Òfin Ìfẹ́ Tá a Kọ Sínú Ọkàn
Òfin Ìfẹ́ Tá a Kọ Sínú Ọkàn
“Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí.”—JÉRÉMÁYÀ 31:33.
1, 2. (a) Kí la fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí báyìí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun wà láàárín àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì ní Òkè Sínáì?
NÍNÚ àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé nígbà tí Mósè ń sọ̀kalẹ̀ látorí Òkè Sínáì, ńṣe ni ìtànṣán ògo Jèhófà ń yọ ní ojú rẹ̀. A tún sọ̀rọ̀ nípa ìbòjú tí Mósè fi bojú. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ohun kan tó jẹ mọ́ ohun tá a ti kọ́ yìí, èyí tó ṣe pàtàkì fáwa Kristẹni lónìí.
2 Nígbà tí Mósè wà lórí òkè náà, Jèhófà fún un láwọn ìtọ́ni kan. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé jọ síwájú Òkè Sínáì, wọ́n rí ohun àgbàyanu kan tó jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà láàárín wọn. “Ààrá sán, mànàmáná sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ, àti àwọsánmà ṣíṣú dùdù lórí òkè ńlá náà àti ìró ìwo adúnròkè lálá, tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ibùdó fi bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì. . . . Òkè Ńlá Sínáì sì rú èéfín káríkárí, nítorí òtítọ́ náà pé Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀ nínú iná; èéfín rẹ̀ sì ń gòkè bí èéfín ẹbu, gbogbo òkè ńlá náà sì ń wárìrì gidigidi.”—Ẹ́kísódù 19:16-18.
3. Kí ni Jèhófà lò láti fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin Mẹ́wàá, kí sì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá mọ̀ nípa òfin wọ̀nyí?
3 Jèhófà gbẹnu áńgẹ́lì kan bá wọn sọ̀rọ̀ láti fún wọn ní àwọn òfin tá a wá mọ̀ sí Òfin Mẹ́wàá. (Ẹ́kísódù 20:1-17) Torí náà, kò sí àní-àní pé Ọlọ́run Olódùmarè ló pèsè àwọn òfin wọ̀nyí. Jèhófà kọ àwọn òfin náà sórí wàláà òkúta, ìyẹn àwọn òkúta tí Mósè fọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tó rí i tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe. Jèhófà wá tún àwọn òfin náà kọ sórí wàláà òkúta mìíràn. Lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ni ìtànṣán ń yọ ní ojú Mósè nígbà tó ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ tòun ti àwọn wàláà náà. Èyí jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ mọ̀ pé àwọn òfin náà ṣe pàtàkì gan-an.—Ẹ́kísódù 32:15-19; 34:1, 4, 29, 30.
4. Kí ló mú kí Òfin Mẹ́wàá ṣe pàtàkì gan-an?
4 Inú Àpótí Májẹ̀mú ni wọ́n tọ́jú àwọn wàláà méjì tí àwọn Òfin Mẹ́wàá náà wà sí, wọ́n sì gbé àpótí yìí sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn. Nígbà tó yá, wọ́n gbé e sínú tẹ́ńpìlì. Àwọn òfin wọ̀nyẹn sọ àwọn ìlànà pàtàkì tó wà nínú májẹ̀mú òfin, àwọn sì ni Ọlọ́run fi ń darí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àwọn òfin náà jẹ́ kó hàn gbangba pé Jèhófà ń bá àwọn èèyàn kan lò, ìyẹn àwọn tó yàn.
5. Báwo làwọn òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn?
5 Àwọn òfin wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà, pàápàá ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn rẹ̀. Dájúdájú, ẹ̀bùn pàtàkì làwọn òfin wọ̀nyẹn jẹ́ fún àwọn tó bá pa wọ́n mọ́! Ọ̀mọ̀wé kan kọ̀wé pé: “Kò sí òfin èyíkéyìí tí ọmọ aráyé tíì ṣe bóyá ṣáájú àkókò yẹn tàbí látìgbà yẹn wá, . . . tá a lè fi wé òfin mẹ́wàá tí Ọlọ́run fúnni yìí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí òfin ọ̀hún dára jù wọ́n lọ.” Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa Òfin Mósè lódindi, ó sọ pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi. Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.”—Ẹ́kísódù 19:5, 6.
Òfin Tí Ọlọ́run Kọ sí Ọkàn
6. Òfin wo ló ṣe pàtàkì ju àwọn òfin tá a kọ sórí òkúta lọ?
6 Dájúdájú, àwọn òfin wọ̀nyẹn ṣe pàtàkì gan-an ni. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ohun kan tó ṣe pàtàkì gidigidi ju àwọn òfin tá a kọ sára wàláà òkúta lọ? Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun yóò bá wọn dá májẹ̀mú tuntun kan tó yàtọ̀ sí májẹ̀mú òfin tó bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá. Ó sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí.” (Jeremáyà 31:31-34) Jésù tó jẹ́ Alárinà májẹ̀mú tuntun náà kò fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní òfin tí wọ́n kọ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló tẹ òfin Jèhófà mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn, àwọn ohun tó sọ àti ohun tó ṣe ló sì fi ṣe èyí.
7. Àwọn wo ni Ọlọ́run kọ́kọ́ fún ní “òfin Kristi,” àwọn wo ló sì wá tẹ́wọ́ gbà á nígbà tó yá?
7 “Òfin Kristi” ni òfin yìí. Kì í ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jákọ́bù ni Ọlọ́run fún ní òfin yìí, orílẹ̀-èdè tẹ̀mí ló kọ́kọ́ fún, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:2, 16; Róòmù 2:28, 29) Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ló para pọ̀ di Ísírẹ́lì Ọlọ́run yìí. Nígbà tó yá, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tún pẹ̀lú wọn torí ó wu àwọn náà láti jọ́sìn Jèhófà. (Ìṣípayá 7:9, 10; Sekaráyà 8:23) Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì ló tẹ́wọ́ gba “òfin Kristi,” ìyẹn ni pé wọ́n ń jẹ́ kó darí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.—Jòhánù 10:16.
8. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Òfin Mósè àti òfin Kristi?
8 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló wà lábẹ́ Òfin Mósè torí pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì la bí wọn sí, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fáwọn Kristẹni, torí pé àwọn fúnra wọn ló máa pinnu pé àwọn fẹ́ wà lábẹ́ òfin Kristi. Kì í ṣe ibi tí wọ́n bí wọn sí àti ìran wọn ló máa pinnu èyí. Wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀, ó sì wù wọ́n láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Òfin Ọlọ́run tó ‘wà nínú ọkàn’ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló ń mú kí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà, kì í ṣe torí pé wọ́n ń bẹ̀rù pé ó máa fìyà jẹ wọ́n tí wọn ò bá ṣègbọràn tàbí nítorí pé ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún wọn. Ohun tó ṣe pàtàkì tó sì lágbára gan-an yìí ló ń mú kí wọ́n ṣègbọràn. Bákan náà, òfin Ọlọ́run tó wà lọ́kàn àwọn tí wọ́n jẹ́ ara àgùntàn mìíràn ló mú kí wọ́n jẹ́ onígbọràn.
Òfin Tó Jẹ́ Òfin Ìfẹ́
9. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ìfẹ́ ni lájorí àwọn òfin Jèhófà?
9 Ìfẹ́ ni lájorí gbogbo àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà. Ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn mímọ́. Bó ṣe rí látọjọ́ pípẹ́ nìyẹn, bẹ́ẹ̀ sì ni yóò ṣe máa rí lọ. Nígbà tí ẹnì kan béèrè òfin tó tóbi jù lọ nínú Òfin Mẹ́wàá lọ́wọ́ Jésù, ó dáhùn pé: “Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” Èkejì ni pé: “Nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Jésù wá sọ pé: “Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.” (Mátíù 22:35-40) Nípa báyìí, Jésù jẹ́ kó hàn pé kì í ṣe gbogbo Òfin Mẹ́wàá àtàwọn òfin yòókù nìkan ló jẹ́ òfin ìfẹ́, gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù lódindi ni.
10. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìfẹ́ ni lájorí òfin Kristi?
10 Ṣé ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì náà ni lájorí òfin tó wà ní ọkàn àwọn Kristẹni? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni! Kéèyàn tó lè pa òfin Kristi mọ́ ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkànwá, òfin tuntun kan sì tún wà nínú òfin náà, ìyẹn ni pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ fún ara wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó sì fi tinútinú fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìfẹ́ alọ́májàá tí wọ́n ní fún ara wọn ni ohun pàtàkì tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn gan-an ni Kristẹni tòótọ́. (Jòhánù 13:34, 35; 15:12, 13) Kódà, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Mátíù 5:44.
11. Kí ni Jésù ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aráyé?
11 Tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ hàn, kò sẹ́ni tó dà bíi Jésù. Nígbà tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára lọ́run, ó gbà tinútinú pé òun yóò wá ṣe ohun tó máa túbọ̀ gbé orúkọ Baba rẹ̀ ga lórí ilẹ̀ ayé. Yàtọ̀ sí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ káwọn ẹlòmíràn lè wà láàyè títí láé, ó tún kọ́ àwọn èèyàn bó ṣe yẹ kí wọ́n gbé ìgbé ayé wọn. Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onínúure, ó ń gba ti àwọn èèyàn rò, ó sì ń ran àwọn tí wọ́n wà nínú ìsìnrú àti ìnira lọ́wọ́. Bákan náà, ó tún máa ń sọ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun” fún àwọn èèyàn, ó sì máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.—Jòhánù 6:68.
12. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì wa wọnú ara wọn?
12 Ká sòótọ́, ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì wa wọnú ara wọn gan-an. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá . . . Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòhánù 4:7, 20) Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ ti ṣẹ̀ wá, òun gan-an sì ni ìfẹ́. Ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìdí tá a fi lè fi ìfẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn lò ni pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Bí a bá ń fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọnìkejì wa lò, yóò hàn gbangba pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
Ìgbọràn Ló Máa Fi Hàn Pé A Ní Ìfẹ́
13. Kí la gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
13 Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá ò lè rí? Ohun pàtàkì àkọ́kọ́ ni pé ká sapá láti mọ̀ ọ́n. A ò lè sọ pé a ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ẹni tá ò mọ̀ rí, a ò sì lè fọkàn tán an. Ìdí nìyí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi rọ̀ wá pé ká sapá láti mọ Ọlọ́run. Bá a sì ṣe lè mọ̀ ọ́n ni pé ká máa ka Bíbélì, ká máa gbàdúrà, ká sì máa bá àwọn tó ti mọ̀ ọ́n tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kẹ́gbẹ́. (Sáàmù 1:1, 2; Fílípì 4:6; Hébérù 10:25) Àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí nítorí pé wọ́n á jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi. Yóò túbọ̀ wù wá gan-an láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bá a bá sapá láti mọ̀ ọ́n tá a sì mọrírì ìfẹ́ tó fi hàn sí wa. Bẹ́ẹ̀ ni o, a ní láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
14. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn òfin Ọlọ́run kì í ṣe ohun tó nira?
14 Bí a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, a ó mọ ohun tí onítọ̀hún fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́, a ó sì máa fi àwọn ohun wọ̀nyí sọ́kàn bá a ṣe ń bá ẹni náà lò. A ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú bí ẹni tá a bá fẹ́ràn. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Àwọn àṣẹ rẹ̀ ò pọ̀ jù fún wa, wọn ò sì nira jù fún wa torí pé ìfẹ́ ló ń mú ká pa wọ́n mọ́. A kì í há ọ̀pọ̀ òfin sórí tí a óò máa tẹ̀ lé nínú gbogbo ohun tá a bá fẹ́ ṣe, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run ló ń darí wa. Bí a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kò ní ni wá lára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Nípa báyìí, a óò rí ojú rere Ọlọ́run, a ó sì jàǹfààní torí pé kò sígbà tí ìtọ́sọ́nà rẹ̀ kì í ṣe wá láǹfààní.—Aísáyà 48:17.
15. Kí ló máa jẹ́ ká lè fara wé Jèhófà? Ṣàlàyé.
15 Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló ń mú ká fara wé e. Bí a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, àwọn ìwà rẹ̀ á wù wá a ó sì fẹ́ láti dà bíi rẹ̀. Ronú nípa àjọṣe Jèhófà àti Jésù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún ni àwọn méjèèjì fi wà lọ́run. Àwọn méjèèjì sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ ọ̀run gan-an débi tó fi lè sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba.” (Jòhánù 14:9) Bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, tí a sì ń mọyì wọn sí i, yóò máa wù wá láti fìwà jọ wọ́n. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, [kí a] sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara [wa] láṣọ.”—Kólósè 3:9, 10; Gálátíà 5:22, 23.
Ohun Tí Ìfẹ́ Mú Kí Àwọn Kan Ṣe
16. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa?
16 Ìfẹ́ táwa Kristẹni ní fún Ọlọ́run àtàwọn ọmọnìkejì wa ló ń mú ká máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn, “ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Èyí á jẹ́ ká lè máa láyọ̀ bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí òfin Kristi lè wà nínú ọkàn wọn. Bí wọ́n bá sì ń tẹ̀ síwájú tí ìwà wọn ń yí padà tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti dà bíi Jèhófà, inú wa yóò máa dùn. (2 Kọ́ríńtì 3:18) Ká sòótọ́, ẹ̀bùn tó dára jù lọ tá a lè fún àwọn èèyàn ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Àwọn tó bá di ọ̀rẹ́ Jèhófà lè máa bá a ṣọ̀rẹ́ títí ayérayé.
17. Kí nìdí tó fi dára pé ká sapá láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn dípò ká nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara?
17 Nínú ayé tá à ń gbé yìí, àwọn èèyàn ti sọ nǹkan ti ara di bàbàrà, àní wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Àmọ́ o, nǹkan tara kì í wà títí ayé. Olè lè jí wọn tàbí kí wọ́n bà jẹ́. (Mátíù 6:19) Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:16, 17) Bẹ́ẹ̀ ni o, títí ayé ni Jèhófà yóò máa wà, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń sìn ín ṣe máa wà títí ayé. Látàrí èyí, ǹjẹ́ kò ní dára jù tá a bá sapá láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn dípò ká máa lépa àwọn nǹkan inú ayé, èyí tí kì í wà títí ayé?
18. Báwo ni míṣọ́nárì kan ṣe fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn?
18 Àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ máa ń mú káwọn èèyàn fìyìn fún Jèhófà. Wo àpẹẹrẹ míṣọ́nárì kan lórílẹ̀-èdè Senegal tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sonia. Ó kọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Heidi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkọ obìnrin náà tí kì í ṣe onígbàgbọ́ sì ti kó àrùn éèdì ràn án. Lẹ́yìn tí ọkọ Heidi kú, Heidi ṣèrìbọmi, àmọ́ kò pẹ́ sígbà náà ni àìsàn rẹ̀ burú sí i, tí wọ́n sì dá a dúró sílé ìwòsàn. Sonia sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ṣe bẹbẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò pọ̀ rárá. Wọ́n ní kí àwọn ará ìjọ yọ̀ǹda ara wọn láti tọ́jú Heidi nígbà tó wà nílé ìwòsàn. Ẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ ni mo tẹ́ ẹní mi sí lóru ọjọ́ kejì, mo sì ṣaájò rẹ̀ títí tó fi kú. Dókítà tó jẹ́ ọ̀gá ilé ìwòsàn náà sọ pé: ‘Èyí tó tiẹ̀ wá le jù níbẹ̀ ni pé ńṣe làwọn mọ̀lẹ́bí ẹni tó bá lárùn yìí pàápàá máa ń pa a tì tí wọ́n bá ti rí i pé ó ní àrùn éèdì. Kí ló wá dé tí ìwọ tí kì í ṣe mọ̀lẹ́bí aláìsàn yìí, tí ẹ kì í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà, àní tí ẹ kì í ṣe ẹ̀yà kan náà, ṣe wá dúró tì í bẹ́ẹ̀ nígbà tó o mọ̀ pé bó ò bá ṣọ́ra àrùn náà lè ràn ọ́?’ Mo ṣàlàyé fún un pé bí ọmọ ìyá ni Heidi jẹ́ sí mi, a sún mọ́ra gan-an ni. Nítorí pé Heidi sún mọ́ mi bí ọmọ ìyá, kò ṣòro fún mi rárá láti tọ́jú rẹ̀.” Kẹ́ ẹ sì wá wò ó o, kò sóhun tó ṣe Sonia pẹ̀lú gbogbo bó ṣe fi ìfẹ́ tọ́jú Heidi.
19. Níwọ̀n bí òfin Ọlọ́run ti wà nínú ọkàn wa, kí ló yẹ ká máa lo àǹfààní tá a bá ní láti ṣe?
19 Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n ń fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn. Kò sí òfin kankan tó wà lákọsílẹ̀ tá a fi lè dá àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ lónìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ inú Hébérù 8:10 ló ń ṣẹ. Ẹsẹ Bíbélì náà kà pé: “‘Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,’ ni Jèhófà wí. ‘Ṣe ni èmi yóò fi àwọn òfin mi sínú èrò inú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ wọ́n sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.’” Ẹ jẹ́ ká máa mọrírì òfin ìfẹ́ tí Jèhófà kọ sí ọkàn wa, ká sì máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti fi ìfẹ́ hàn.
20. Kí nìdí tí òfin Kristi fi jẹ́ ohun iyebíye?
20 Kò sí àní-àní pé bí àwa àtàwọn ará wa jákèjádò ayé tí wọ́n ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ṣe jọ ń sin Ọlọ́run ń mú ká láyọ̀ gan-an! Àwọn tí òfin Kristi wà nínú ọkàn wọn ní ohun iyebíye kan nínú ayé táwọn èèyàn kì í ti í fìfẹ́ hàn yìí. Kì í ṣe pé wọ́n ń jàǹfààní ìfẹ́ Jèhófà nìkan ni, inú wọn tún ń dùn sí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tó wà láàárín wọn. “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà, èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń sọ, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ìṣọ̀kan wà nínú ẹ̀sìn wọn, irú ìṣọ̀kan yìí ò sì sí níbòmíràn. Ìṣọ̀kan tí wọ́n ní yìí sì ń mú kí wọ́n rí ojú rere Jèhófà. Ẹni tó kọ Sáàmù 133 sọ pé: “Ibẹ̀ [àárín àwọn tí ìfẹ́ mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan] ni Jèhófà pàṣẹ pé kí ìbùkún wà, àní ìyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 133:1-3.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Báwo ni Òfin Mẹ́wàá ṣe ṣe pàtàkì tó?
• Kí ni òfin tí Ọlọ́run kọ sí ọkàn àwọn Kristẹni?
• Báwo ni ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó nínú “òfin Kristi”?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ìfẹ́ wa hàn sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn òfin tí Ọlọ́run kọ sórí wàláà òkúta làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń tẹ̀ lé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Inú ọkàn àwọn Kristẹni ni òfin Ọlọ́run tí wọ́n ń tẹ̀ lé wà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Sonia rèé àti ọmọ ilẹ̀ Senegal kan ní ìpàdé àgbègbè ọdún 2004