Ǹjẹ́ O Lè Ní Àlàáfíà Nínú Ayé Oníwàhálà Yìí?
Ǹjẹ́ O Lè Ní Àlàáfíà Nínú Ayé Oníwàhálà Yìí?
ṢÉ ỌKÀN àwọn èèyàn balẹ̀ ní àdúgbò yín? Rárá ni ìdáhùn ọ̀pọ̀ èèyàn máa jẹ́ sí ìbéèrè yìí. Ìdí ni pé ogun, wàhálà àwọn olóṣèlú, ìjà ẹ̀yà tàbí mọ̀huru-mọ̀huru àwọn apániláyà ò jẹ́ kí wọ́n rímú mí. Táwọn nǹkan tá a mẹ́nu bà yìí ò bá tiẹ̀ yọ ẹ́ lẹ́nu, ó ṣeé ṣe kí ìwà ọ̀daràn, ìhalẹ̀mọ́ni àti aáwọ̀ láàárín ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ dòwò pọ̀ tàbí àwọn aládùúgbò rẹ kó wàhálà ọkàn bá ẹ. Kò sí àlàáfíà nínú ọ̀pọ̀ ìdílé pàápàá, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbógun tira wọn.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ káwọn ní àlàáfíà ọkàn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n wá ìfọ̀kànbalẹ̀ lọ sínú ìsìn, àwọn ibi tí wọ́n ti ń fáwọn èèyàn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣàṣàrò, wọ́n sì tún lè máa ṣàṣàrò bíi tàwọn ẹlẹ́sìn Híńdù. Àwọn kan rò pé àwọn á ní àlàáfíà ọkàn táwọn bá ń wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, táwọn ń rìnrìn àjò afẹ́, táwọn ń lọ sórí àwọn òkè ńláńlá àtàwọn igbó kìjikìji tàbí àwọn ibi tómi gbígbóná ti ń sun jáde. Kódà bó bá tiẹ̀ dà bíi pé àlàáfíà tó irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ó lè máà pẹ́ rárá tí wọ́n fi máa rí i pé kò tọ́jọ́.
Ibo wá lo ti lè rí ojúlówó àlàáfíà? Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa ni orísun àlàáfíà. Kí nìdí? Ìdí ni pé òun ni “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà.” (Róòmù 15:33) “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” ló máa wà nínú Ìjọba Ọlọ́run tí kò ní pẹ́ dé mọ́. (Sáàmù 72:7; Mátíù 6:9, 10) Gbólóhùn yìí yàtọ̀ sí àdéhùn àlàáfíà tí kò fìdí múlẹ̀ táwọn èèyàn máa ń ṣe. Irú àwọn àdéhùn bẹ́ẹ̀ kàn máa ń paná ìjà fúngbà díẹ̀ ni. Àmọ́ àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa mú gbogbo nǹkan tó ń fa ogun àti gbọ́nmi-si omi-ò-to kúrò pátápátá. Kódà, ẹnikẹ́ni ò ní kọ́ ogun jíjà mọ́. (Sáàmù 46:8, 9) Ojúlówó àlàáfíà nìyẹn máa jẹ́ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín!
orí kẹrin ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Fílípì. Tó o bá ti ṣí i, jọ̀wọ́ ka ẹsẹ 4 sí 13 nínú Bíbélì rẹ.
Àmọ́, láìka báwọn ohun tá à ń retí lọ́jọ́ ọ̀la ti lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó, ó ṣeé ṣe kó o máa wá bó o ṣe máa ní àlàáfíà ọkàn dé ìwọ̀n àyè kan láyé tá a ṣì wà yìí. Ṣé nǹkan kan tiẹ̀ wà tó o lè ṣe láti ní àlàáfíà tó máa mú kí ọkàn ẹ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nínú ayé oníwàhálà yìí? Inú wa dùn pé Bíbélì jẹ́ ká mohun tá a lè ṣe láti ní irú àlàáfíà ọkàn bẹ́ẹ̀. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà kan nínú“Àlàáfíà Ọlọ́run”
Ẹsẹ 7 kà pé: “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Kì í ṣe nípa wíwulẹ̀ ṣàṣàrò tàbí kíkọ́ láti ní àwọn ànímọ́ kan ni àlàáfíà yìí fi máa wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti ń wá. Àlàáfíà yìí lágbára débi pé “ó ta gbogbo ìrònú yọ.” Ó dájú pé ó lè borí gbogbo àníyàn, ìmọ̀ àti ìrònú wa. A lè má mọ ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú àwọn ìṣòro wa, àmọ́ àlàáfíà Ọlọ́run lè jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé lọ́jọ́ ọjọ́ kan àwọn ìṣòro wa máa di ohun ìgbàgbé.
Ṣéyẹn lè ṣeé ṣe báyìí? Lójú èèyàn, ó lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe, àmọ́ “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Fọkàn yàwòrán ọmọ kékeré kan tó sọ nù sínú ilé ìtajà ńlá kan. Ó dá a lójú pé tóun bá ti lè wá màmá òun kàn, ìṣòro òun ti yanjú nìyẹn. Ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run máa fà wá mọ́ra bí màmá ọmọ yẹn ṣe máa ṣe fún un nígbà tó bá rí i. Ó máa tù wá nínú, ó sì máa mú gbogbo àníyàn ọkàn wa kúrò.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ló ti ní àlàáfíà Ọlọ́run nígbà ìṣòro tó le koko. Bí àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe rí lára Nadine nígbà tí oyún bà jẹ́ lára ẹ̀. Ó ní: “Ó ṣòro fún mi gan-an láti ṣàlàyé bó ṣe ń ṣe mí, mo sì máa ń dọ́gbọ́n ṣe bíi pé kò síṣòro kankan. Àmọ́ nínú mi lọ́hùn-ún, ọkàn mi bà jẹ́ gidigidi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí mo sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́. Jèhófà sì máa ń gbọ́ àdúrà mi torí pé, nígbàkigbà tí ìbànújẹ́ bá dorí mi kodò, tí mo sì ronú pé, ‘Kò sọ́nà àbáyọ mọ́,’ ìgbà yẹn gan-an ni Jèhófà máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀, tí mo sì máa ń ní àlàáfíà. Mo máa ń nímọ̀lára pé kò séwu.”
Ó Ń Dáàbò Bo Ọkàn àti Èrò Inú Rẹ
Jẹ́ ká pa dà lọ ka ìwé Fílípì 4:7. Ó ní àlàáfíà Ọlọ́run á máa ṣọ́ ọkàn àti agbára ìrònú wa. Bí ìgbà tí ọmọ ogun kan bá ń ṣọ́ ibi tí wọ́n ní kó máa ṣọ́, àlàáfíà Ọlọ́run máa ń ṣọ́ ọkàn wa, kí ìrònú kíkó ọrọ̀ jọ, àwọn àníyàn tí kò pọn dandan àti ìrònú tí kò bá ti Ọlọ́run mu má bàa yọ́ wọnú ọkàn wa. Gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò.
Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé oníwàhálà yìí ló gbà pé káwọn tó lè láyọ̀, kí ọkàn àwọn sì balẹ̀, àwọn gbọ́dọ̀ lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn agbaninímọ̀ràn lè ní kí wọ́n ra ìpín ìdókòwò sáwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá. Ṣẹ́yẹn á wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ lóòótọ́? Kò dájú pé ọkàn wọn á balẹ̀. Àníyàn ọkàn lè mú kí wọ́n máa lọ yẹ ìníyelórí ìpín ìdókòwò wọn wò lójoojúmọ́ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá káwọn tà á, káwọn rà sí i tàbí káwọn ṣì ní sùúrù ná. Nígbà tí ìníyelórí àwọn ìpín ìdókòwò bá ń lọ sílẹ̀, àyà wọn á wá kó sókè. Ó dájú pé Bíbélì ò ní ká má ṣòwò, àmọ́ ó fún wa ní ìlàlóye tó jinlẹ̀ yìí pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú. Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.”—Oníwàásù 5:10, 12.
Nígbà tí Ìwé Fílípì 4:7 ń parí lọ, ó ní àlàáfíà Ọlọ́run á máa ṣọ́ ọkàn àti agbára ìrònú wa “nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Báwo ni àlàáfíà Ọlọ́run á ṣe máa ṣọ́ wa nípasẹ̀ Kristi Jésù? Ipa pàtàkì ni Jésù kó nínú mímú àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣẹ. Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 3:16) Òun náà tún ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá mọ ipa tí Jésù ń kó, ìyẹn á jẹ́ kí àlàáfíà jọba lọ́kàn wa. Báwo ló ṣe máa rí bẹ́ẹ̀?
Tá a bá fi tọkàntọkàn ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, Ìṣe 3:19) Tá a bá mọ̀ pé a ò lè gbádùn ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nísinsìnyí, àyàfi nígbà tí Ìjọba Kristi bá dé, a ò ní máa gbé ayé bíi pé a ò mẹ̀yìn ọ̀la. (1 Tímótì 6:19) Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ò ní máa yọ wá nínú gbogbo wàhálà, àmọ́ tá a bá fi ń dára wa lójú pé ìgbà ọ̀tun máa tó dé, ìyẹn á máa tù wá nínú.
Ọlọ́run á dárí jì wá, ìyẹn á sì jẹ́ ká ní àlàáfíà ọkàn. (Bó O Ṣe Lè Ní Àlàáfíà Ọlọ́run
Báwo lo wá ṣe lè ní àlàáfíà Ọlọ́run? Ìwé Fílípì 4:4, 5 sọ ọ́, ó ní: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀! Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Olúwa ń bẹ nítòsí.” Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù wà láìṣẹ̀ láìrò, nílùú Róòmù, nígbà tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. (Fílípì 1:13) Kàkà tí ì bá fi máa ronú lórí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ ẹ́ láìṣẹ̀ láìrò, ńṣe ló ń gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Kì í ṣe ipò tó wà ló ń jẹ́ kínú ẹ̀ máa dùn, àmọ́ àjọṣe tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwa náà ní láti kọ́ bá a ṣe lè máa gbádùn sísin Ọlọ́run láìka ipòkípò tá a bá bára wa sí. Bá a bá ṣe mọ Jèhófà dáadáa tó, tá a sì ń sapá gidigidi láti máa ṣohun tó fẹ́, bẹ́ẹ̀ la ó túbọ̀ máa gbádùn sísìn ín. Ìyẹn á sì jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà ọkàn.
Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa fòye báni lò. Tá a bá ń fòye bára wa lò, a ò ní máa ṣohun tó ju agbára wa lọ. A mọ̀ pé aláìpé ni wá; a ò sì lè máa ṣe dáadáa nínú gbogbo nǹkan. Kí wá nìdí tá a fi ní láti máa dá oorun mọ́ra wa lójú níbi tá a ti ń ronú nípa bá a ṣe fẹ́ máa hùwà pípé tàbí tá a ti ń ronú pé gbogbo nǹkan tiwa ló gbọ́dọ̀ ta tàwọn ẹlòmíì yọ? Kò sì yẹ ká máa retí pé káwọn ẹlòmíì pàápàá máa hùwà pípé. Ìyẹn á jẹ́ ká máa ní sùúrù nígbà táwọn ẹlòmíì bá ṣe ohun tó mú wa bínú. A tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfòyebánilò” yìí sí “ṣíṣàì rin kinkin.” Tá ò bá kí í rin kinkin nínú àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ tiwa, a ò ní máa dá aáwọ̀ sílẹ̀, torí pé kò sí àǹfààní kankan nínú aáwọ̀, kàkà kó ṣe wá láǹfààní, ṣe ló máa dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíì, tí ò sì ní jẹ́ káwa pẹ̀lú ní àlàáfíà ọkàn ní gbogbo ìgbà tó bá wáyé.
Ó lè dà bíi pé gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e nínú ìwé Fílípì 4:5, kò bá ohun tó ti ń sọ bọ̀ mu, ó ní: “Olúwa ń bẹ nítòsí.” Ọlọ́run ṣì ń bọ̀ wá fi ayé tuntun rọ́pò ayé ògbólógbòó yìí nígbà tí Ìjọba rẹ̀ bá dé. Àmọ́ ní báyìí, Ọlọ́run lè sún mọ́ gbogbo ẹni tó bá sún mọ́ ọn. (Ìṣe 17:27; Jákọ́bù 4:8) Tá a bá ń ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe sún mọ́ wa, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa láyọ̀, á jẹ́ ká máa fòye báwọn ẹlòmíì lò, a ò sì ní máa ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro tá a ní nísinsìnyí tàbí nípa ọjọ́ ọ̀la, gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ 6 ṣe sọ.
Tá a bá wo ẹsẹ 6 àti 7, a máa rí i pé àlàáfíà Ọlọ́run ló máa ń jẹ́ àbájáde àdúrà ní tààràtà. Àwọn kan gbà pé ṣíṣàṣàrò lásán ni àdúrà wà fún, wọ́n rò pé àwọn á ní ìbàlẹ̀ ọkàn táwọn bá ṣáà ti gba oríṣi àdúrà kan. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ojúlówó ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jèhófà ni àdúrà jẹ́, ó dà bí ìgbà tí ọmọ kan bá ń sọ àwọn nǹkan tó ń múnú ẹ̀ dùn àtàwọn nǹkan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún òbí onífẹ̀ẹ́ kan. Ẹ ò rí i bó ṣe tù wá nínú tó pé “ohun gbogbo” la lè bá Ọlọ́run sọ. Tí ohunkóhun bá ń jẹ wá lọ́kàn, ká sáà ti bá bàbá wa ọ̀run sọ ọ́.
Ẹsẹ 8 gbà wá níyànjú láti máa ronú nípa àwọn nǹkan rere. Ìyẹn nìkan kọ́ o. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 9 ti ṣàlàyé, a tún gbọ́dọ̀ máa fìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Ìyẹn á jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa mọ́. Abájọ tí òwe kan fi sọ pé: Ẹ̀rí ọkàn dà bí ìrọ̀rí tó ń jẹ́ ká lè sun oorun àsùnwọra!
Ó dájú pé o lè ní àlàáfíà ọkàn. Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ló ti ń wá, ó sì máa ń fi í fún àwọn tó bá sún mọ́ ọn, tí wọ́n sì fẹ́ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá mọ èrò Ọlọ́run. Fífi àwọn ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ṣèwà hù ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, àmọ́ èrè wà níbẹ̀ torí pé ‘Ọlọ́run àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú rẹ.’—Fílípì 4:9.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
‘Àlàáfíà Ọlọ́run yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.’—FÍLÍPÌ 4:7
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Ẹ ò rí i bó ṣe tù wá nínú tó láti mọ̀ pé “ohun gbogbo” la lè bá Ọlọ́run sọ