Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Èèyàn
ALÀGBÀ ìjọ ni François, orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló sì ń gbé, ó sọ pé: “Ìjà rẹpẹtẹ bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn ìdìbò kan tí èsì rẹ̀ kò tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn, èyí sì mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sá kúrò nílé wọn. A kò rí oúnjẹ àti oògùn, èyí tá a bá sì rí máa ń wọ́n gan-an. Àwọn ilé ìfowópamọ́ ò ṣiṣẹ́, owó tán nínú àwọn ẹ̀rọ sanwósanwó kan, àwọn míì sì bà jẹ́.”
Kíákíá ni àwọn arákùnrin láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò owó àtàwọn nǹkan míì táwọn Ẹlẹ́rìí tó sá filé sílẹ̀ nílò, wọ́n sì ń fi ránṣẹ́ sí wọn láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n kóra jọ sí káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹgbẹ́ tó ń bára wọn jà gbégi dí ojú ọ̀nà, wọ́n mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀ràn òṣèlú, wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì kọjá.
Arákùnrin François sọ pé: “Àwọn ọmọ ogun tó fara pamọ́ síbì kan yìnbọn lu ọkọ̀ wa nígbà tá à ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àmọ́ ńṣe ni àwọn ọta ìbọn náà gba àárín wa kọjá. Bá a ṣe rí sójà kan tó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ wa pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́, a yára fi ọkọ̀ sí rìfáàsì, a ṣẹ́rí pa dà, a sì kọrí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ńṣe là ń dúpẹ́ pé Jèhófà dá ẹ̀mí wa sí. Ní ọjọ́ kejì, gbogbo àádóje [130] àwọn ará tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sá lọ síbi tí ààbò wà. Díẹ̀ lára wọn wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara àti fún ìjọsìn Ọlọ́run títí tí rògbòdìyàn náà fi parí.”
Arákùnrin François ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ la gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa káàkiri orílẹ̀-èdè yìí lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Wọ́n ti rí bí àwọn ará wọn tó wà níbòmíràn ṣe ṣèrànwọ́ fún wọn, èyí sì mú kí ìgbọ́kànlé wọn nínú Jèhófà túbọ̀ pọ̀ sí i.”
Bóyá àjálù ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ni o, tàbí àwọn èèyàn ló fà á, a kì í sọ fún àwọn ará wa tó nílò ìrànlọ́wọ́ pé “kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa.” (Ják. 2:15, 16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa ti ara. Lọ́nà kan náà, nígbà tí ìkìlọ̀ kan wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pé ìyàn máa mú, “àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.”—Ìṣe 11:28-30.
Àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń fẹ́ láti fi àwọn ohun ìní ti ara ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣaláìní. Àmọ́ ṣá o, ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run. (Mát. 5:3) Nítorí pé Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a máa ń lo ọ̀pọ̀ lára àkókò wa, okun wa àti àwọn ohun ìní wa láti ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nínú ètò Ọlọ́run tá a wà, a máa ń fi díẹ̀ lára ọrẹ tó wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn pèsè ohun ìní ti ara fún àwọn tó ṣaláìní, ṣùgbọ́n a máa ń lo èyí tó pọ̀ jù lára ọrẹ yìí fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àti ìhìn rere náà. À ń tipa báyìí fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa.—Mát. 22:37-39.
A fẹ́ kí àwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé mọ̀ dájú pé à ń lo àwọn ọrẹ náà lọ́nà tó yẹ àti lọ́nà tó dára jù lọ. Ǹjẹ́ o lè pèsè ìtura fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ tó nílò ìrànlọ́wọ́? Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, “má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”—Òwe 3:27.