Kí Ló Máa Sọ Bí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ á Ṣe rí?
Kí Ló Máa Sọ Bí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ á Ṣe rí?
ẸLẸ́KỌ̀Ọ́ ẹfolúṣọ̀n tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Gray kọ̀wé pé: “Bí ẹranko kò ṣe lè pa kádàrá rẹ̀ dà, bẹ́ẹ̀ lèèyàn náà ò ṣe lè pa kádàrá rẹ̀ dà.” Àmọ́, ìdàkejì ìyẹn lohun tí òǹkọ̀wé Shmuley Boteach sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní An Intelligent Person’s Guide to Judaism, ó sọ pé: “Nítorí pé èèyàn kì í ṣe ẹranko, èèyàn lè pinnu bó ṣe fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun rí.”
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé òótọ́ lohun tí Gray sọ. Wọ́n gbà pé ohun kan tí ẹ̀dá èèyàn ò lágbára lé lórí ló ń pinnu kádàrá ọmọ aráyé tàbí bí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ yóò ṣe rí. Àwọn míì ní tiwọn gbà pé Ọlọ́run tó dá èèyàn ti fún èèyàn lágbára láti pinnu bó ṣe fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun rí.
Àwọn kan tún gbà pé ohun táwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn láwùjọ bá ṣe ló máa sọ bí ọjọ́ ọ̀la àwọn yóò ṣe rí. Òǹkọ̀wé Roy Weatherford kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó wà láyé, pàápàá àwọn obìnrin, ni kò . . . lè pinnu bí ayé wọn ṣe máa rí. Ìdí ni pé àwọn èèyàn máa ń ni wọ́n lára wọ́n sì máa ń pọ́n wọn lójú.” (Ìwé The Implications of Determinism) Àwọn olóṣèlú tàbí àwọn ológun tó máa ń bára wọn figa gbága ti sọ ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ di èèyàn gidi di ẹdun arinlẹ̀.
Bákan náà, látìgbà ìwáṣẹ̀ làwọn èèyàn ti ń ronú pé kò sóhun táwọn lè ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn nítorí wọ́n rò pé ohun kan tí ẹ̀dá èèyàn ò lágbára lé lórí ló ń pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wọn yóò ṣe rí. Òǹkọ̀wé Boteach sọ pé: “Èrò tó gba àwọn Gíríìkì ayé ọjọ́un lọ́kàn ni pé asán ni gbogbo ìrètí téèyàn bá ní nítorí pé èèyàn ò lè yí ohun tí wọ́n ti kádàrá mọ́ ọn tẹ́lẹ̀ padà.” Wọ́n gbà pé àwọn abo ọlọ́run tó máa ń ṣe ohun tó bá wù wọ́n ló máa ń pinnu kádàrá ẹnì kọ̀ọ̀kan.
Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn abo ọlọ́run yìí ló ń pinnu ìgbà téèyàn máa kú. Wọ́n tún gbà gbọ́ pé àwọn ni wọ́n ń pinnu bí ìyà àti wàhálà téèyàn á rí jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ yóò ṣe pọ̀ tó.Lónìí, ọ̀pọ̀ ibi làwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé ohun kan tí ẹ̀dá èèyàn ò lágbára lé lórí ló ń sọ bí ọjọ́ ọ̀la èèyàn yóò ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé àyànmọ́ wà. Wọ́n sọ pé ohun tó máa jẹ́ àbájáde gbogbo ohun téèyàn bá ṣe àti ìgbà téèyàn máa kú ni Ọlọ́run ti yàn mọ́ wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Bákan náà, wọ́n tún gbà gbọ́ pé àkọọ́lẹ̀ Ọlọ́run wà. Wọ́n ní Ọlọ́run Olódùmarè “ti kọ ìgbàlà mọ́ àwọn kan, pé ó sì ti kọ ìparun mọ́ àwọn mìíràn.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ló gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́.
Kí lèrò tìẹ? Ǹjẹ́ o rò pé ohun kan tí o kò lágbára lé lórí ti pinnu bí ọjọ́ ọ̀la rẹ yóò ṣe rí? Òǹkọ̀wé William Shakespeare, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó máa ń kọ eré onítàn sọ pé: “Nígbà mìíràn, èèyàn ló máa ń fúnra rẹ̀ pinnu bó ṣe fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun rí.” Ǹjẹ́ òótọ́ wà nínú ohun tó sọ yìí? Wo ohun tí Bíbélì wí lórí ọ̀rọ̀ yìí.