí tó bá ṣe nǹkan tí kò dáa ò burú tó ìnira téèyàn máa ní tó bá ń bò ó mọ́ra.”—Donna
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 288]
Àwọn ìlànà Bíbélì ò ká ẹ lọ́wọ́ kò; wọ́n wulẹ̀ ń dáàbò bò ẹ́ ni