Privacy Settings

To provide you with the best possible experience, we use cookies and similar technologies. Some cookies are necessary to make our website work and cannot be refused. You can accept or decline the use of additional cookies, which we use only to improve your experience. None of this data will ever be sold or used for marketing. To learn more, read the Global Policy on Use of Cookies and Similar Technologies. You can customize your settings at any time by going to Privacy Settings.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?

Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. (Sáàmù 145:18, 19) Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká máa sọ ohunkóhun tó bá ń jẹ wá lọ́kàn fún un. (Fílípì 4:6, 7) Síbẹ̀, àwọn àdúrà kan wà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, inú Ọlọ́run ò dùn sí kéèyàn máa gba àdúrà àkọ́sórí.—Ka Mátíù 6:7.

Bákan náà, inú Jèhófà kì í dùn sí àdúrà àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀. (Òwe 28:9) Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Ọlọ́run kò fetí sí àdúrà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pààyàn. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé, tí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa àwọn ohun kan wà tí a gbọ́dọ̀ ṣe.—Ka Aísáyà 1:15.

Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó gbọ́ àdúrà wa?

Bí a kò bá ní ìgbàgbọ́, kò sí bí a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:5, 6) Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run wà àti pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún. A gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, torí pé orí àwọn ẹ̀rí àti ìdánilójú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàgbọ́ tòótọ́ dá lé.—Ka Hébérù 11:1, 6.

Ó yẹ ká máa gbàdúrà tọkàntọkàn àti pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Kódà, Jésù Ọmọ Ọlọ́run rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó ń gbàdúrà. (Lúùkù 22:41, 42) Torí náà, dípò ká máa yan ohun tí a fẹ́ lé Ọlọ́run lọ́wọ́, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti mọ ohun tí ó fẹ́ ká ṣe, tí a bá sì ń ka Bíbélì la tó lè mọ̀ wọ́n. Èyí á jẹ́ kí àdúrà wa máa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—Ka 1 Jòhánù 5:14.