A Ṣí Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Sílẹ̀ fún Gbogbo Èèyàn Láti Wò
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
A Ṣí Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Sílẹ̀ fún Gbogbo Èèyàn Láti Wò
NÍGBÀ tí Jésù Kristi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba, ó gbà wọ́n níyànjú láti “wàásù rẹ̀ láti orí ilé.” (Mátíù 10:27) Dájúdájú, wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wọn ní gbangba, níṣojú gbogbo èèyàn. Nítorí ìlànà kan náà yìí ni ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi jẹ́ èyí tá à ń ṣe ní gbangba. Àìfi nǹkan kan pa mọ́ yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún àwa Ẹlẹ́rìí láti borí àtakò, ó sì ń jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dáa wò wá.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn la máa ń sọ pé kó wá sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ ẹ̀tanú máa ń jẹ́ káwọn kan lọ́ tìkọ̀ láti wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Finland gan-an nìyẹn. Àwọn mìíràn sì wà tó jẹ́ pé ìtìjú ni kì í jẹ́ kí wọ́n lọ síbi tí wọn ò dé rí. Nígbà tá a bá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan tàbí tá a bá tún èyí tá à ń lò tẹ́lẹ̀ ṣe, a sábà máa ń ṣètò fún ṣíṣí ilé náà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti wò. A lè sapá lọ́nà àkànṣe láti pe gbogbo àwọn aládùúgbò wa wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà kí wọ́n lè túbọ̀ mọ púpọ̀ sí i nípa ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ní àgbègbè kan, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò láti pín ìwé ìròyìn ní ọjọ́ kan náà tí wọ́n ṣí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti wò. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì bá bàbá àgbàlagbà kan pàdé tó sọ pé òun máa ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! dáadáa. Àwọn arákùnrin náà sọ nípa ilé tí wọ́n ṣí sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti wò fún un, wọ́n sì sọ pé àwọn á mú un lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ọkùnrin náà sọ pé inú òun yóò dùn láti bá wọn lọ. Ìyàwó rẹ̀ tó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lọgun pé, “O ò gbọ́dọ̀ lọ láìmú mi dání o!”
Nígbà tí ọkùnrin náà wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba ọ̀hún, ó wò yíká, ó sì sọ pé: “Èyí ò dúdú rárá. Họ́wù, ó lẹ́wà, ó sì mọ́lẹ̀ rokoṣo. Ohun tí wọ́n sọ fún mi ni pé ńṣe ni Gbọ̀ngàn Ìjọba náà máa dúdú!” Tọkọtaya náà dúró fúngbà díẹ̀, wọ́n sì gba díẹ̀ lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táwọn ará kó sórí káńtà.
Ìjọ kan fẹ́ lo ìwé ìròyìn kan ládùúgbò láti kéde ètò ṣíṣí ilé sílẹ̀ tí wọ́n fẹ́ ṣe lọ́jọ́ tí wọ́n máa ya Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn sí mímọ́. Nígbà tí olótùú ìwé ìròyìn náà gbọ́ nípa ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí, ó dábàá pé ó yẹ kí wọ́n kọ àpilẹ̀kọ kan nípa rẹ̀. Àwọn ará gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí wọ́n fi gbé àpilẹ̀kọ kan tó dáa, èyí tó gba ìdajì ojú ewé kan jáde nínú ìwé ìròyìn náà. Àpilẹ̀kọ náà sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà látòkèdélẹ̀, ó sì tún sọ nípa ìgbòkègbodò ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò ọ̀hún.
Lẹ́yìn tí wọ́n gbé àpilẹ̀kọ náà jáde, ìyá àgbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá aládùúgbò rẹ̀ kan pàdé tó sọ fún un pé: “Àgbàyanu àpilẹ̀kọ kan nípa ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà nínú ìwé ìròyìn lónìí!” Arábìnrin náà wá jẹ́rìí fún un, ó sì fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà, Jehovah’s Witnesses in the Twentieth Century.
Yàtọ̀ sí mímú èrò òdì táwọn èèyàn ní nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò, irú ètò bẹ́ẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣí ilé sílẹ̀ fún àwọn èèyàn láti wò àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ yíya Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun sí mímọ́ ti ta àwọn akéde jí nípa fífún wọn níṣìírí láti pe àwọn èèyàn púpọ̀ sí i wá sípàdé. Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn èèyàn ti mọ̀ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wa ní ṣíṣí sílẹ̀ fún gbogbo èèyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, títí kan ilẹ̀ Finland.