Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?
Ikú ti ṣàkóbá fún gbogbo èèyàn, àmọ́ ṣé ikú lòpin ìgbésí ayé ẹ̀dá? Téèyàn bá kú, ṣé ó ti di ẹni ìgbàgbé nìyẹn? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú?
WO OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:
ỌLỌ́RUN Ò GBÀGBÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ
“Gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa . . . jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.
Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn tó ti kú; gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ máa jíǹde.
ÀJÍǸDE MÁA WÀ NÍ AYÉ
“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
Àìmọye èèyàn ló máa jíǹde, wọ́n á sì ní ìrètí láti gbé títí láé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
Ó DÁJÚ PÉ ÀWỌN ÒKÚ MÁA JÍǸDE
“[Ọlọ́run] ń ka iye àwọn ìràwọ̀; gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ pè.”—Sáàmù 147:4.
Ọlọ́run lè fi orúkọ pe gbogbo àwọn ìràwọ̀, torí náà kò lè ṣòro fún un láti rántí gbogbo àwọn tó máa jí dìde.