Jésù Borí Ìdẹwò
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Jésù Borí Ìdẹwò
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA MÁTÍÙ 4:1-11.
Ṣàpèjúwe bí aginjù tí Jésù ti lo ogójì [40] ọjọ́ ṣe rí.
․․․․․
Kí lo kíyè sí nínú bí Adẹniwò náà ṣe sọ̀rọ̀? àti bí Jésù ṣe fèsì?
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Báwo ni Sátánì ṣe fi hàn pé akóninífà lòun? (Tún ẹsẹ 2 kà.)
․․․․․
Kí nídìí tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Èṣù fi gbogbo ìjọba ayé lọ Jésù ó tún fi “ògo wọn” hàn-án? (Tún ẹsẹ 8 kà.)
․․․․․
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìjọba ayé ni Sátánì sọ pé òun máa gbé fún Jésù?
․․․․․
(a) Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tí Sátánì fi dẹ Jésù wò jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tí Sátánì ń rò lọ́kàn? ․․․․․
(b) Àmọ́, kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan èsì tí Jésù fún un jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tí Jésù ń rò lọ́kàn? ․․․․․
MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ìgbà tó ṣeé ṣe kí ìdẹwò wáyé.
․․․․․
Oríṣiríṣi ọ̀nà tí Sátánì lè gbà dẹ wá wò.
․․․․․
Béèyàn ṣe lè kojú ìdẹwò.
․․․․․
KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․