Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo máa ń gbádùn bíbá àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ ṣeré

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mo Fẹ́ràn Baseball Gan-an!

Mo Fẹ́ràn Baseball Gan-an!
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1928

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: COSTA RICA

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ERÉ ÌDÍJE ÀTI TẸ́TẸ́ LÓ GBÀ MÍ LỌ́KÀN JÙ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

Àgbègbè Puerto Limón ni mo dàgbà sí, nítòsí etíkun Costa Rica. Ọmọ mẹ́jọ làwọn òbí mi bí, èmi ni wọ́n bí ṣìkeje. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí nígbà tí bàbá mi kú. Ẹrù ẹni méjì wá di tẹnì kan, màmá mi wá di òbí anìkàn-tọ́mọ.

Mo fẹ́ràn Baseball gan-an. Láti kékeré ni mo ti yan eré ìdárayá yìí láàyò. Nígbà tó kù díẹ̀ kí n pé ọmọ ogún ọdún, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ tó ń gbá Baseball. Lẹ́yìn tí mo lé lọ́mọ ogún ọdún, ọkùnrin kan tó ń wá àwọn tó mọ baseball gbá kiri rí bí mo ṣe ń gbá a, ó sì ní kí n wá dara pọ̀ mọ́ àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nílùú Nicaragua. Àmọ́, torí ara màmá mi ò yá, èmi sì ni mò ń tọ́jú wọn, kò ní rọrùn fún mi láti fi wọ́n sílẹ̀ kí n sì kó lọ sílùú Nicaragua. Torí náà, mo kọ̀ láti lọ. Nígbà tó yá, ẹlòmíì tún pè mí pé ki ń wá dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ tó ń gbá baseball fún orílẹ̀-èdè Costa Rica. Mo sì fara mọ́ ọn. Mo gbá baseball fún orílẹ̀-èdè Costa Rica láti ọdún 1949 títí di ọdun 1952, mo sì kópa nínú ìdíje tó wáyé lórílẹ̀-èdè Cuba, Mẹ́síkò àti Nicaragua. Mo mọ bọ́ọ̀lù mú dáadáa, kódà tí mo bá gbá géèmù yìí nígbà mẹ́tàdínlógún [17], mi ò ní ṣì í mú rárá. Orí mi máa ń wú táwọn èrò bá ń pariwo orúkọ mí ṣáá!

Ó dùn mí pé mo máa ń ṣèṣekúṣe gan-an nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo lẹ́ni tí mò ń fẹ́, síbẹ̀ mo tún láwọn obìnrin míì tí mò ń gbé. Mo tún máa ń mutí para. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà tí mo mutí débí pé mi ò mọ bí mo ṣe délé, mo kàn jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì ni mo bá ara mi lórí bẹ́ẹ̀dì! Mo máa ń ta tẹ́tẹ́ àtàwọn géèmù onítẹ́tẹ́ gan-an.

Bí mo ṣe ń bá ìgbésí ayé mi lọ nìyẹn. Àsìkò yìí ni màmá mi di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n gbìyànjú láti sọ ohun tí wọ́n gbàgbọ́ fún mi, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí nígbà yẹn torí eré ìdíje tí mò ń ṣe ló gbà mí lọ́kàn. Tí mo bá ń ṣe ìdánrawò lásìkò oúnjẹ, ebi kì í tiẹ̀ pa mí! Eré yìí nìkan ni mò ń fi gbogbo ọkàn mi rò. Mo fẹ́ràn baseball ju nǹkan míì lọ!

Àmọ́ nígbà tí mo pọ́mọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29], mo ṣèṣe gan-an lọ́jọ́ kan tí mò ń sáré láti mú bọ́ọ̀lù. Nígbà tára mi le, mi ò fi ṣiṣẹ́ ṣe mọ́. Àmọ́, mo ṣì ń kọ́ àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ tó wà nítòsí ilé mi ní baseball.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

Lọ́dún 1957, mo gba ìwé ìkésíni láti wá sí àpéjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní pápá ìṣeré kan tí mo ti gbá baseball rí. Bí mo ṣe jókòó láàárin èrò, mo kàn ṣáà ń ronú lórí ìyàtọ̀ tó wà láàárin bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe jókòó pẹ̀sẹ̀ àti ìwà jákujàku táwọn tó wá wòran máa ń hù nígbà tá a bá wá gbá baseball. Ohun tí mo rí yìí wú mi lórí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ wọn.

Ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì wú mi lórí gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. (Mátíù 24:14) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe ẹ̀sìn wọn torí owó. Jésù sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”Mátíù 10:8.

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni mò ń wo ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bóyá ó bá ohun tí wọ́n ń kọ́ mu. Ó wú mi lórí láti rí bí wọ́n ṣe ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè wàásù dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn. Mo tún rí i pé wọ́n lẹ́mìí ọ̀làwọ́ tí Jésù pàṣẹ pé káwọn Kristẹni ní. Nígbà tí mo sì ka Máàkù 10:21, mo rí i pé Jésù ń pe àwọn èèyàn pé: “Wá di ọmọlẹ́yìn” mi, ó wu èmi náà láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àmọ́ ó pẹ́ díẹ̀ kí n tó ṣe àwọn àtúnṣe kan nígbèésí ayé mi. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ta tẹ́tẹ́, ọ̀sẹ̀ kan ò sì lọ kí n má fi nọ́ńbà “oríire” ta á. Àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé Ọlọ́run kórìíra àwọn tó bá ń sin “ọlọrun Oríire” àtàwọn olójúkòkòrò. (Aísáyà 65:11; Kólósè 3:5) Torí náà, mi ò ta tẹ́tẹ́ mọ́. Sunday àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí mo fi tẹ́tẹ́ sílẹ̀ ni nọ́ńbà “oríire” mi jẹ! Àwọn èèyàn fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí mi ò wá ta tẹ́tẹ́ lọ́sẹ̀ yẹn, wọ́n sì ń dà mí láàmú pé kí n ta sí i, àmọ́ mo kọ̀. Mi ò tún pa dà sídìí tẹ́tẹ́ mọ́.

Mo tún kojú àdánwò láti ní “ìwà tuntun” ní ọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi ní àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Éfésù 4:24) Lálẹ́ ọjọ́ tá à ń wí yìí, bí mo ṣe pa dà sí òtẹ́ẹ̀lì tó mo dé sí, mo bá rí ọ̀rẹ́bìnrin mi tẹ́lẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà tó ń dúró dè mí. Ó wá ní: “Máa bọ̀ jàre Sammy, ká lọ gbádùn ara wa!” Ṣùgbọ́n ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo dá a lóhùn pé, “Mi ò ṣe!” Mo sì sọ fún un pé ìlànà Bíbélì ni mò ń tẹ̀ lé báyìí. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ńṣe ló jágbe mọ́ mi pé: “Kí ni gbogbo eléyìí?” Ó wá bẹnu àtẹ́ lu ìlànà Bíbélì nípa ìṣekúṣe, ó sì ní dandan àfi ká máa bá ìfẹ́ wa lọ. Àmọ́, ńṣe ni mo kàn wọnú yàrá mi lọ tí mo sì tilẹ̀kùn látẹ̀yìn. Inú mi dùn láti sọ fún yín pé látìgbà tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1958, mi ò tíì fi àwọn ìlànà Bíbélì tí mò ń tẹ̀ lé sílẹ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

Ó ṣe mí bíi pé kí n kọ̀wé nípa àǹfààní tí mo ti rí látinú títẹ̀lé ìlànà Bíbélì! Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní náà ni pé mo ti láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìgbésí ayé mi nítumọ̀ mo sì láyọ̀ tòótọ́.

Mo ṣì fẹ́ràn baseball, àmọ́ mi ò fi ṣiṣẹ́ ṣe mọ́. Nígbà tí mò ń gbá baseball mo lókìkí mo sì lówó, àmọ́ kò wà pẹ́. Ṣùgbọ́n, àjọ́ṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn ará máa wà pẹ́ títí. Bíbélì sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Ní báyìí, mo ti wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ ju ohunkóhun mìíràn lọ!