Ẹ̀kọ́ Bíbélì

Ẹ̀kọ́ Bíbélì

Ẹ̀kọ́ Bíbélì

ỌMỌ ỌDÚN MẸ́TA ÀTI ÀWỌN TÍ KÒ TÓ BẸ́Ẹ̀

Kọ́lá gbọ́ pé ara ọ̀rẹ́ òun kò yá.

Ó sọ pé: “Mo mọ nǹkan tí màá ṣe.

Mo máa kọ lẹ́tà sí i kí ara rẹ̀ lè yá, màá sì lọ fún un!”

Máa ṣe oore, inú ẹ̀yin méjèèjì yóò sì dùn! 1 Pétérù 3:8

IṢẸ́ ÒBÍ

Ní kí ọmọ rẹ tọ́ka sí:

Ilé Tábìlì Kọ́lá

Oòrùn Ẹyẹ Igi

Dárúkọ ọ̀rẹ́ yín kan tí ara rẹ̀ kò yá, kí o sì bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀yin méjèèjì ṣe lè lọ kí ẹni náà.